Jak 1:9-11
Jak 1:9-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn jẹ ki arakunrin ti iṣe talaka mã ṣogo ni ipo giga rẹ̀. Ati ọlọrọ̀, ni irẹ̀silẹ rẹ̀, nitori bi itanná koriko ni yio kọja lọ. Nitori õrun là ti on ti õru mimu, o si gbẹ koriko, itanná rẹ̀ si rẹ̀ danu, ẹwà oju rẹ̀ si parun: bẹ̃ pẹlu li ọlọrọ̀ yio ṣegbe ni ọ̀na rẹ̀.
Jak 1:9-11 Yoruba Bible (YCE)
Kí arakunrin tí ó jẹ́ mẹ̀kúnnù kí ó yọ̀ nígbà tí Ọlọrun bá gbé e ga. Bẹ́ẹ̀ ni kí ọlọ́rọ̀ kí ó yọ̀ nígbà tí Ọlọrun bá rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀, nítorí bí òdòdó koríko ìgbẹ́ ni ọlọ́rọ̀ kò ní sí mọ́. Nítorí nígbà tí oòrùn bá yọ, tí ó mú, koríko á rọ, òdòdó rẹ̀ á sì rẹ̀, òdòdó tí ó lẹ́wà tẹ́lẹ̀ á wá ṣègbé. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ọlọ́rọ̀ yóo parẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
Jak 1:9-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n jẹ́ kí arákùnrin tí ó ń ṣe onírẹ̀lẹ̀ máa ṣògo ní ipò gíga. Àti ọlọ́rọ̀, ní ìrẹ̀sílẹ̀, nítorí bí ìtànná koríko ni yóò kọjá lọ. Nítorí oòrùn là ti òun ti ooru gbígbóná yóò gbẹ́ koríko, ìtànná rẹ̀ sì rẹ̀ dànù, ẹwà ojú rẹ̀ sì parun: bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ọlọ́rọ̀ yóò ṣègbé ní ọ̀nà rẹ̀.