Isa 29:1-12

Isa 29:1-12 YBCV

EGBE ni fun Arieli, fun Arieli, ilu ti Dafidi ti ngbe! ẹ fi ọdun kún ọdun; jẹ ki wọn pa ẹran rubọ. Ṣugbọn emi o pọ́n Arieli loju, àwẹ on ibanujẹ yio si wà; yio si dabi Arieli si mi. Emi o si dótì ọ yika, emi o si wà odi tì ọ, emi o si mọ odi giga tì ọ. A o si rẹ̀ ọ silẹ, iwọ o sọ̀rọ lati ilẹ jade, ọ̀rọ rẹ yio rẹ̀lẹ lati inu ekuru wá, ohùn rẹ yio si dabi ti ẹnikan ti o li ẹmi àfọṣẹ lati ilẹ jade, ọ̀rọ rẹ yio si dún lati inu erupẹ ilẹ wá. Ọpọlọpọ awọn ọtá rẹ yio dabi ekuru lẹ́bulẹ́bu, ọpọlọpọ aninilara rẹ yio dabi ìyangbo ti o kọja lọ: lõtọ, yio ri bẹ̃ nisisiyi lojiji. Ãrá, ìṣẹlẹ, ati iró nla, pẹlu ìji on ẹfúfu, ati ọwọ́ ajonirun iná ni a o fi bẹ̀ ọ wò lati ọdọ Oluwa awọn ọmọ-ogun wá. Bi alá iran oru li ọ̀pọlọpọ awọn orilẹ-ède ti mba Arieli jà yio ri; gbogbo ẹniti o bá ati on, ati odi agbara rẹ̀ jà, ti nwọn si pọ́n ọ loju. Yio si dabi igbati ẹni ebi npa nla alá; si wo o, o njẹun; ṣugbọn o ji, ọkàn rẹ̀ si ṣofo: tabi bi igbati ẹniti ongbẹ ngbẹ nla alá, si wo o, o nmu omi, ṣugbọn o ji, si wo o, o dáku, ongbẹ si ngbẹ ọkàn rẹ̀; gẹgẹ bẹ̃ ni gbogbo ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède yio ri, ti mba oke Sioni jà. Mu ara duro jẹ, ki ẹnu ki o yà nyin; ẹ fọ́ ara nyin loju, ẹ si fọju: nwọn mu amupara; ṣugbọn kì iṣe fun ọti-waini, nwọn nta gbọngbọ́n ṣugbọn kì iṣe fun ohun mimu lile. Nitori Oluwa dà ẹmi õrun ijìka lù nyin, o si se nyin li oju: awọn wolĩ ati awọn olori awọn ariran nyin li o bò li oju. Iran gbogbo si dabi ọ̀rọ iwe kan fun nyin ti a dí, ti a fi fun ẹnikan ti o mọ̀ ọ kà, wipe, Emi bẹ̀ ọ, kà eyi, ti o si wipe, emi kò le ṣe e; nitori a ti dí i. A si fi iwe na fun ẹniti kò mọ̀ iwe, wipe, Emi bẹ̀ ọ, kà eyi, on si wipe, emi kò mọ̀ iwe.