AISAYA 29:1-12

AISAYA 29:1-12 YCE

Ó ṣe fún Arieli, Jerusalẹmu, ìlú tí ń jẹ́ pẹpẹ Ọlọrun! Ìlú tí Dafidi pàgọ́ sí. Ẹ ṣe ọdún kan tán, ẹ tún ṣe òmíràn sí i, ẹ máa ṣe àwọn àjọ̀dún ní gbogbo àkókò wọn. Sibẹsibẹ n óo mú ìpọ́njú bá ìlú tí ń jẹ́ pẹpẹ Ọlọrun. Ìkérora ati ìpohùnréré ẹkún yóo wà ninu rẹ̀, bíi Arieli ni yóo sì rí sí mi. N óo jẹ́ kí ogun dó tì yín yíká n óo fi àwọn ilé ìṣọ́ ka yín mọ́; n óo sì mọ òkítì sára odi yín. Ninu ọ̀gbun ilẹ̀ ni a óo ti máa gbóhùn rẹ̀, láti inú erùpẹ̀ ni a óo ti máa gbọ́, tí yóo máa sọ̀rọ̀. A óo máa gbọ́ ohùn rẹ̀ láti inú ilẹ̀ bí ohùn òkú, a óo sì máa gbọ́ tí yóo máa sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ láti inú erùpẹ̀. Àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóo pọ̀ bí iyanrìn, ogunlọ́gọ̀ àwọn aláìláàánú yóo bò ọ́ bí ìyàngbò tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ. Lójijì, kíá, OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo dé ba yín, pẹlu ààrá, ati ìdágìrì, ati ariwo ńlá; ati ààjà, ati ìjì líle, ati ahọ́n iná ajónirun. Ogunlọ́gọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí ń bá ìlú tí ń jẹ́ pẹpẹ Ọlọrun jà, yóo parẹ́ bí àlá, gbogbo àwọn tí ń bá ìlú olódi rẹ jà, tí wọn ń ni í lára yóo parẹ́ bí ìran òru. Bí ìgbà tí ẹni tí ebi ń pa bá lá àlá pé òun ń jẹun, tí ó jí, tí ó rí i pé ebi sì tún pa òun, tabi tí ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ́ lá àlá pé òun ń mu omi ṣugbọn tí ó jí, tí ó rí i pé òùngbẹ ṣì ń gbẹ òun, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún ogunlọ́gọ̀ orílẹ̀-èdè tí ń bá Jerusalẹmu jà. Ẹ sọ ara yín di òmùgọ̀, kí ẹ sì máa ṣe bí òmùgọ̀. Ẹ fọ́ ara yín lójú kí ẹ sì di afọ́jú. Ẹ mu àmuyó, ṣugbọn kì í ṣe ọtí. Ẹ máa ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n láì mu ọtí líle. Nítorí OLUWA ti fi ẹ̀mí oorun àsùnwọra si yín lára Ó ti di ẹ̀yin wolii lójú; ó ti bo orí ẹ̀yin aríran. Gbogbo ìran yìí sì ru yín lójú, bí ọ̀rọ̀ inú ìwé tí a fi èdìdì dì. Nígbà tí wọ́n gbé e fún ọ̀mọ̀wé tí wọ́n ní, “Jọ̀wọ́ bá wa kà á.” Ó ní òun kò lè kà á nítorí pé wọ́n ti fi èdìdì dì í. Nígbà tí wọ́n gbé e fún ẹni tí kò mọ̀wé tí wọ́n ní, “Jọ̀wọ́ bá wa kà á.” Ó ní òun kò mọ̀wé kà.