O si ṣe lati ìgba ti o ti fi Josefu jẹ́ olori ile rẹ̀, ati olori ohun gbogbo ti o ní, ni OLUWA busi ile ara Egipti na nitori Josefu: ibukún OLUWA si wà lara ohun gbogbo ti o ní ni ile ati li oko. O si fi ohun gbogbo ti o ní si ọwọ́ Josefu; kò si mọ̀ ohun ti on ní bikoṣe onjẹ ti o njẹ. Josefu si ṣe ẹni daradara ati arẹwà enia. O si ṣe lẹhin nkan wọnyi, ni aya oluwa rẹ̀ gbé oju lé Josefu; o si wipe, Bá mi ṣe. Ṣugbọn on kọ̀, o si wi fun aya oluwa rẹ̀ pe, kiyesi i, oluwa mi kò mọ̀ ohun ti o wà lọdọ mi ni ile, o si ti fi ohun gbogbo ti o ní lé mi lọwọ: Kò sí ẹniti o pọ̀ jù mi lọ ninu ile yi; bẹ̃ni kò si pa ohun kan mọ́ kuro lọwọ mi bikoṣe iwọ, nitori pe aya rẹ̀ ni iwọ iṣe: njẹ emi o ha ti ṣe hù ìwabuburu nla yi, ki emi si dẹ̀ṣẹ si Ọlọrun? O si ṣe, bi o ti nsọ fun Josefu lojojumọ́, ti on kò si gbọ́ tirẹ̀ lati dubulẹ tì i, tabi lati bá a ṣe. O si ṣe niwọ̀n akokò yi, ti Josefu wọle lọ lati ṣe iṣẹ rẹ̀; ti kò si sí ẹnikan ninu awọn ọkunrin ile ninu ile nibẹ̀. On si di Josefu li aṣọ mú, o wipe, bá mi ṣe: on si jọwọ aṣọ rẹ̀ si i lọwọ, o si sá, o bọ sode.
Kà Gẹn 39
Feti si Gẹn 39
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Gẹn 39:5-12
4 Days
Most of us will spend about 50 percent of our adult life at work. We want to know our work has meaning – that our work matters. But stress, demands and adversity can cause us to see work as hard – something to get through. This reading plan will help you recognize the power you have to choose a positive meaning for your work that is rooted in faith.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò