Gẹn 39

39
Josẹfu ati Aya Pọtifari
1A SI mú Josefu sọkalẹ wá si Egipti; Potifari, ijoye Farao kan, olori ẹṣọ́, ara Egipti, si rà a lọwọ awọn ara Iṣmaeli ti o mú u sọkalẹ wá sibẹ̀.
2OLUWA si wà pẹlu Josefu, o si ṣe alasiki enia; o si wà ni ile oluwa rẹ̀ ara Egipti na.
3Oluwa rẹ̀ si ri pe OLUWA pẹlu rẹ̀, ati pe, OLUWA mu ohun gbogbo ti o ṣe dara li ọwọ́ rẹ̀.
4Josefu si ri ojurere li oju rẹ̀, on si nsìn i: o si fi i jẹ́ olori ile rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ní on li o fi lé e lọwọ.
5O si ṣe lati ìgba ti o ti fi Josefu jẹ́ olori ile rẹ̀, ati olori ohun gbogbo ti o ní, ni OLUWA busi ile ara Egipti na nitori Josefu: ibukún OLUWA si wà lara ohun gbogbo ti o ní ni ile ati li oko.
6O si fi ohun gbogbo ti o ní si ọwọ́ Josefu; kò si mọ̀ ohun ti on ní bikoṣe onjẹ ti o njẹ. Josefu si ṣe ẹni daradara ati arẹwà enia.
7O si ṣe lẹhin nkan wọnyi, ni aya oluwa rẹ̀ gbé oju lé Josefu; o si wipe, Bá mi ṣe.
8Ṣugbọn on kọ̀, o si wi fun aya oluwa rẹ̀ pe, kiyesi i, oluwa mi kò mọ̀ ohun ti o wà lọdọ mi ni ile, o si ti fi ohun gbogbo ti o ní lé mi lọwọ:
9Kò sí ẹniti o pọ̀ jù mi lọ ninu ile yi; bẹ̃ni kò si pa ohun kan mọ́ kuro lọwọ mi bikoṣe iwọ, nitori pe aya rẹ̀ ni iwọ iṣe: njẹ emi o ha ti ṣe hù ìwabuburu nla yi, ki emi si dẹ̀ṣẹ si Ọlọrun?
10O si ṣe, bi o ti nsọ fun Josefu lojojumọ́, ti on kò si gbọ́ tirẹ̀ lati dubulẹ tì i, tabi lati bá a ṣe.
11O si ṣe niwọ̀n akokò yi, ti Josefu wọle lọ lati ṣe iṣẹ rẹ̀; ti kò si sí ẹnikan ninu awọn ọkunrin ile ninu ile nibẹ̀.
12On si di Josefu li aṣọ mú, o wipe, bá mi ṣe: on si jọwọ aṣọ rẹ̀ si i lọwọ, o si sá, o bọ sode.
13O si ṣe, nigbati o ri i pe Josefu jọwọ aṣọ rẹ̀ si i lọwọ, ti o si sá jade,
14Nigbana li o kepè awọn ọkunrin ile rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Ẹ wò o, o mú Heberu kan wọle tọ̀ wa wá lati fi wa ṣe ẹlẹyà; o wọle tọ̀ mi wá lati bá mi ṣe, mo si kigbe li ohùn rara:
15O si ṣe, nigbati o gbọ́ pe mo gbé ohùn mi soke ti mo si kigbe, o jọwọ aṣọ rẹ̀ sọdọ mi, o si sá, o bọ sode.
16O si fi aṣọ Josefu lelẹ li ẹba ọdọ rẹ̀, titi oluwa rẹ̀ fi bọ̀wá ile.
17O si wi fun u bi ọ̀rọ wọnyi pe, Ẹrú Heberu ti iwọ mu tọ̀ wá wá, o wọle tọ̀ mi lati fi mi ṣe ẹlẹyà:
18O si ṣe, bi mo ti gbé ohùn mi soke ti mo si ké, o si jọwọ aṣọ rẹ̀ sọdọ mi, o si sá jade.
19O si ṣe, nigbati oluwa rẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ aya rẹ̀, ti o sọ fun u wipe, Bayibayi li ẹrú rẹ ṣe si mi; o binu gidigidi.
20Oluwa Josefu si mú u, o si fi i sinu túbu, nibiti a gbé ndè awọn ara túbu ọba; o si wà nibẹ̀ ninu túbu.
21Ṣugbọn OLUWA wà pẹlu Josefu, o si ṣãnu fun u, o si fun u li ojurere li oju onitúbu.
22Onitúbu si fi gbogbo awọn ara túbu ti o wà ninu túbu lé Josefu lọwọ; ohunkohun ti nwọn ba si ṣe nibẹ̀, on li oluṣe rẹ̀.
23Onitúbu kò si bojuwò ohun kan ti o wà li ọwọ́ rẹ̀; nitori ti OLUWA wà pẹlu rẹ̀, ati ohun ti o ṣe OLUWA mú u dara.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Gẹn 39: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa