Gẹn 36:1-30

Gẹn 36:1-30 YBCV

WỌNYI si ni iran Esau, ẹniti iṣe Edomu. Esau fẹ́ awọn aya rẹ̀ ninu awọn ọmọbinrin Kenaani; Ada, ọmọbinrin Eloni, enia Hitti, ati Aholibama, ọmọbinrin Ana, ọmọbinrin Sibeoni, ara Hiffi; Ati Baṣemati, ọmọbinrin Iṣmaeli, arabinrin Nebajotu. Ada si bí Elifasi fun Esau; Baṣemati si bí Reueli; Aholibama si bí Jeuṣi, ati Jaalamu, ati Kora: awọn wọnyi li ọmọkunrin Esau, ti a bí fun u ni ilẹ Kenaani. Esau si mú awọn aya rẹ̀, ati awọn ọmọkunrin rẹ̀, ati awọn ọmọbinrin rẹ̀, ati gbogbo awọn enia ile rẹ̀, ati ẹran rẹ̀, ati gbogbo ohun-ọ̀sin, ati ohun iní gbogbo ti o ní ni ilẹ Kenaani; o si lọ si ilẹ kan kuro niwaju Jakobu arakunrin rẹ̀. Nitori ti ọrọ̀ wọn pọ̀ jù ki nwọn ki o gbé pọ̀ lọ; ilẹ ti nwọn si ṣe atipo si kò le gbà wọn, nitori ohun-ọ̀sin wọn. Bẹ̃ni Esau tẹ̀dó li oke Seiri: Esau ni Edomu. Wọnyi si ni iran Esau, baba awọn ara Edomu, li oke Seiri: Wọnyi li orukọ awọn ọmọ Esau; Elifasi, ọmọ Ada, aya Esau, Rueli, ọmọ Baṣemati, aya Esau. Ati awọn ọmọ Elifasi ni Temani, Omari, Sefo, ati Gatamu, ati Kenasi. Timna li o si ṣe àle Elifasi, ọmọ Esau; on si bí Amaleki fun Elifasi; wọnyi si li awọn ọmọ Ada, aya Esau. Wọnyi si li awọn ọmọ Reueli; Nahati, ati Sera, Ṣamma, ati Misa: awọn wọnyi li awọn ọmọ Baṣemati, aya Esau. Wọnyi si li awọn ọmọ Aholibama, ọmọbinrin Ana, ọmọbinrin Sibeoni, aya Esau: on si bí Jeuṣi fun Esau, ati Jaalamu, ati Kora. Awọn wọnyi ni olori ninu awọn ọmọ Esau: awọn ọmọ Elifasi, akọ́bi Esau; Temani olori, Omari olori, Sefo olori, Kenasi olori, Kora olori, Gatamu olori, Amaleki olori: wọnyi li awọn olori ti o ti ọdọ Elifasi wá ni ilẹ Edomu; wọnyi li awọn ọmọ Ada. Wọnyi si li awọn ọmọ Reueli ọmọ Esau; Nahati olori, Sera olori, Ṣamma olori, Misa olori; wọnyi li awọn olori ti o ti ọdọ Reueli wá ni ilẹ Edomu; wọnyi li awọn ọmọ Baṣemati, aya Esau. Wọnyi si li awọn ọmọ Aholibama, aya Esau; Jeuṣi olori, Jaalamu olori, Kora olori: wọnyi li awọn ti o ti ọdọ Aholibama wá, aya Esau, ọmọbinrin Ana. Wọnyi li awọn ọmọ Esau, eyini ni Edomu, wọnyi si li awọn olori wọn. Wọnyi li awọn ọmọ Seiri, enia Hori, ti o tẹ̀dó ni ilẹ na; Lotani, ati Ṣobali, ati Sibeoni, ati Ana, Ati Diṣoni, ati Eseri, ati Diṣani: wọnyi li awọn olori enia Hori, awọn ọmọ Seiri ni ilẹ Edomu. Ati awọn ọmọ Lotani ni Hori ati Hemamu: arabinrin Lotani si ni Timna. Ati awọn ọmọ Ṣobali ni wọnyi; Alfani, ati Mahanati, ati Ebali, Sefo, ati Onamu. Wọnyi si li awọn ọmọ Sibeoni; ati Aja on Ana: eyi ni Ana ti o ri awọn isun omi gbigbona ni ijù, bi o ti mbọ́ awọn kẹtẹkẹtẹ Sibeoni baba rẹ̀. Wọnyi si li awọn ọmọ Ana; Disoni ati Aholibama, ọmọbinrin Ana. Wọnyi si li awọn ọmọ Diṣoni; Hemdani, ati Eṣbani, ati Itrani, ati Kerani. Awọn ọmọ Eseri ni wọnyi; Bilhani, ati Saafani, ati Akani. Awọn ọmọ Diṣani ni wọnyi; Usi ati Arani. Wọnyi li awọn olori ti o ti ọdọ Hori wá; Lotani olori, Ṣobali olori, Sibeoni olori, Ana olori, Diṣoni olori, Eseri olori, Diṣani olori; wọnyi li awọn olori awọn enia Hori, ninu awọn olori wọn ni ilẹ Seiri.