Gẹn 36:1-30

Gẹn 36:1-30 Bibeli Mimọ (YBCV)

WỌNYI si ni iran Esau, ẹniti iṣe Edomu. Esau fẹ́ awọn aya rẹ̀ ninu awọn ọmọbinrin Kenaani; Ada, ọmọbinrin Eloni, enia Hitti, ati Aholibama, ọmọbinrin Ana, ọmọbinrin Sibeoni, ara Hiffi; Ati Baṣemati, ọmọbinrin Iṣmaeli, arabinrin Nebajotu. Ada si bí Elifasi fun Esau; Baṣemati si bí Reueli; Aholibama si bí Jeuṣi, ati Jaalamu, ati Kora: awọn wọnyi li ọmọkunrin Esau, ti a bí fun u ni ilẹ Kenaani. Esau si mú awọn aya rẹ̀, ati awọn ọmọkunrin rẹ̀, ati awọn ọmọbinrin rẹ̀, ati gbogbo awọn enia ile rẹ̀, ati ẹran rẹ̀, ati gbogbo ohun-ọ̀sin, ati ohun iní gbogbo ti o ní ni ilẹ Kenaani; o si lọ si ilẹ kan kuro niwaju Jakobu arakunrin rẹ̀. Nitori ti ọrọ̀ wọn pọ̀ jù ki nwọn ki o gbé pọ̀ lọ; ilẹ ti nwọn si ṣe atipo si kò le gbà wọn, nitori ohun-ọ̀sin wọn. Bẹ̃ni Esau tẹ̀dó li oke Seiri: Esau ni Edomu. Wọnyi si ni iran Esau, baba awọn ara Edomu, li oke Seiri: Wọnyi li orukọ awọn ọmọ Esau; Elifasi, ọmọ Ada, aya Esau, Rueli, ọmọ Baṣemati, aya Esau. Ati awọn ọmọ Elifasi ni Temani, Omari, Sefo, ati Gatamu, ati Kenasi. Timna li o si ṣe àle Elifasi, ọmọ Esau; on si bí Amaleki fun Elifasi; wọnyi si li awọn ọmọ Ada, aya Esau. Wọnyi si li awọn ọmọ Reueli; Nahati, ati Sera, Ṣamma, ati Misa: awọn wọnyi li awọn ọmọ Baṣemati, aya Esau. Wọnyi si li awọn ọmọ Aholibama, ọmọbinrin Ana, ọmọbinrin Sibeoni, aya Esau: on si bí Jeuṣi fun Esau, ati Jaalamu, ati Kora. Awọn wọnyi ni olori ninu awọn ọmọ Esau: awọn ọmọ Elifasi, akọ́bi Esau; Temani olori, Omari olori, Sefo olori, Kenasi olori, Kora olori, Gatamu olori, Amaleki olori: wọnyi li awọn olori ti o ti ọdọ Elifasi wá ni ilẹ Edomu; wọnyi li awọn ọmọ Ada. Wọnyi si li awọn ọmọ Reueli ọmọ Esau; Nahati olori, Sera olori, Ṣamma olori, Misa olori; wọnyi li awọn olori ti o ti ọdọ Reueli wá ni ilẹ Edomu; wọnyi li awọn ọmọ Baṣemati, aya Esau. Wọnyi si li awọn ọmọ Aholibama, aya Esau; Jeuṣi olori, Jaalamu olori, Kora olori: wọnyi li awọn ti o ti ọdọ Aholibama wá, aya Esau, ọmọbinrin Ana. Wọnyi li awọn ọmọ Esau, eyini ni Edomu, wọnyi si li awọn olori wọn. Wọnyi li awọn ọmọ Seiri, enia Hori, ti o tẹ̀dó ni ilẹ na; Lotani, ati Ṣobali, ati Sibeoni, ati Ana, Ati Diṣoni, ati Eseri, ati Diṣani: wọnyi li awọn olori enia Hori, awọn ọmọ Seiri ni ilẹ Edomu. Ati awọn ọmọ Lotani ni Hori ati Hemamu: arabinrin Lotani si ni Timna. Ati awọn ọmọ Ṣobali ni wọnyi; Alfani, ati Mahanati, ati Ebali, Sefo, ati Onamu. Wọnyi si li awọn ọmọ Sibeoni; ati Aja on Ana: eyi ni Ana ti o ri awọn isun omi gbigbona ni ijù, bi o ti mbọ́ awọn kẹtẹkẹtẹ Sibeoni baba rẹ̀. Wọnyi si li awọn ọmọ Ana; Disoni ati Aholibama, ọmọbinrin Ana. Wọnyi si li awọn ọmọ Diṣoni; Hemdani, ati Eṣbani, ati Itrani, ati Kerani. Awọn ọmọ Eseri ni wọnyi; Bilhani, ati Saafani, ati Akani. Awọn ọmọ Diṣani ni wọnyi; Usi ati Arani. Wọnyi li awọn olori ti o ti ọdọ Hori wá; Lotani olori, Ṣobali olori, Sibeoni olori, Ana olori, Diṣoni olori, Eseri olori, Diṣani olori; wọnyi li awọn olori awọn enia Hori, ninu awọn olori wọn ni ilẹ Seiri.

Gẹn 36:1-30 Yoruba Bible (YCE)

Àkọsílẹ̀ ìran Esau, tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Edomu nìyí: Ninu àwọn ọmọbinrin Kenaani ni Esau ti fẹ́ aya, ekinni ń jẹ́ Ada, ọmọ Eloni ará Hiti, ekeji ń jẹ́ Oholibama, ọmọ Ana tí baba rẹ̀ ń jẹ́ Sibeoni, ará Hifi. Ẹkẹta ń jẹ́ Basemati ọmọ Iṣimaeli, arabinrin Nebaiotu. Ada bí Elifasi fún Esau, Basemati bí Reueli. Oholibama bí Jeuṣi, Jalamu ati Kora. Àwọn ni ọmọ Esau, tí àwọn aya rẹ̀ bí fún un ní ilẹ̀ Kenaani. Nígbà tí ó ṣe, Esau kó àwọn aya rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin, gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, àwọn mààlúù rẹ̀, àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀, ati gbogbo ohun ìní rẹ̀ tí ó ti kójọ ní ilẹ̀ Kenaani, ó kó kúrò ní ilẹ̀ Kenaani lọ́dọ̀ Jakọbu, arakunrin rẹ̀. Ìdí ni pé ọrọ̀ wọn ti pọ̀ ju kí wọ́n jọ máa gbé pọ̀ lọ, ilẹ̀ tí wọ́n sì ti ń ṣe àtìpó kò gbà wọ́n mọ́, nítorí pé wọ́n ní ẹran ọ̀sìn tí ó pọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni Esau ṣe di ẹni tí ń gbé orí òkè Seiri. Esau kan náà ni ń jẹ́ Edomu. Àkọsílẹ̀ ìran Esau, baba àwọn ará Edomu, tí ń gbé orí òkè Seiri nìyí: orúkọ àwọn ọmọ rẹ̀ ni, Elifasi, tí Ada bí, ati Reueli, tí Basemati bí. Àwọn ọmọ Elifasi ni: Temani, Omari, Sefo, Gatamu ati Kenasi. (Elifasi, ọmọ Esau ní obinrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Timna, òun ni ó bí Amaleki fún un.) Àwọn ni àwọn ọmọ Ada, aya Esau. Àwọn ọmọ Reueli ni Nahati, Sera, Ṣama, ati Misa. Àwọn ni àwọn ọmọ Basemati, aya Esau. Àwọn ọmọ tí Oholibama, ọmọ Ana, ọmọ Sibeoni, aya Esau, bí fún un ni Jeuṣi, Jalamu ati Kora. Àwọn tí wọ́n jẹ́ ìjòyè ninu àwọn ọmọ Esau nìwọ̀nyí, Lára àwọn ọmọ Elifasi, àkọ́bí Esau, tí Ada bí fún un: Temani, Omari, Sefo, Kenasi. Kora, Gatamu, ati Amaleki. Àwọn wọnyii jẹ́ ọmọ Ada, aya Esau. Lára àwọn ọmọ Reueli, ọmọ Esau, àwọn tí wọ́n jẹ́ ìjòyè ni: Nahati, Sera, Ṣama, ati Misa. Àwọn ni ìjòyè tí wọ́n ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Reueli, ní ilẹ̀ Edomu, wọ́n sì jẹ́ ọmọ Basemati, aya Esau. Lára àwọn ọmọ Oholibama, aya Esau: àwọn tí wọ́n jẹ́ ìjòyè ni: Jeuṣi, Jalamu, ati Kora. Àwọn ni ìjòyè tí wọ́n ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Oholibama, ọmọ Ana, aya Esau. Wọ́n jẹ́ ọmọ Esau, tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Edomu, àwọn sì ni ìjòyè tí wọ́n ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ṣẹ̀. Àwọn ọmọ Seiri ará Hori, tí ń gbé ilẹ̀ náà nìyí: àwọn ọmọ rẹ̀ ni: Lotani, Ṣobali, Sibeoni ati Ana, Diṣoni, Eseri, ati Diṣani, àwọn ni ìjòyè ní ilẹ̀ Hori, wọ́n sì jẹ́ ọmọ Seiri ní ilẹ̀ Edomu. Àwọn ọmọ Lotani ni Hori, ati Hemani, Timna ni arabinrin Lotani. Àwọn ọmọ Ṣobali ni Alfani, Manahati, Ebali, Ṣefo ati Onamu. Àwọn ọmọ Sibeoni ni Aya ati Ana. Ana yìí ni ó rí àwọn ìsun omi gbígbóná láàrin aginjù, níbi tí ó ti ń tọ́jú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Sibeoni, baba rẹ̀. Àwọn ọmọ Ana ni, Diṣoni ati Oholibama. Àwọn ọmọ Diṣoni ni Hemdani, Eṣibani, Itirani, ati Kerani. Àwọn ọmọ Eseri ni: Bilihani, Saafani, ati Akani. Àwọn ọmọ Diṣani ni: Usi ati Arani. Àwọn ìjòyè tí wọ́n ṣẹ̀ lára Hori nìwọ̀nyí: Lotani, Ṣobali, Sibeoni, Diṣoni, Eseri, ati Diṣani. Àwọn ìjòyè ilẹ̀ Hori, gẹ́gẹ́ bí olórí ìdílé ìdílé wọn ní ilẹ̀ Seiri.

Gẹn 36:1-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Wọ̀nyí ni ìran Esau, ẹni tí a ń pè ní Edomu. Nínú àwọn ọmọbìnrin Kenaani ni Esau ti fẹ́ àwọn ìyàwó rẹ̀: Adah ọmọbìnrin Eloni ará Hiti àti Oholibama, ọmọbìnrin Ana, ọmọ ọmọ Sibeoni ará Hifi. Ó sì tún fẹ́ Basemati ọmọ Iṣmaeli arábìnrin Nebaioti. Adah bí Elifasi fún Esau, Basemati sì bí Reueli, Oholibama pẹ̀lú sì bí Jeuṣi, Jalamu, àti Kora. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ tí Esau bí ní Kenaani. Esau sì mú àwọn aya rẹ̀, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ àti gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ àti àwọn ẹran ọ̀sìn mìíràn àti gbogbo ohun ìní mìíràn tí ó ní, ni Kenaani, ó sì kó lọ sí ilẹ̀ mìíràn, jìnà sí ibi tí Jakọbu arákùnrin rẹ̀ wà. Ohun ìní wọn pọ̀ ju èyí tí àwọn méjèèjì lè máa gbé ní ojú kan lọ. Ilẹ̀ tí wọ́n wà kò le gba àwọn méjèèjì nítorí àwọn ohun ọ̀sìn wọn. Báyìí ni Esau tí a tún mọ̀ sí Edomu tẹ̀dó sí àwọn orílẹ̀-èdè olókè tí Seiri. Èyí ni ìran Esau baba àwọn ará Edomu ní àwọn orílẹ̀-èdè olókè Seiri. Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Esau: Elifasi ọmọ Adah aya Esau àti Reueli, ọmọ Basemati tí í ṣe aya Esau pẹ̀lú. Àwọn ọmọ Elifasi ni ìwọ̀nyí: Temani, Omari, Sefi, Gatamu, àti Kenasi. Elifasi ọmọ Esau sì tún ní àlè tí a ń pè ní Timna pẹ̀lú, òun ló bí Amaleki fún un. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ ọmọ Adah aya Esau. Àwọn ọmọ Reueli: Nahati, Sera, Ṣamma àti Missa. Àwọn ni ọmọ ọmọ Basemati aya Esau. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Oholibama ọmọbìnrin Ana ọmọ ọmọ Sibeoni: tí ó bí fún Esau: Jeuṣi, Jalamu àti Kora. Àwọn wọ̀nyí ni olórí nínú àwọn ọmọ Esau: Àwọn ọmọ Elifasi, àkọ́bí Esau: Temani, Omari, Sefi, Kenasi, Kora, Gatamu àti Amaleki. Àwọn wọ̀nyí ló jẹ́ olórí ìdílé tí ó ti ọ̀dọ̀ Elifasi ní Edomu wá, wọ́n jẹ́ ọmọ ọmọ Adah. Wọ̀nyí sì ni àwọn ọmọ Esau, ọmọ Rueli: Nahati olórí, Sera olórí, Ṣamma olórí, Missa olórí; Àwọn wọ̀nyí ló jẹ́ olórí ìdílé tí ó ti ọ̀dọ̀ Reueli jáde ní Edomu. Ọmọ ọmọ Basemati aya Esau ni wọ́n jẹ́. Àwọn ọmọ Oholibama aya Esau: Jeuṣi, Jalamu, àti Kora, àwọn wọ̀nyí ló jẹ́ olórí ìdílé tí ó ti ọ̀dọ̀ Oholibama ọmọ Ana, ìyàwó Esau wá. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Esau (Edomu). Àwọn wọ̀nyí ni olórí wọn. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Seiri ará Hori tí ó ń gbé ní ilẹ̀ náà: Lotani, Ṣobali, Sibeoni, Ana, Diṣoni, Eseri, àti Diṣani, àwọn wọ̀nyí olórí ènìyàn Hori, àwọn ọmọ Seiri ni ilẹ̀ Edomu. Àwọn ọmọ Lotani: Hori àti Homamu: Timna sì ni arábìnrin Lotani. Àwọn ọmọ Ṣobali: Alifani, Manahati, Ebali, Ṣefo àti Onamu. Àwọn ọmọ Sibeoni: Aiah àti Ana. Èyí ni Ana tí ó rí ìsun omi gbígbóná ní inú aginjù bí ó ti ń da àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Ṣebeoni baba rẹ̀. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ana: Diṣoni àti Oholibama (Àwọn ọmọbìnrin ni wọn). Àwọn ọmọ Diṣoni ni: Hemdani, Eṣbani, Itrani àti Kerani. Àwọn ọmọ Eseri: Bilhani, Saafani àti Akani. Àwọn ọmọ Diṣani ni: Usi àti Arani. Àwọn wọ̀nyí ni olórí ìdílé Hori: Lotani, Ṣobali, Sibeoni, Ana, Diṣoni Eseri, àti Diṣani. Àwọn ni olórí ìdílé àwọn ará Hori gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn ní ilẹ̀ Seiri.