Gẹn 24:14-20

Gẹn 24:14-20 YBCV

Ki o si jẹ ki o ṣe pe, omidan ti emi o wi fun pe, Emi bẹ̀ ọ, sọ ladugbo rẹ kalẹ, ki emi ki o mu; ti on o si wipe, Mu, emi o si fi fun awọn ibakasiẹ rẹ mu pẹlu: on na ni ki o jẹ ẹniti iwọ yàn fun Isaaki iranṣẹ rẹ; nipa eyi li emi o si mọ̀ pe, iwọ ti ṣe ore fun oluwa mi. O si ṣe, ki on to pari ọ̀rọ isọ, kiyesi i, Rebeka jade de, ẹniti a bí fun Betueli, ọmọ Milka, aya Nahori, arakunrin Abrahamu, ti on ti ladugbo rẹ̀ li ejika rẹ̀. Omidan na li ẹwà gidigidi lati wò, wundia ni, bẹ̃li ẹnikẹni kò ti imọ̀ ọ: o si sọkalẹ lọ sinu kanga, o si pọn ladugbo rẹ̀ kún, o si goke. Iranṣẹ na si sure lọ ipade rẹ̀, o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki nmu omi diẹ ninu ladugbo rẹ. O si dahùn pe, Mu, oluwa mi: o si yara, o sọ̀ ladugbo rẹ̀ ka ọwọ́, o si fun u mu. Nigbati o si fun u mu tan, o si wipe, Emi o pọn fun awọn ibakasiẹ rẹ pẹlu, titi nwọn o fi mu tan. O si yara, o si tú ladugbo rẹ̀ sinu ibumu, o si tun pada sure lọ si kanga lati pọn omi, o si pọn fun gbogbo awọn ibakasiẹ rẹ̀.