Gẹn 24

24
Wọ́n Gbeyawo fún Isaaki
1ABRAHAMU si gbó, o si pọ̀ li ọjọ́: OLUWA si ti busi i fun Abrahamu li ohun gbogbo.
2Abrahamu si wi fun iranṣẹ rẹ̀, agba ile rẹ̀ ti o ṣe olori ohun gbogbo ti o ni pe, Emi bẹ̀ ọ, fi ọwọ rẹ si abẹ itan mi;
3Emi o si mu ọ fi OLUWA bura, Ọlọrun ọrun, ati Ọlọrun aiye, pe iwọ ki yio fẹ́ aya fun ọmọ mi ninu awọn ọmọbinrin ara Kenaani, lãrin awọn ẹniti mo ngbé:
4Ṣugbọn iwọ o lọ si ilẹ mi, ati si ọdọ awọn ará mi, ki iwọ ki o si fẹ́ aya fun Isaaki, ọmọ mi.
5Iranṣẹ na si wi fun u pe, Bọya obinrin na ki yio fẹ́ ba mi wá si ilẹ yi: mo ha le mu ọmọ rẹ pada lọ si ilẹ ti iwọ gbé ti wá?
6Abrahamu si wi fun u pe, Kiyesara ki iwọ ki o má tun mu ọmọ mi pada lọ sibẹ̀.
7OLUWA Ọlọrun ọrun, ti o mu mi lati ile baba mi wá, ati lati ilẹ ti a bi mi, ẹniti o sọ fun mi, ti o si bura fun mi, wipe, Irú-ọmọ rẹ li emi o fi ilẹ yi fun; on ni yio rán angeli rẹ̀ ṣaju rẹ, iwọ o si fẹ́ aya lati ibẹ̀ fun ọmọ mi wá.
8Bi obinrin na kò ba si fẹ́ tẹle ọ, njẹ nigbana li ọrùn rẹ yio mọ́ kuro ni ibura mi yi: ọkan ni, ki iwọ máṣe tun mu ọmọ mi pada lọ sibẹ̀.
9Iranṣẹ na si fi ọwọ́ rẹ̀ si abẹ itan Abrahamu oluwa rẹ̀, o si bura fun u nitori ọ̀ran yi.
10Iranṣẹ na si mu ibakasiẹ mẹwa, ninu ibakasiẹ oluwa rẹ̀, o si lọ; nitori pe li ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo ẹrù oluwa rẹ̀ wà: o si dide, o si lọ si Mesopotamia, si ilu Nahori.
11O si mu awọn ibakasiẹ rẹ̀ kunlẹ lẹhin ode ilu na li ẹba kanga omi kan nigba aṣalẹ, li akokò igbati awọn obinrin ima jade lọ pọnmi.
12O si wipe, OLUWA, Ọlọrun Abrahamu oluwa mi, emi bẹ̀ ọ, ṣe ọ̀na mi ni rere loni, ki o si ṣe ore fun Abrahamu oluwa mi.
13Kiyesi i, emi duro li ẹba kanga omi yi; awọn ọmọbinrin ara ilu na njade wá lati pọnmi:
14Ki o si jẹ ki o ṣe pe, omidan ti emi o wi fun pe, Emi bẹ̀ ọ, sọ ladugbo rẹ kalẹ, ki emi ki o mu; ti on o si wipe, Mu, emi o si fi fun awọn ibakasiẹ rẹ mu pẹlu: on na ni ki o jẹ ẹniti iwọ yàn fun Isaaki iranṣẹ rẹ; nipa eyi li emi o si mọ̀ pe, iwọ ti ṣe ore fun oluwa mi.
15O si ṣe, ki on to pari ọ̀rọ isọ, kiyesi i, Rebeka jade de, ẹniti a bí fun Betueli, ọmọ Milka, aya Nahori, arakunrin Abrahamu, ti on ti ladugbo rẹ̀ li ejika rẹ̀.
16Omidan na li ẹwà gidigidi lati wò, wundia ni, bẹ̃li ẹnikẹni kò ti imọ̀ ọ: o si sọkalẹ lọ sinu kanga, o si pọn ladugbo rẹ̀ kún, o si goke.
17Iranṣẹ na si sure lọ ipade rẹ̀, o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki nmu omi diẹ ninu ladugbo rẹ.
18O si dahùn pe, Mu, oluwa mi: o si yara, o sọ̀ ladugbo rẹ̀ ka ọwọ́, o si fun u mu.
19Nigbati o si fun u mu tan, o si wipe, Emi o pọn fun awọn ibakasiẹ rẹ pẹlu, titi nwọn o fi mu tan.
20O si yara, o si tú ladugbo rẹ̀ sinu ibumu, o si tun pada sure lọ si kanga lati pọn omi, o si pọn fun gbogbo awọn ibakasiẹ rẹ̀.
21Ọkunrin na si tẹjumọ ọ, o dakẹ, lati mọ̀ bi OLUWA mu ìrin on dara, bi bẹ̃kọ.
22O si ṣe, bi awọn ibakasiẹ ti mu omi tan, ni ọkunrin na mu oruka wurà àbọ ìwọn ṣekeli, ati jufù meji fun ọwọ́ rẹ̀, ti ìwọn ṣekeli wurà mẹwa;
23O si bi i pe, Ọmọbinrin tani iwọ iṣe? Emi bẹ̀ ọ, wi fun mi: àye wà ni ile baba rẹ fun wa lati wọ̀ si?
24On si wi fun u pe, Ọmọbinrin Betueli, ọmọ Milka, ti o bí fun Nahori, li emi iṣe.
25O si wi fun u pe, Awa ni koriko ati sakasáka tó pẹlu, ati àye lati wọ̀ si.
26Ọkunrin na si tẹriba, o si sìn OLUWA.
27O si wipe, Olubukún li OLUWA, Ọlọrun Abrahamu, oluwa mi, ti kò jẹ ki ãnu rẹ̀ ati otitọ rẹ̀ ki o yẹ̀ kuro lọdọ, oluwa mi, niti emi, OLUWA fi ẹsẹ̀ mi le ọ̀na ile awọn arakunrin baba mi.
28Omidan na si sure, o si rò nkan wọnyi fun awọn ara ile iya rẹ̀.
29Rebeka si li arakunrin kan, orukọ rẹ̀ si ni Labani: Labani si sure jade tọ̀ ọkunrin na lọ si ibi kanga.
30O si ṣe, bi o ti ri oruka, ati jufù li ọwọ́ arabinrin rẹ̀, ti o si gbọ́ ọ̀rọ Rebeka arabinrin rẹ̀ pe, Bayi li ọkunrin na ba mi sọ; bẹ̃li o si tọ̀ ọkunrin na wá; si kiyesi i, o duro tì awọn ibakasiẹ rẹ̀ leti kanga na.
31O si wipe, Wọle, iwọ ẹni-ibukún OLUWA; ẽṣe ti iwọ fi duro lode? mo sá ti pèse àye silẹ ati àye fun awọn ibakasiẹ.
32Ọkunrin na si wọle na wá; o si tú awọn ibakasiẹ, o si fun awọn ibakasiẹ, ni koriko ati sakasáka, ati omi fun u lati wẹ̀ ẹsẹ̀ rẹ̀, ati ẹsẹ̀ awọn ọkunrin ti o pẹlu rẹ̀.
33A si gbé onjẹ kalẹ fun u lati jẹ: ṣugbọn on si wipe, Emi ki yio jẹun titi emi o fi jiṣẹ mi tán. On si wipe, Ma wi.
34O si wipe, Ọmọ-ọdọ Abrahamu li emi iṣe.
35OLUWA si ti bukún fun oluwa mi gidigidi; o si di pupọ̀: o si fun u li agutan, ati mãlu, ati fadaka, ati wurà, ati iranṣẹkunrin, ati iranṣẹbinrin, ati ibakasiẹ, ati kẹtẹkẹtẹ.
36Sara, aya oluwa mi, si bí ọmọ kan fun oluwa mi nigbati on (Sara) gbó tán: on li o si fi ohun gbogbo ti o ni fun.
37Oluwa mi si mu mi bura, wipe, Iwọ kò gbọdọ fẹ́ obinrin fun ọmọ mi ninu awọn ọmọbinrin ara Kenaani ni ilẹ ẹniti emi ngbé:
38Bikoṣe ki iwọ ki o lọ si ile baba mi, ati si ọdọ awọn ibatan mi, ki o si fẹ́ aya fun ọmọ mi.
39Emi si wi fun oluwa mi pe, Bọya obinrin na ki yio tẹle mi.
40O si wi fun mi pe, OLUWA, niwaju ẹniti emi nrìn, yio rán angeli rẹ̀ pelu rẹ, yio si mu ọ̀na rẹ dara; iwọ o si fẹ́ aya fun ọmọ mi lati ọdọ awọn ibatan mi, ati lati inu ile baba mi:
41Nigbana li ọrùn rẹ yio mọ́ kuro ninu ibura mi yi, nigbati iwọ ba de ọdọ awọn ibatan mi; bi nwọn kò ba si fi ẹnikan fun ọ, ọrùn rẹ yio si mọ́ kuro ninu ibura mi.
42Emi si de si ibi kanga loni, mo si wipe, OLUWA, Ọlọrun Abrahamu oluwa mi, bi iwọ ba mu ọ̀na àjo mi ti mo nlọ nisisiyi dara:
43Kiyesi i, mo duro li ẹba kanga omi; ki o si ṣẹ, pe nigbati wundia na ba jade wá ipọn omi, ti mo ba si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, bùn mi li omi diẹ ki emi mu lati inu ladugbo rẹ;
44Ti o si wi fun mi pe, Iwọ mu, emi o si pọn fun awọn ibakasiẹ rẹ pẹlu: ki on na ki o ṣe obinrin ti OLUWA ti yàn fun ọmọ oluwa mi.
45Ki emi ki o si tó wi tán li ọkàn mi, kiyesi i, Rebeka jade de ti on ti ladugbo rẹ̀ li ejika rẹ̀; o si sọkalẹ lọ sinu kanga, o pọn omi: emi si wi fun u pe, Mo bẹ̀ ọ, jẹ ki emi mu omi.
46O si yara, o si sọ ladugbo rẹ̀ kalẹ kuro li ejika rẹ̀, o si wipe, Mu, emi o si fi fun awọn ibakasiẹ rẹ mu pẹlu; bẹ̃li emi mu, o si fi fun awọn ibakasiẹ mu pẹlu.
47Emi si bi i, mo si wipe, Ọmọbinrin tani iwọ iṣe? o si wipe, Ọmọbinrin Betueli, ọmọ Nahori, ti Milka bí fun u: emi si fi oruka si i ni imu, ati jufù si ọwọ́ rẹ̀.
48Emi si tẹriba, mo si wolẹ fun OLUWA, mo si fi ibukún fun OLUWA, Ọlọrun Abrahamu oluwa mi, ti o mu mi tọ̀ ọ̀na titọ lati mu ọmọbinrin arakunrin oluwa mi fun ọmọ rẹ̀ wá.
49Njẹ nisisiyi, bi ẹnyin o ba bá oluwa mi lò inu rere ati otitọ, ẹ wi fun mi: bi bẹ̃ si kọ; ẹ wi fun mi: ki emi ki o le pọ̀ si apa ọtún, tabi si òsi.
50Nigbana ni Labani ati Betueli dahùn nwọn si wipe, Lọdọ OLUWA li ohun na ti jade wá: awa kò le sọ rere tabi buburu fun ọ.
51Wò o, Rebeka niyi niwaju rẹ, mu u, ki o si ma lọ, ki on ki o si ma ṣe aya ọmọ oluwa rẹ, bi OLUWA ti wi.
52O si ṣe, nigbati iranṣẹ Abrahamu gbọ́ ọ̀rọ wọn, o wolẹ fun OLUWA.
53Iranṣẹ na si yọ ohun èlo fadaka, ati èlo wurà jade, ati aṣọ, o si fi wọn fun Rebeka: o si fi ohun iyebiye pẹlu fun arakunrin rẹ̀ ati fun iya rẹ̀.
54Nwọn si jẹ, nwọn si mu, on ati awọn ọkunrin ti o wà pẹlu rẹ̀, nwọn si wọ̀ nibẹ̀ li oru ijọ́ na; nwọn si dide li owurọ̀, o si wipe, Ẹ rán mi lọ si ọdọ oluwa mi.
55Arakunrin ati iya rẹ̀ si wipe, Jẹ ki omidan na ki o ba wa joko ni ijọ́ melokan, bi ijọ́ mẹwa, lẹhin eyini ni ki o ma wa lọ.
56On si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe da mi duro, OLUWA sa ti ṣe ọ̀na mi ni rere; ẹ rán mi, ki emi ki o le tọ̀ oluwa mi lọ.
57Nwọn si wipe, Awa o pè omidan na, a o si bère li ẹnu rẹ̀.
58Nwọn si pè Rebeka, nwọn bi i pe, Iwọ o bá ọkunrin yi lọ? o si wipe, Emi o lọ.
59Nwọn si rán Rebeka, arabinrin wọn, ati olutọ rẹ̀, ati iranṣẹ Abrahamu, ati awọn ọkunrin rẹ̀ lọ.
60Nwọn si súre fun Rebeka, nwọn si wi fun u pe, Iwọ li arabinrin wa, ki iwọ, ki o si ṣe iya ẹgbẹgbẹrun lọnà ẹgbãrun, ki irú-ọmọ rẹ ki o si ni ẹnubode awọn ti o korira wọn.
61Rebeka si dide, ati awọn omidan rẹ̀, nwọn si gùn awọn ibakasiẹ, nwọn si tẹle ọkunrin na: iranṣẹ na si mu Rebeka, o si ba tirẹ̀ lọ.
62Isaaki si nti ọ̀na kanga Lahai-roi mbọ̀wá; nitori ilu ìha gusù li on ngbé.
63Isaaki si jade lọ ṣe àṣaro li oko li aṣalẹ: o si gbé oju rẹ̀ soke, o si ri i, si kiyesi i, awọn ibakasiẹ mbọ̀wá.
64Rebeka si gbé oju rẹ̀ soke, nigbati o ri Isaaki, o sọkalẹ lori ibakasiẹ.
65Nitori ti o ti bi iranṣẹ na pe, ọkunrin ewo li o nrìn bọ̀ li oko lati wá pade wa nì? Iranṣẹ na si ti wi fun u pe, oluwa mi ni: nitori na li o ṣe mu iboju o fi bò ara rẹ̀.
66Iranṣẹ na si rò ohun gbogbo ti on ṣe fun Isaaki.
67Isaaki si mu u wá si inu agọ́ Sara, iya rẹ̀, o si mu Rebeka, o di aya rẹ̀; o si fẹ́ ẹ; a si tu Isaaki ninu lẹhin ikú iya rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Gẹn 24: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa