Gal 3:9-16

Gal 3:9-16 YBCV

Gẹgẹ bẹ̃li awọn ti iṣe ti igbagbọ́ jẹ ẹni alabukún-fun pẹlu Abrahamu olododo. Nitoripe iye awọn ti mbẹ ni ipa iṣẹ ofin mbẹ labẹ ègún: nitoriti a ti kọ ọ pe, Ifibu ni olukuluku ẹniti kò duro ninu ohun gbogbo ti a kọ sinu iwe ofin lati mã ṣe wọn. Nitori o daniloju pe, a kò da ẹnikẹni lare niwaju Ọlọrun nipa iṣẹ ofin: nitoripe, Olododo yio yè nipa igbagbọ́. Ofin kì si iṣe ti igbagbọ́: ṣugbọn Ẹniti nṣe wọn yio yè nipasẹ wọn. Kristi ti rà wa pada kuro lọwọ egun ofin, ẹniti a fi ṣe egun fun wa: nitoriti a ti kọ ọ pe, Ifibu li olukuluku ẹniti a fi kọ́ sori igi: Ki ibukún Abrahamu ki o le wá sori awọn Keferi nipa Kristi Jesu; ki awa ki o le gbà ileri Ẹmí nipa igbagbọ́. Ará, emi nsọ̀rọ bi enia; bi o tilẹ jẹ pe majẹmu enia ni, ṣugbọn bi a ba ti fi idi rẹ̀ mulẹ, kò si ẹniti o le sọ ọ di asan, tabi ti o le fi kún u mọ́. Njẹ fun Abrahamu ati fun irú-ọmọ rẹ̀ li a ti ṣe awọn ileri na. On kò wipe, Fun awọn irú ọmọ, bi ẹnipe ọ̀pọlọpọ; ṣugbọn bi ẹnipe ọ̀kan, ati fun irú-ọmọ rẹ, eyiti iṣe Kristi.