Gal 3:9-16

Gal 3:9-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn tí i ṣe tí ìgbàgbọ́ jẹ́ ẹni alábùkún fún pẹ̀lú Abrahamu olódodo. Nítorí pé iye àwọn tí ń bẹ ni ipa iṣẹ́ òfin ń bẹ lábẹ́ ègún: nítorí tí a tí kọ ọ́ pé, “Ìfibú ni olúkúlùkù ẹni tí kò dúró nínú ohun gbogbo tí a kọ sínú ìwé òfin láti máa ṣe wọ́n. Nítorí ó dánilójú pé, a kò dá ẹnikẹ́ni láre níwájú Ọlọ́run nípa iṣẹ́ òfin: nítorí pé, olódodo yóò yè nípa ìgbàgbọ́.” Òfin kì í sì í ṣe ti ìgbàgbọ́: ṣùgbọ́n “Ẹni tí ó ba ṣe, yóò yè nípa wọn.” Kristi ti rà wá padà kúrò lọ́wọ́ ègún òfin, ẹni tí a fi ṣe ègún fún wa: nítorí tí a ti kọ ọ́ pé, “Ìfibú ni olúkúlùkù ẹni tí a fi kọ́ sórí igi.” Ó gbà wá là ki ìbùkún Abrahamu ba à lè wá sórí àwọn aláìkọlà nípa Kristi Jesu; kí àwa ba à lè gba ìlérí Ẹ̀mí nípa ìgbàgbọ́. Ará, èmi ń sọ̀rọ̀ bí ènìyàn, gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú ènìyàn ti a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, kò sí ẹni tí ó lè sọ ọ́ di asán, tàbí tí ó lè fi kún un mọ́. Ǹjẹ́ fún Abrahamu àti fún irú-ọmọ rẹ̀ ni a ti ṣe àwọn ìlérí náà. Ìwé Mímọ́ kò ṣe wí pé, Fún àwọn irú-ọmọ rẹ̀, bí ẹni pé ọ̀pọ̀lọpọ̀; ṣùgbọ́n bí ẹni pé ọ̀kan ṣoṣo, àti fún irú-ọmọ rẹ̀, èyí tí í ṣe Kristi.