Gal 3:7-14

Gal 3:7-14 YBCV

Nitorina ki ẹnyin ki o mọ̀ pe awọn ti iṣe ti igbagbọ́, awọn na ni iṣe ọmọ Abrahamu. Bi iwe-mimọ́ si ti ri i tẹlẹ pe, Ọlọrun yio dá awọn Keferi lare nipa igbagbọ́, o ti wasu ihinrere ṣaju fun Abrahamu, o nwipe, Ninu rẹ li a o bukún fun gbogbo orilẹ-ède. Gẹgẹ bẹ̃li awọn ti iṣe ti igbagbọ́ jẹ ẹni alabukún-fun pẹlu Abrahamu olododo. Nitoripe iye awọn ti mbẹ ni ipa iṣẹ ofin mbẹ labẹ ègún: nitoriti a ti kọ ọ pe, Ifibu ni olukuluku ẹniti kò duro ninu ohun gbogbo ti a kọ sinu iwe ofin lati mã ṣe wọn. Nitori o daniloju pe, a kò da ẹnikẹni lare niwaju Ọlọrun nipa iṣẹ ofin: nitoripe, Olododo yio yè nipa igbagbọ́. Ofin kì si iṣe ti igbagbọ́: ṣugbọn Ẹniti nṣe wọn yio yè nipasẹ wọn. Kristi ti rà wa pada kuro lọwọ egun ofin, ẹniti a fi ṣe egun fun wa: nitoriti a ti kọ ọ pe, Ifibu li olukuluku ẹniti a fi kọ́ sori igi: Ki ibukún Abrahamu ki o le wá sori awọn Keferi nipa Kristi Jesu; ki awa ki o le gbà ileri Ẹmí nipa igbagbọ́.