Gal 3:7-14
Gal 3:7-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina ki ẹnyin ki o mọ̀ pe awọn ti iṣe ti igbagbọ́, awọn na ni iṣe ọmọ Abrahamu. Bi iwe-mimọ́ si ti ri i tẹlẹ pe, Ọlọrun yio dá awọn Keferi lare nipa igbagbọ́, o ti wasu ihinrere ṣaju fun Abrahamu, o nwipe, Ninu rẹ li a o bukún fun gbogbo orilẹ-ède. Gẹgẹ bẹ̃li awọn ti iṣe ti igbagbọ́ jẹ ẹni alabukún-fun pẹlu Abrahamu olododo. Nitoripe iye awọn ti mbẹ ni ipa iṣẹ ofin mbẹ labẹ ègún: nitoriti a ti kọ ọ pe, Ifibu ni olukuluku ẹniti kò duro ninu ohun gbogbo ti a kọ sinu iwe ofin lati mã ṣe wọn. Nitori o daniloju pe, a kò da ẹnikẹni lare niwaju Ọlọrun nipa iṣẹ ofin: nitoripe, Olododo yio yè nipa igbagbọ́. Ofin kì si iṣe ti igbagbọ́: ṣugbọn Ẹniti nṣe wọn yio yè nipasẹ wọn. Kristi ti rà wa pada kuro lọwọ egun ofin, ẹniti a fi ṣe egun fun wa: nitoriti a ti kọ ọ pe, Ifibu li olukuluku ẹniti a fi kọ́ sori igi: Ki ibukún Abrahamu ki o le wá sori awọn Keferi nipa Kristi Jesu; ki awa ki o le gbà ileri Ẹmí nipa igbagbọ́.
Gal 3:7-14 Yoruba Bible (YCE)
kí ó ye yín pé àwọn ẹni tí ó bá gbàgbọ́ ni ọmọ Abrahamu. Ìwé Mímọ́ ti sọ tẹ́lẹ̀ pé nípa igbagbọ ni Ọlọrun yóo fi dá àwọn tí kì í ṣe Juu láre, ó waasu ìyìn rere fún Abrahamu pé, “Gbogbo àwọn tí kì í ṣe Juu yóo di ẹni ibukun nípasẹ̀ rẹ.” Èyí ni pé àwọn tí ó gbàgbọ́ rí ibukun gbà, bí Abrahamu ti rí ibukun gbà nítorí pé ó gbàgbọ́. A ti fi gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé iṣẹ́ òfin gégùn-ún. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ègbé ni fún gbogbo ẹni tí kò bá máa ṣe ohun gbogbo tí a kọ sinu ìwé òfin.” Ó dájú pé kò sí ẹnikẹ́ni tí Ọlọrun yóo dá láre nípa òfin, nítorí a kà á pé, “Olódodo yóo wà láàyè nípa igbagbọ.” Ṣugbọn òfin kì í ṣe igbagbọ, nítorí a kà á pé, “Ẹni tí ó bá ń pa gbogbo òfin mọ́ yóo wà láàyè nípa wọn.” Kristi ti rà wá pada kúrò lábẹ́ ègún òfin, ó ti di ẹni ègún nítorí tiwa, nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ègbé ni fún gbogbo ẹni tí wọ́n bá gbé kọ́ sórí igi.” Ìdí rẹ̀ ni pé kí ibukun Abrahamu lè kan àwọn tí kì í ṣe Juu nípasẹ̀ Kristi Jesu, kí á lè gba ìlérí Ẹ̀mí nípa igbagbọ.
Gal 3:7-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ jẹ́ kí ó yé é yín nígbà náà pé, àwọn ti ó gbàgbọ́, àwọn náà ní í ṣe ọmọ Abrahamu. Bí ìwé mímọ́ sì tí wí tẹ́lẹ̀ pé, Ọlọ́run yóò dá aláìkọlà láre nípa ìgbàgbọ́, ó tí wàásù ìhìnrere ṣáájú fún Abrahamu, ó ń wí pé, “Nínú rẹ̀ ni a ó bùkún fún gbogbo orílẹ̀-èdè.” Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn tí i ṣe tí ìgbàgbọ́ jẹ́ ẹni alábùkún fún pẹ̀lú Abrahamu olódodo. Nítorí pé iye àwọn tí ń bẹ ni ipa iṣẹ́ òfin ń bẹ lábẹ́ ègún: nítorí tí a tí kọ ọ́ pé, “Ìfibú ni olúkúlùkù ẹni tí kò dúró nínú ohun gbogbo tí a kọ sínú ìwé òfin láti máa ṣe wọ́n. Nítorí ó dánilójú pé, a kò dá ẹnikẹ́ni láre níwájú Ọlọ́run nípa iṣẹ́ òfin: nítorí pé, olódodo yóò yè nípa ìgbàgbọ́.” Òfin kì í sì í ṣe ti ìgbàgbọ́: ṣùgbọ́n “Ẹni tí ó ba ṣe, yóò yè nípa wọn.” Kristi ti rà wá padà kúrò lọ́wọ́ ègún òfin, ẹni tí a fi ṣe ègún fún wa: nítorí tí a ti kọ ọ́ pé, “Ìfibú ni olúkúlùkù ẹni tí a fi kọ́ sórí igi.” Ó gbà wá là ki ìbùkún Abrahamu ba à lè wá sórí àwọn aláìkọlà nípa Kristi Jesu; kí àwa ba à lè gba ìlérí Ẹ̀mí nípa ìgbàgbọ́.