Eks 4:10-12

Eks 4:10-12 YBCV

Mose si wi fun OLUWA pe, Oluwa, emi ki iṣe ẹni ọ̀rọ-sisọ nigba atijọ wá, tabi lati igbati o ti mbá iranṣẹ rẹ sọ̀rọ: ṣugbọn olohùn wuwo ni mi, ati alahọn wuwo. OLUWA si wi fun u pe, Tali o dá ẹnu enia? tabi tali o dá odi, tabi aditi, tabi ariran, tabi afọju? Emi OLUWA ha kọ́? Njẹ lọ nisisiyi, emi o si pẹlu ẹnu rẹ, emi o si kọ́ ọ li eyiti iwọ o wi.