Mose si sọ fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli pe, Eyi li ohun ti OLUWA palaṣẹ, wipe,
Ẹnyin mú ọrẹ wá lati inu ara nyin fun OLUWA: ẹnikẹni ti ọkàn rẹ̀ fẹ́, ki o mú u wá, li ọrẹ fun OLUWA; wurà, ati fadakà, ati idẹ;
Ati aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ didara, ati irun ewurẹ;
Ati awọ àgbo ti a sè ni pupa, ati awọ seali, ati igi ṣittimu;
Ati oróro fun fitila, ati olõrùn fun oróro itasori, ati fun turari didùn;
Ati okuta oniki, ati okuta ti a o tò si ẹ̀wu-efodi, ati si igbàiya.
Gbogbo ọlọgbọ́n inú ninu nyin yio si wá, yio si wá ṣiṣẹ gbogbo ohun ti OLUWA palaṣẹ;
Ibugbé na, ti on ti agọ́ rẹ̀, ati ibori rẹ̀, kọkọrọ rẹ̀, ati apáko rẹ̀, ọpá rẹ̀, ọwọ̀n rẹ̀, ati ihò-ìtẹbọ rẹ̀;
Apoti nì, ati ọpá rẹ̀, itẹ́-ãnu nì, ati aṣọ-ikele na;
Tabili na, ati ọpá rẹ̀, ati ohun-èlo rẹ̀ gbogbo, ati àkara ifihàn nì;
Ati ọpà-fitila na fun titanna, ati ohun-elo rẹ̀, ati fitila rẹ̀, pẹlu oróro fun titanna.
Ati pẹpẹ turari, ati ọpá rẹ̀, ati oróro itasori, ati turari didùn, ati aṣọ-sisorọ̀ fun ẹnu-ọ̀na, ani atiwọle ẹnu agọ́ na;
Ati pẹpẹ ẹbọsisun, ti on ti àwọn oju-àro idẹ rẹ̀, ati ọpá rẹ̀, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀, agbada na ti on ti ẹsẹ rẹ̀;
Aṣọ-isorọ̀ ti agbalá, ọwọ̀n rẹ̀, ati ihò-ìtẹbọ rẹ̀, ati aṣọ-isorọ̀ fun ẹnu-ọ̀na agbalá na;
Ekàn agọ́ na, ati ekàn agbalá na, ati okùn wọn;
Aṣọ ìsin wọnni, lati sìn ni ibi mimọ́, aṣọ mimọ́ wọnni fun Aaroni alufa, ati aṣọ awọn ọmọ rẹ̀, lati ma fi ṣe iṣẹ alufa.