Eks 35:4-19

Eks 35:4-19 Bibeli Mimọ (YBCV)

Mose si sọ fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli pe, Eyi li ohun ti OLUWA palaṣẹ, wipe, Ẹnyin mú ọrẹ wá lati inu ara nyin fun OLUWA: ẹnikẹni ti ọkàn rẹ̀ fẹ́, ki o mú u wá, li ọrẹ fun OLUWA; wurà, ati fadakà, ati idẹ; Ati aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ didara, ati irun ewurẹ; Ati awọ àgbo ti a sè ni pupa, ati awọ seali, ati igi ṣittimu; Ati oróro fun fitila, ati olõrùn fun oróro itasori, ati fun turari didùn; Ati okuta oniki, ati okuta ti a o tò si ẹ̀wu-efodi, ati si igbàiya. Gbogbo ọlọgbọ́n inú ninu nyin yio si wá, yio si wá ṣiṣẹ gbogbo ohun ti OLUWA palaṣẹ; Ibugbé na, ti on ti agọ́ rẹ̀, ati ibori rẹ̀, kọkọrọ rẹ̀, ati apáko rẹ̀, ọpá rẹ̀, ọwọ̀n rẹ̀, ati ihò-ìtẹbọ rẹ̀; Apoti nì, ati ọpá rẹ̀, itẹ́-ãnu nì, ati aṣọ-ikele na; Tabili na, ati ọpá rẹ̀, ati ohun-èlo rẹ̀ gbogbo, ati àkara ifihàn nì; Ati ọpà-fitila na fun titanna, ati ohun-elo rẹ̀, ati fitila rẹ̀, pẹlu oróro fun titanna. Ati pẹpẹ turari, ati ọpá rẹ̀, ati oróro itasori, ati turari didùn, ati aṣọ-sisorọ̀ fun ẹnu-ọ̀na, ani atiwọle ẹnu agọ́ na; Ati pẹpẹ ẹbọsisun, ti on ti àwọn oju-àro idẹ rẹ̀, ati ọpá rẹ̀, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀, agbada na ti on ti ẹsẹ rẹ̀; Aṣọ-isorọ̀ ti agbalá, ọwọ̀n rẹ̀, ati ihò-ìtẹbọ rẹ̀, ati aṣọ-isorọ̀ fun ẹnu-ọ̀na agbalá na; Ekàn agọ́ na, ati ekàn agbalá na, ati okùn wọn; Aṣọ ìsin wọnni, lati sìn ni ibi mimọ́, aṣọ mimọ́ wọnni fun Aaroni alufa, ati aṣọ awọn ọmọ rẹ̀, lati ma fi ṣe iṣẹ alufa.

Eks 35:4-19 Yoruba Bible (YCE)

Mose sọ fún gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA pa láṣẹ, ó ní, ‘Ẹ gba ọrẹ jọ fún OLUWA láàrin ara yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́, lè mú ọrẹ wá fún OLUWA. Àwọn ọrẹ náà ni: wúrà, fadaka ati idẹ, aṣọ aláwọ̀ aró, ti aláwọ̀ elése àlùkò, ati aṣọ pupa, aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, ati irun ewúrẹ́; awọ àgbò tí wọ́n ṣe ní àwọ̀ pupa ati awọ ewúrẹ́, igi akasia, òróró ìtànná, àwọn èròjà fún òróró ìyàsímímọ́ ati fún turari olóòórùn dídùn, òkúta onikisi ati òkúta tí wọn yóo tò sí ara efodu ati sí ara aṣọ ìgbàyà.’ “Kí gbogbo ọkunrin tí ó bá mọ iṣẹ́ ọwọ́ ninu yín jáde wá láti ṣe àwọn nǹkan tí OLUWA pa láṣẹ wọnyi: àgọ́ àjọ, ati àwọn ìbòrí rẹ, àwọn ìkọ́ rẹ̀ ati àwọn àkànpọ̀ igi rẹ̀, àwọn ọ̀pá rẹ̀, àwọn òpó rẹ̀, ati àwọn ìtẹ́lẹ̀ wọn. Àpótí ẹ̀rí, ati àwọn ọ̀pá rẹ̀, ìtẹ́ àánú rẹ̀, ati aṣọ títa rẹ̀. Tabili, pẹlu àwọn ọ̀pá rẹ̀ ati gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀ pẹlu burẹdi ìfihàn orí rẹ̀. Ọ̀pá fìtílà fún iná títàn, ati àwọn ohun èlò tí ó jẹ mọ́ fìtílà rẹ̀ ati òróró fún iná títàn. Pẹpẹ turari, ati àwọn ọ̀pá rẹ̀ ati òróró ìyàsímímọ́, ati turari olóòórùn dídùn, ati àwọn aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà. Pẹpẹ ẹbọ sísun tòun ti ojú ààrò onídẹ rẹ̀, pẹlu àwọn ọ̀pá rẹ̀ ati àwọn ohun èlò tí ó jẹ mọ́ ti pẹpẹ ẹbọ, agbada omi ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Àwọn aṣọ títa ti àgbàlá ati àwọn òpó rẹ̀ ati ìtẹ́lẹ̀ àwọn òpó ati aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà. Àwọn èèkàn àgọ́, ati àwọn èèkàn àgbàlá pẹlu àwọn okùn wọn; àwọn aṣọ tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí fún ṣíṣe iṣẹ́ alufaa níbi mímọ́, ati àwọn ẹ̀wù mímọ́ fún Aaroni alufaa, ati ẹ̀wù iṣẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀, tí wọn yóo máa fi ṣe iṣẹ́ alufaa.”

Eks 35:4-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)

Mose sọ fún gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli pé, “Èyí ni ohun tí OLúWA pàṣẹ. Láti inú ohun tí ẹ ni ni kí ẹ ti mú ọrẹ fún OLúWA. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ ni kí ó mú ọrẹ fún OLúWA ní ti: “wúrà, fàdákà àti idẹ; aṣọ aláró, elése àlùkò, òdòdó àti ọ̀gbọ̀ dáradára; àti irun ewúrẹ́; awọ àgbò tí a kùn ní pupa àti awọ màlúù; odò igi kasia; òróró olifi fún títan iná; olóòórùn fún òróró ìtasórí, àti fún tùràrí dídùn; òkúta óníkìsì àti òkúta tí a tò sí ẹ̀wù efodu àti ìgbàyà. “Gbogbo ẹni tí ó ní ọgbọ́n láàrín yín, kí ó wa, kí ó sì wá ṣe gbogbo ohun tí OLúWA ti pàṣẹ: “àgọ́ náà pẹ̀lú àgọ́ rẹ àti ìbòrí rẹ̀, kọ́kọ́rọ́ rẹ̀, pákó rẹ̀, ọ̀pá rẹ̀, ọ̀wọ́n rẹ̀ àti ihò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀; Àpótí náà pẹ̀lú ọ̀pá rẹ̀, ìbò àánú àti aṣọ títa náà tí ó síji bò ó. Tábìlì náà pẹ̀lú òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀ àti àkàrà ìfihàn náà. Ọ̀pá fìtílà tí ó wà fún títanná pẹ̀lú ohun èlò rẹ̀, fìtílà àti òróró fún títanná. Pẹpẹ tùràrí náà pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀, òróró ìtasórí àti tùràrí dídùn; aṣọ títa fún ọ̀nà ìlẹ̀kùn ní ẹnu-ọ̀nà sí àgọ́ náà. Pẹpẹ ẹbọ sísun pẹ̀lú ojú ààrò idẹ rẹ̀, òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀; agbada idẹ pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀. Aṣọ títa ti àgbàlá pẹ̀lú, ọ̀wọ́n àti ihò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀ àti aṣọ títa fún ẹnu-ọ̀nà àgbàlá náà. Èèkàn àgọ́ náà fún àgọ́ náà àti fún àgbàlá àti okùn wọn. Aṣọ híhun láti ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́ aṣọ mímọ́ fún Aaroni àlùfáà àti aṣọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n sìn bí àlùfáà.”