Eks 12:17-30

Eks 12:17-30 YBCV

Ẹ o si kiyesi ajọ aiwukàra; nitori li ọjọ́ na gan ni mo mú ogun nyin jade kuro ni ilẹ Egipti; nitorina ni ki ẹ ma kiyesi ọjọ́ na ni iran-iran nyin nipa ìlana lailai. Li oṣù kini li ọjọ kẹrinla oṣù na li aṣalẹ li ẹ o jẹ àkara alaiwu, titi yio fi di ọjọ́ kọkanlelogun oṣù na li aṣalẹ. Ni ọjọ́ meje ni ki a máṣe ri iwukàra ninu ile nyin: nitori ẹniti o ba jẹ eyiti a wu, ọkàn na li a o ke kuro ninu ijọ Israeli, iba ṣe alejò, tabi ẹniti a bi ni ilẹ na. Ẹ kò gbọdọ jẹ ohunkohun ti a wu; ninu ibugbé nyin gbogbo li ẹnyin o jẹ àkara alaiwu. Nigbana ni Mose pè gbogbo awọn àgba Israeli, o si wi fun wọn pe, Ẹ jade lọ imú ọdọ-agutan fun ara nyin, gẹgẹ bi idile nyin, ki ẹ si pa irekọja na. Ẹnyin o si mú ìdi ewe-hissopu, ẹ o si fi bọ̀ ẹ̀jẹ ti o wà ninu awokoto, ẹ o si fi ẹ̀jẹ na ti o wà ninu awokoto kùn ara atẹrigba, ati opó ìha mejeji; ẹnikẹni ninu nyin kò si gbọdọ jade lati ẹnu-ọ̀na ile rẹ̀ titi yio fi di owurọ̀. Nitoriti OLUWA yio kọja lati kọlù awọn ara Egipti; nigbati o ba si ri ẹ̀jẹ lara atẹrigba, ati lara opó ìha mejeji, OLUWA yio si rekọja ẹnu-ọ̀na na, ki yio jẹ ki apanirun ki o wọle nyin wá lati kọlù nyin. Ẹ o si ma kiyesi nkan yi nipa ìlana fun ọ, ati fun awọn ọmọ rẹ lailai. O si ṣe, nigbati ẹ ba dé ilẹ na ti OLUWA yio fi fun nyin, gẹgẹ bi o ti wi, bẹ̃li ẹ o si ma kiyesi ìsin yi. Yio si ṣe nigbati awọn ọmọ nyin ba bi nyin pe, Eredi ìsin yi? Ki ẹ wipe, Ẹbọ irekọja OLUWA ni, ẹniti o rekọja ile awọn ọmọ Israeli ni Egipti, nigbati o kọlù awọn ara Egipti, ti o si dá ile wa si. Awọn enia si tẹriba nwọn si sìn. Awọn ọmọ Israeli si lọ, nwọn si ṣe bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose ati Aaroni, bẹ̃ni nwọn ṣe. O si ṣe lãrin ọganjọ́ li OLUWA pa gbogbo awọn akọ́bi ni ilẹ Egipti, lati akọ́bi Farao lọ ti o joko lori itẹ́ rẹ̀ titi o fi dé akọ́bi ẹrú ti o wà ni túbu; ati gbogbo akọ́bi ẹran-ọ̀sin. Farao si dide li oru, on ati gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀, ati awọn ara Egipti; igbe nla si ta ni Egipti; nitoriti kò si ile kan ti enia kan kò kú.