Eks 12:17-30

Eks 12:17-30 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ẹ o si kiyesi ajọ aiwukàra; nitori li ọjọ́ na gan ni mo mú ogun nyin jade kuro ni ilẹ Egipti; nitorina ni ki ẹ ma kiyesi ọjọ́ na ni iran-iran nyin nipa ìlana lailai. Li oṣù kini li ọjọ kẹrinla oṣù na li aṣalẹ li ẹ o jẹ àkara alaiwu, titi yio fi di ọjọ́ kọkanlelogun oṣù na li aṣalẹ. Ni ọjọ́ meje ni ki a máṣe ri iwukàra ninu ile nyin: nitori ẹniti o ba jẹ eyiti a wu, ọkàn na li a o ke kuro ninu ijọ Israeli, iba ṣe alejò, tabi ẹniti a bi ni ilẹ na. Ẹ kò gbọdọ jẹ ohunkohun ti a wu; ninu ibugbé nyin gbogbo li ẹnyin o jẹ àkara alaiwu. Nigbana ni Mose pè gbogbo awọn àgba Israeli, o si wi fun wọn pe, Ẹ jade lọ imú ọdọ-agutan fun ara nyin, gẹgẹ bi idile nyin, ki ẹ si pa irekọja na. Ẹnyin o si mú ìdi ewe-hissopu, ẹ o si fi bọ̀ ẹ̀jẹ ti o wà ninu awokoto, ẹ o si fi ẹ̀jẹ na ti o wà ninu awokoto kùn ara atẹrigba, ati opó ìha mejeji; ẹnikẹni ninu nyin kò si gbọdọ jade lati ẹnu-ọ̀na ile rẹ̀ titi yio fi di owurọ̀. Nitoriti OLUWA yio kọja lati kọlù awọn ara Egipti; nigbati o ba si ri ẹ̀jẹ lara atẹrigba, ati lara opó ìha mejeji, OLUWA yio si rekọja ẹnu-ọ̀na na, ki yio jẹ ki apanirun ki o wọle nyin wá lati kọlù nyin. Ẹ o si ma kiyesi nkan yi nipa ìlana fun ọ, ati fun awọn ọmọ rẹ lailai. O si ṣe, nigbati ẹ ba dé ilẹ na ti OLUWA yio fi fun nyin, gẹgẹ bi o ti wi, bẹ̃li ẹ o si ma kiyesi ìsin yi. Yio si ṣe nigbati awọn ọmọ nyin ba bi nyin pe, Eredi ìsin yi? Ki ẹ wipe, Ẹbọ irekọja OLUWA ni, ẹniti o rekọja ile awọn ọmọ Israeli ni Egipti, nigbati o kọlù awọn ara Egipti, ti o si dá ile wa si. Awọn enia si tẹriba nwọn si sìn. Awọn ọmọ Israeli si lọ, nwọn si ṣe bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose ati Aaroni, bẹ̃ni nwọn ṣe. O si ṣe lãrin ọganjọ́ li OLUWA pa gbogbo awọn akọ́bi ni ilẹ Egipti, lati akọ́bi Farao lọ ti o joko lori itẹ́ rẹ̀ titi o fi dé akọ́bi ẹrú ti o wà ni túbu; ati gbogbo akọ́bi ẹran-ọ̀sin. Farao si dide li oru, on ati gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀, ati awọn ara Egipti; igbe nla si ta ni Egipti; nitoriti kò si ile kan ti enia kan kò kú.

Eks 12:17-30 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ óo máa ṣe àjọ̀dún ìrántí àjọ àìwúkàrà, nítorí ọjọ́ yìí ni ọjọ́ tí mo ko yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. Nítorí náà ẹ óo máa ṣe ìrántí ọjọ́ náà bí ìlànà ati ẹ̀yin ati àwọn arọmọdọmọ yín títí lae. Láti ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrinla oṣù kinni yìí títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kọkanlelogun oṣù náà, burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ni ẹ gbọdọ̀ máa jẹ. Kò gbọdọ̀ sí ìwúkàrà ninu ilé yín fún ọjọ́ mejeeje, nítorí pé bí ẹnikẹ́ni bá jẹ burẹdi tí ó ní ìwúkàrà ninu, a kò ní ka irú ẹni bẹ́ẹ̀ kún àwọn eniyan Israẹli mọ́, kì báà jẹ́ àlejò tabi onílé ní ilẹ̀ náà. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó ní ìwúkàrà ninu; ninu gbogbo ilé yín patapata, burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu ni ẹ gbọdọ̀ máa jẹ.” Mose bá pe gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli jọ, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ ṣa ọ̀dọ́ aguntan kọ̀ọ̀kan ní ìdílé yín kọ̀ọ̀kan, kí ẹ sì pa á fún ìrékọjá. Ẹ mú ìdì ewé hisopu, kí ẹ tì í bọ ẹ̀jẹ̀ tí ẹ bá gbè sinu àwo kòtò kan, kí ẹ fi ẹ̀jẹ̀ náà kun àtẹ́rígbà ati òpó ìlẹ̀kùn mejeeji. Ẹnikẹ́ni ninu yín kò sì gbọdọ̀ jáde ninu ilé títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji. Nítorí pé, OLUWA yóo rékọjá, yóo sì pa àwọn ará Ijipti. Ṣugbọn nígbà tí ó bá rí ẹ̀jẹ̀ lára àtẹ́rígbà ati lára òpó ẹnu ọ̀nà mejeeji, OLUWA yóo ré ẹnu ọ̀nà náà kọjá, kò sì ní jẹ́ kí apanirun wọ ilé yín láti pa yín. Ẹ̀yin ati àwọn arọmọdọmọ yín, ẹ gbọdọ̀ máa pa ìlànà yìí mọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin títí lae. Nígbà tí ẹ bá sì dé ilẹ̀ tí OLUWA yóo fún yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí, ẹ gbọdọ̀ máa ṣe ìsìn yìí. Nígbà tí àwọn ọmọ yín bá sì bi yín léèrè pé, ‘Kí ni ìtumọ̀ ìsìn yìí?’ ẹ óo dá wọn lóhùn pé, ‘Ẹbọ ìrékọjá OLUWA ni, nítorí pé ó ré ilé àwọn eniyan Israẹli kọjá ní Ijipti, nígbà tí ó ń pa àwọn ará Ijipti, ṣugbọn ó dá àwọn ilé wa sí.’ ” Àwọn eniyan Israẹli wólẹ̀, wọ́n sì sin OLUWA. Wọ́n bá lọ, wọ́n sì ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose ati Aaroni. Nígbà tí ó di ọ̀gànjọ́ òru, OLUWA lu gbogbo àwọn àkọ́bí ilẹ̀ Ijipti pa, ó bẹ̀rẹ̀ láti orí àrẹ̀mọ ọba Farao tí ó wà lórí ìtẹ́, títí kan àkọ́bí ẹrú tí ó wà ninu ọgbà ẹ̀wọ̀n, ati àkọ́bí gbogbo ẹran ọ̀sìn. Farao bá dìde ní ọ̀gànjọ́ òru, òun ati gbogbo àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀, ati gbogbo àwọn ará Ijipti. Igbe ẹkún ńlá sì sọ ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti, nítorí pé kò sí ẹyọ ilé kan tí eniyan kò ti kú.

Eks 12:17-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)

“Ẹ ó sì kíyèsí àjọ àìwúkàrà, nítorí ní ọjọ́ náà gan an ni mo mú ogun yín jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti. Nítorí náà ni kí ẹ máa kíyèsi ọjọ́ náà ní ìran-ìran yín bí ìlànà tí yóò wà títí ayé. Àkàrà ti kò ni ìwúkàrà ni ẹ̀yin yóò jẹ láti ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrìnlá títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kọ̀kànlélógún oṣù àkọ́kọ́. Fún ọjọ́ méje ni ẹ kò gbọdọ̀ ni ìwúkàrà nínú ilé yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ohun tí ó ni ìwúkàrà nínú ni a ó yọ kúrò ni àárín àwùjọ Israẹli, ìbá à ṣe àlejò tàbí ẹni tí a bí ní ilẹ̀ náà. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí a fi ìwúkàrà ṣe. Ní ibikíbi tí ẹ̀yin bá ń gbé, kí ẹ̀yin kí ó jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà.” Ní ìgbà náà ni Mose pé gbogbo àwọn àgbàgbà Israẹli jọ, ó sì sọ fún wọn pé, “Ẹ jáde lọ, kí ẹ sì yan ọ̀dọ́-àgùntàn fún àwọn ìdílé yín, kí ẹ sì pa ẹran àjọ ìrékọjá OLúWA. Ẹ̀yin yóò sì mú ìdí-ewé hísópù, ẹ tì í bọ inú ẹ̀jẹ̀ tí ó wà nínú ọpọ́n kí ẹ sì fi kun òkè à bá wọ ẹnu-ọ̀nà ilé yín àti ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ìlẹ̀kùn yín. Ẹnikẹ́ni nínú yín kò gbọdọ̀ jáde sí òde títí di òwúrọ̀. Ní ìgbà tí OLúWA bá ń lọ káàkiri ní ilẹ̀ Ejibiti láti kọlù wọn, yóò rí ẹ̀jẹ̀ ni òkè ẹnu-ọ̀nà àti ni ẹ̀gbẹ́ ẹnu-ọ̀nà ilé yín, yóò sì ré ẹnu-ọ̀nà ilé náà kọjá, kì yóò gba apanirun láààyè láti wọ inú ilé e yín láti kọlù yín. “Ẹ pa ìlànà yìí mọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun tí ẹ ó máa ṣe títí ayérayé láàrín yín àti àwọn ìran yín. Nígbà tí ẹ̀yin bá de ilẹ̀ tí OLúWA yóò fi fún un yín bí òun ti ṣe ìlérí, ẹ máa kíyèsi àjọ yìí. Ní ìgbà tí àwọn ọmọ yín bá béèrè lọ́wọ́ yín, ‘Kí ni ohun tí àjọ yìí túmọ̀ sí fún un yín?’ Ẹ sọ fún wọn ni ìgbà náà, ‘Ẹbọ ìrékọjá sí OLúWA ni, ẹni tí ó rékọjá ilé àwọn ọmọ Israẹli ni ìgbà tí ó kọlu àwọn ara Ejibiti. Tí ó si da wa sí nígbà ti ó pa àwọn ara Ejibiti.’ ” Àwọn ènìyàn sì tẹríba láti sìn. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti pàṣẹ fún Mose àti Aaroni. Ní ọ̀gànjọ́ òru OLúWA kọlu gbogbo àwọn àkọ́bí ilẹ̀ Ejibiti, láti orí àkọ́bí. Farao tí ó wà ní orí ìtẹ́ títí dé orí àkọ́bí ẹlẹ́wọ̀n tí ó wà nínú túbú àti àkọ́bí ẹran ọ̀sìn pẹ̀lú. Farao àti àwọn ìjòyè rẹ̀ àti gbogbo àwọn ara Ejibiti dìde ní ọ̀gànjọ́ òru, igbe ẹkún ńlá sì gba gbogbo ilẹ̀ Ejibiti, nítorí kò sí ilé kan tí ó yọ sílẹ̀ tí ènìyàn kan kò ti kú.