Eks 1:1-6

Eks 1:1-6 YBCV

NJẸ orukọ awọn ọmọ Israeli, ti o wá si Egipti pẹlu Jakobu ni wọnyi; olukuluku pẹlu ile rẹ̀. Reubeni, Simeoni, Lefi, ati Judah; Issakari, Sebuluni, ati Benjamini; Dani ati Naftali, Gadi ati Aṣeri. Ati gbogbo ọkàn ti o ti inu Jakobu jade, o jẹ́ ãdọrin ọkàn: Josefu sa ti wà ni Egipti. Josefu si kú, ati gbogbo awọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo iran na.