Eks 1:1-6
Eks 1:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
NJẸ orukọ awọn ọmọ Israeli, ti o wá si Egipti pẹlu Jakobu ni wọnyi; olukuluku pẹlu ile rẹ̀. Reubeni, Simeoni, Lefi, ati Judah; Issakari, Sebuluni, ati Benjamini; Dani ati Naftali, Gadi ati Aṣeri. Ati gbogbo ọkàn ti o ti inu Jakobu jade, o jẹ́ ãdọrin ọkàn: Josefu sa ti wà ni Egipti. Josefu si kú, ati gbogbo awọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo iran na.
Eks 1:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Orúkọ àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n bá Jakọbu wá sí Ijipti nìwọ̀nyí, olukuluku pẹlu ìdílé rẹ̀: Reubẹni, Simeoni, Lefi, Juda, Isakari, Sebuluni, Bẹnjamini, Dani, Nafutali, Gadi ati Aṣeri. Gbogbo àwọn ọmọ ati àwọn ọmọ ọmọ Jakọbu jẹ́ aadọrin, Josẹfu ti wà ní Ijipti ní tirẹ̀. Nígbà tí ó yá, Josẹfu kú, gbogbo àwọn arakunrin rẹ̀ náà kú ní ọ̀kọ̀ọ̀kan títí tí gbogbo ìran náà fi kú tán.
Eks 1:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìwọ̀nyí ni àwọn orúkọ ọmọ Israẹli tí wọ́n bá Jakọbu lọ sí Ejibiti, ẹnìkọ̀ọ̀kan pẹ̀lú ìdílé rẹ̀: Reubeni, Simeoni, Lefi àti Juda; Isakari, Sebuluni àti Benjamini; Dani àti Naftali; Gadi àti Aṣeri. Àwọn ìran Jakọbu sì jẹ́ àádọ́rin ní àpapọ̀; Josẹfu sì ti wà ní Ejibiti. Wàyí o, Josẹfu àti gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo ìran náà kú