Iṣe Apo 4:9-12

Iṣe Apo 4:9-12 YBCV

Bi o ba ṣe pe a nwadi wa loni niti iṣẹ rere ti a ṣe lara abirùn na, bi a ti ṣe mu ọkunrin yi laradá; Ki eyi ki o yé gbogbo nyin ati gbogbo enia Israeli pe, li orukọ Jesu Kristi ti Nasareti, ti ẹnyin kàn mọ agbelebu, ti Ọlọrun gbé dide kuro ninu okú, nipa rẹ̀ li ọkunrin yi fi duro niwaju nyin ni dida ara ṣaṣa. Eyi li okuta ti a ti ọwọ́ ẹnyin ọmọle kọ̀ silẹ, ti o si di pàtaki igun ile. Kò si si igbala lọdọ ẹlomiran: nitori kò si orukọ miran labẹ ọrun ti a fifunni ninu enia, nipa eyiti a le fi gbà wa là.