II. Tes 3:6-12

II. Tes 3:6-12 YBCV

Awa si paṣẹ fun nyin, ará, li orukọ Jesu Kristi Oluwa wa, ki ẹnyin ki o yẹra kuro lọdọ olukuluku arakunrin, ti nrin ségesège, ti kì iṣe gẹgẹ bi ìlana ti nwọn ti gbà lọwọ wa. Nitori ẹnyin tikaranyin mọ̀ bi o ti yẹ ki ẹnyin na farawe wa: nitori awa kò rin ségesège larin nyin; Bẹ̃li awa kò si jẹ onjẹ ẹnikẹni lọfẹ; ṣugbọn ninu ãpọn ati lãlã li a nṣiṣẹ́ lọsan ati loru, ki awa ki o ma bã dẹruba ẹnikẹni ninu nyìn: Kì iṣe pe awa kò li agbara, ṣugbọn awa nfi ara wa ṣe apẹrẹ fun nyin ki ẹnyin kì o le mã farawe wa. Nitori nigbati awa tilẹ wà pẹlu nyin, eyi li awa palaṣẹ fun nyin, pe bi ẹnikẹni kò bá fẹ ṣiṣẹ, ki o maṣe jẹun. Nitori awa gburo awọn kan ti nrin ségesège larin nyìn ti nwọn kò nṣiṣẹ rara, ṣugbọn nwọn jẹ àtọjú-ile-kiri. Njẹ irú awọn ẹni bẹ̃ li awa npaṣẹ fun, ti a si nrọ̀ ninu Oluwa Jesu Kristi, pe ki nwọn ki o mã fi ìwa pẹlẹ ṣiṣẹ, ki nwọn ki o si mã jẹ onjẹ awọn tikarawọn.