II. Tes 3:6-12
II. Tes 3:6-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Awa si paṣẹ fun nyin, ará, li orukọ Jesu Kristi Oluwa wa, ki ẹnyin ki o yẹra kuro lọdọ olukuluku arakunrin, ti nrin ségesège, ti kì iṣe gẹgẹ bi ìlana ti nwọn ti gbà lọwọ wa. Nitori ẹnyin tikaranyin mọ̀ bi o ti yẹ ki ẹnyin na farawe wa: nitori awa kò rin ségesège larin nyin; Bẹ̃li awa kò si jẹ onjẹ ẹnikẹni lọfẹ; ṣugbọn ninu ãpọn ati lãlã li a nṣiṣẹ́ lọsan ati loru, ki awa ki o ma bã dẹruba ẹnikẹni ninu nyìn: Kì iṣe pe awa kò li agbara, ṣugbọn awa nfi ara wa ṣe apẹrẹ fun nyin ki ẹnyin kì o le mã farawe wa. Nitori nigbati awa tilẹ wà pẹlu nyin, eyi li awa palaṣẹ fun nyin, pe bi ẹnikẹni kò bá fẹ ṣiṣẹ, ki o maṣe jẹun. Nitori awa gburo awọn kan ti nrin ségesège larin nyìn ti nwọn kò nṣiṣẹ rara, ṣugbọn nwọn jẹ àtọjú-ile-kiri. Njẹ irú awọn ẹni bẹ̃ li awa npaṣẹ fun, ti a si nrọ̀ ninu Oluwa Jesu Kristi, pe ki nwọn ki o mã fi ìwa pẹlẹ ṣiṣẹ, ki nwọn ki o si mã jẹ onjẹ awọn tikarawọn.
II. Tes 3:6-12 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀yin ará, à ń pàṣẹ fun yín ní orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi pé kí ẹ yẹra fún àwọn onigbagbọ tí wọn bá ń rìn ségesège, tí wọn kò tẹ̀lé ẹ̀kọ́ tí ẹ ti kọ́ lọ́dọ̀ wa. Nítorí ẹ̀yin fúnra yín mọ bí ó ti yẹ kí ẹ ṣe àfarawé wa, nítorí a kò rìn ségesège nígbà tí a wà láàrin yín. Bẹ́ẹ̀ ni a kò jẹ oúnjẹ ẹnikẹ́ni ninu yín lọ́fẹ̀ẹ́. Ṣugbọn ninu làálàá ati ìṣòro ni à ń ṣiṣẹ́ tọ̀sán-tòru, kí á má baà ni ẹnikẹ́ni ninu yín lára. Kì í ṣe pé a kò ní ẹ̀tọ́ láti jẹun lọ́dọ̀ yín; ṣugbọn a kò ṣe bẹ́ẹ̀ kí á lè fi ara wa ṣe àpẹẹrẹ fun yín, kí ẹ lè fara wé wa. Nítorí nígbà tí a wà lọ́dọ̀ yín, a pàṣẹ fun yín pé bí ẹnikẹ́ni bá kọ̀ tí kò ṣiṣẹ́, ẹ má jẹ́ kí ó jẹun. Nítorí a gbọ́ pé àwọn kan ninu yín ń rìn ségesège, wọn kì í ṣiṣẹ́ rárá, ẹsẹ̀ ni wọ́n fi í máa wọ́lẹ̀ kiri. A pàṣẹ fún irú àwọn bẹ́ẹ̀, a tún ń rọ̀ wọ́n ninu Oluwa Jesu Kristi pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ fún oúnjẹ ti ara wọn.
II. Tes 3:6-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní orúkọ Jesu Kristi Olúwa wa, àwa pàṣẹ fún un yín ará, pé kí ẹ yẹra fún gbogbo àwọn arákùnrin yín tí ń ṣe ìmẹ́lẹ́, tí kò sì gbé ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ tí ẹ gbà ní ọ̀dọ̀ wa. Nítorí ẹ̀yin náà mọ̀ bí ó ṣe yẹ kí ẹ máa fi ara wé wa. Àwa kì í ṣe ìmẹ́lẹ́ nígbà tí a wà ní ọ̀dọ̀ yín. Bẹ́ẹ̀ ni àwa kò sì jẹ oúnjẹ ẹnikẹ́ni lọ́fẹ̀ẹ́. Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, àwa ń ṣiṣẹ́ tọ̀sán tòru kí a má ba à di àjàgà sí ẹnikẹ́ni nínú yín lọ́rùn. Àwa ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, kì í ṣe nítorí pé àwa kò ní ẹ̀tọ́ láti béèrè fún un, ṣùgbọ́n àwa ń fi ara wa ṣe àpẹẹrẹ tí ẹ ó tẹ̀lé. Nítorí nígbà tí àwa wà lọ́dọ̀ yín, a ṣe àwọn òfin wọ̀nyí fún un yín pé, “Bí ẹnikẹ́ni kò bá fẹ́ ṣiṣẹ́, kí ó má ṣe jẹun.” A gbọ́ pé àwọn kan wà láàrín yín tí wọn jẹ́ ìmẹ́lẹ́. Wọ́n jẹ́ atọjúlékiri. Ǹjẹ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni àwa ń pàṣẹ fún, tí a sì ń rọ̀ nínú Jesu Kristi Olúwa pé kí wọn ó máa ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ.