II. Sam 3:2-5

II. Sam 3:2-5 YBCV

Dafidi si bi ọmọkunrin ni Hebroni: Ammoni li akọbi rẹ̀ ti Ahinoamu ara Jesreeli bi fun u. Ekeji rẹ̀ si ni Kileabu, ti Abigaili aya Nabali ara Karmeli nì bi fun u; ẹkẹta si ni Absalomu ọmọ ti Maaka ọmọbinrin Talmai ọba Geṣuri bi fun u. Ẹkẹrin si ni Adonija ọmọ Haggiti; ati ikarun ni Ṣefatia ọmọ Abitali; Ẹkẹfa si ni Itreamu, ti Egla aya Dafidi bi fun u. Wọnyi li a bi fun Dafidi ni Hebroni.