II. Sam 3:2-5
II. Sam 3:2-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Dafidi si bi ọmọkunrin ni Hebroni: Ammoni li akọbi rẹ̀ ti Ahinoamu ara Jesreeli bi fun u. Ekeji rẹ̀ si ni Kileabu, ti Abigaili aya Nabali ara Karmeli nì bi fun u; ẹkẹta si ni Absalomu ọmọ ti Maaka ọmọbinrin Talmai ọba Geṣuri bi fun u. Ẹkẹrin si ni Adonija ọmọ Haggiti; ati ikarun ni Ṣefatia ọmọ Abitali; Ẹkẹfa si ni Itreamu, ti Egla aya Dafidi bi fun u. Wọnyi li a bi fun Dafidi ni Hebroni.
II. Sam 3:2-5 Yoruba Bible (YCE)
Ọmọkunrin mẹfa ni wọ́n bí fún Dafidi nígbà tí ó wà ní Heburoni. Aminoni tí ìyá rẹ̀ ń jẹ́ Ahinoamu, ará Jesireeli, ni àkọ́bí. Ekeji ni Kileabu, ọmọ Abigaili, opó Nabali, ará Kamẹli. Ẹkẹta ni Absalomu, ọmọ Maaka, ọmọ Talimai, ọba Geṣuri. Ẹkẹrin ni Adonija ọmọ Hagiti. Ẹkarun-un ni Ṣefataya ọmọ Abitali. Ẹkẹfa sì ni Itireamu, ọmọ Egila. Heburoni ni wọ́n ti bí àwọn ọmọ náà fún Dafidi.
II. Sam 3:2-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Dafidi sì bí ọmọkùnrin ní Hebroni: Amnoni ni àkọ́bí rẹ̀ tí Ahinoamu ará Jesreeli bí fún un. Èkejì rẹ̀ sì ni Kileabu, tí Abigaili aya Nabali ará Karmeli bí fún un; ẹ̀kẹta sì ni Absalomu ọmọ tí Maaka ọmọbìnrin Talmai ọba Geṣuri bí fún un. Ẹ̀kẹrin sì ni Adonijah ọmọ Haggiti; àti ẹ̀karùnún ni Ṣefatia ọmọ Abitali; Ẹ̀kẹfà sì ni Itreamu, tí Egla aya Dafidi bí fún un.