DAFIDI si sọ ọ̀rọ orin yi si Oluwa li ọjọ ti Oluwa gbà a kuro li ọwọ́ gbogbo awọn ọta rẹ̀, ati kuro li ọwọ́ Saulu.
O si wipe, Oluwa li apata mi; ati odi mi, ati olugbala mi;
Ọlọrun apata mi; emi o gbẹkẹle e: asà mi, ati iwo igbala mi, ibi isadi giga mi, ati ibi ãbò mi, olugbala mi; iwọ li o ti gbà mi kuro lọwọ agbara.
Emi o kepe Oluwa, ti o yẹ lati ma yìn: a o si gbà mi lọwọ awọn ọta mi.
Nigbati ibilu irora ikú yi mi ka kiri, ti awọn iṣàn enia buburu dẹruba mi;
Ọjá ipo-okú yi mi ka kiri; ikẹkun ikú ti ṣaju mi.
Ninu ipọnju mi emi ke pe Oluwa, emi si gbe ohùn mi soke si Ọlọrun mi: o si gbohùn mi lati tempili rẹ̀ wá, igbe mi si wọ̀ eti rẹ̀.
Ilẹ si mì, o si wariri; ipilẹ ọrun wariri, o si mì, nitoriti o binu.
Ẽfin si jade lati iho-imu rẹ̀ wa, ina lati ẹnu rẹ̀ wa si njonirun, ẹyín si nràn nipasẹ rẹ̀.
O tẹ ori ọrun ba pẹlu, o si sọkalẹ; okunkun biri-biri si mbẹ li atẹlẹsẹ rẹ̀.
O si gun ori kerubu, o si fò: a si ri i lori iyẹ afẹfẹ.
O si fi okunkun ṣe ibujoko yi ara rẹ̀ ka, ati agbajọ omi, ani iṣududu awọ sanma.
Nipasẹ imọlẹ iwaju rẹ̀ ẹyin-iná ràn.
Oluwa san ãra lati ọrun wá, ọga-ogo julọ si fọhùn rẹ̀.
O si ta ọfà, o si tú wọn ka; o kọ màna-mána, o si ṣẹ wọn.
Iṣàn ibu okun si fi ara hàn, ipilẹ aiye fi ara hàn, nipa ibawi Oluwa, nipa fifún ẽmi ihò imu rẹ̀.
O ranṣẹ lati oke wá, o mu mi; o fà mi jade lati inu omi nla wá.
O gbà mi lọwọ ọta mi alagbara, lọwọ awọn ti o korira mi: nitoripe nwọn li agbara jù mi lọ.
Nwọn ṣaju mi li ọjọ ipọnju mi; ṣugbọn Oluwa li alafẹhinti mi.
O si mu mi wá si àye nla: o gbà mi, nitoriti inu rẹ̀ dùn si mi.
Oluwa san a fun mi gẹgẹ bi ododo mi: o si san a fun mi gẹgẹ bi mimọ́ ọwọ́ mi.
Nitoripe emi pa ọ̀na Oluwa mọ, emi kò si fi ìwa buburu yapa kuro lọdọ Ọlọrun mi.
Nitoripe gbogbo idajọ rẹ̀ li o wà niwaju mi: ati niti ofin rẹ̀, emi kò si yapa kuro ninu wọn.
Emi si wà ninu iwà-titọ si i, emi si pa ara mi mọ kuro ninu ẹ̀ṣẹ mi.
Oluwa si san a fun mi gẹgẹ bi ododo mi, gẹgẹ bi ìwa-mimọ́ mi niwaju rẹ̀.