SAMUẸLI KEJI 22:1-25

SAMUẸLI KEJI 22:1-25 YCE

Nígbà tí OLUWA gba Dafidi lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ ati lọ́wọ́ Saulu, Dafidi kọ orin yìí sí OLUWA pé: “OLUWA ni àpáta mi, ààbò mi, ati olùgbàlà mi; Ọlọrun mi, àpáta mi, ọ̀dọ̀ ẹni tí mo sá pamọ́ sí. Àpáta mi ati ìgbàlà mi, ààbò mi ati ibi ìpamọ́ mi, olùgbàlà mi, ìwọ ni o gbà mí lọ́wọ́ ìwà ipá. Mo ké pe OLUWA, ẹni tí ìyìn yẹ, Ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi. “Ikú yí mi káàkiri, bí ìgbì omi; ìparun sì bò mí mọ́lẹ̀ bíi ríru omi; isà òkú ya ẹnu sílẹ̀ dè mí, ewu ikú sì dojú kọ mí. Ninu ìpọ́njú mi, mo ké pe OLUWA mo ké pe Ọlọrun mi, ó gbọ́ ohùn mi láti inú tẹmpili rẹ̀; ó sì tẹ́tí sí igbe mi. “Ayé mì, ó sì wárìrì; ìpìlẹ̀ àwọn ọ̀run sì wárìrì, ó mì tìtì, nítorí ibinu Ọlọrun. Èéfín jáde láti ihò imú rẹ̀, iná ajónirun sì jáde láti ẹnu rẹ̀; ẹ̀yinná tí ó pọ́n rẹ̀rẹ̀ ń ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ jáde. Ó tẹ àwọn ọ̀run ba, ó sì sọ̀kalẹ̀; ìkùukùu tí ó ṣókùnkùn sì wà ní abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó gun orí Kerubu, ó fò, afẹ́fẹ́ ni ó fi ṣe ìyẹ́ tí ó fi ń fò. Ó fi òkùnkùn bo ara, ìkùukùu tí ó ṣókùnkùn, tí ó sì kún fún omi ni ó fi ṣe ìbòrí. Ẹ̀yinná tí ń jó ń jáde, láti inú ìmọ́lẹ̀ tí ó wà níwájú rẹ̀. “OLUWA sán ààrá láti ọ̀run wá, ayé sì gbọ́ ohùn ọ̀gá ògo. Ó ta ọpọlọpọ ọfà, ó sì tú wọn ká. Ó tan mànàmáná, wọ́n sì ń sá. Ìsàlẹ̀ òkun di gbangba, ìpìlẹ̀ ayé sì ṣí sílẹ̀, nígbà tí OLUWA bá wọn wí, tí ó sì fi ibinu jágbe mọ́ wọn. “OLUWA nawọ́ sílẹ̀ láti òkè wá, ó dì mí mú, ó fà mí jáde kúrò ninu omi jíjìn. Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi, tí ó lágbára; ati lọ́wọ́ gbogbo àwọn tí wọ́n kórìíra mi; nítorí pé wọ́n lágbára jù mí lọ. Nígbà tí mo wà ninu ìpọ́njú; wọ́n gbógun tì mí, ṣugbọn OLUWA dáàbò bò mí. Ó ràn mí lọ́wọ́, ó kó mi yọ ninu ewu, ó sì gbà mí là, nítorí pé inú rẹ̀ dùn sí mi. “OLUWA fún mi ní èrè òdodo mi, ó san ẹ̀san fún mi, nítorí pé mo jẹ́ aláìlẹ́bi. Nítorí pé mo pa àwọn òfin OLUWA mọ́, n kò sì ṣe agídí, kí n yipada kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun mi. Mo ti tẹ̀lé gbogbo òfin rẹ̀, n kò sì ṣe àìgbọràn sí àwọn ìlànà rẹ̀. N kò lẹ́bi níwájú rẹ̀, mo sì ti yẹra fún ẹ̀ṣẹ̀ dídá. Nítorí náà ni OLUWA ṣe san án fún mi, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi, ati gẹ́gẹ́ bí mo ti jẹ́ mímọ́ níwájú rẹ̀.