II. Sam 22:1-25
II. Sam 22:1-25 Bibeli Mimọ (YBCV)
DAFIDI si sọ ọ̀rọ orin yi si Oluwa li ọjọ ti Oluwa gbà a kuro li ọwọ́ gbogbo awọn ọta rẹ̀, ati kuro li ọwọ́ Saulu. O si wipe, Oluwa li apata mi; ati odi mi, ati olugbala mi; Ọlọrun apata mi; emi o gbẹkẹle e: asà mi, ati iwo igbala mi, ibi isadi giga mi, ati ibi ãbò mi, olugbala mi; iwọ li o ti gbà mi kuro lọwọ agbara. Emi o kepe Oluwa, ti o yẹ lati ma yìn: a o si gbà mi lọwọ awọn ọta mi. Nigbati ibilu irora ikú yi mi ka kiri, ti awọn iṣàn enia buburu dẹruba mi; Ọjá ipo-okú yi mi ka kiri; ikẹkun ikú ti ṣaju mi. Ninu ipọnju mi emi ke pe Oluwa, emi si gbe ohùn mi soke si Ọlọrun mi: o si gbohùn mi lati tempili rẹ̀ wá, igbe mi si wọ̀ eti rẹ̀. Ilẹ si mì, o si wariri; ipilẹ ọrun wariri, o si mì, nitoriti o binu. Ẽfin si jade lati iho-imu rẹ̀ wa, ina lati ẹnu rẹ̀ wa si njonirun, ẹyín si nràn nipasẹ rẹ̀. O tẹ ori ọrun ba pẹlu, o si sọkalẹ; okunkun biri-biri si mbẹ li atẹlẹsẹ rẹ̀. O si gun ori kerubu, o si fò: a si ri i lori iyẹ afẹfẹ. O si fi okunkun ṣe ibujoko yi ara rẹ̀ ka, ati agbajọ omi, ani iṣududu awọ sanma. Nipasẹ imọlẹ iwaju rẹ̀ ẹyin-iná ràn. Oluwa san ãra lati ọrun wá, ọga-ogo julọ si fọhùn rẹ̀. O si ta ọfà, o si tú wọn ka; o kọ màna-mána, o si ṣẹ wọn. Iṣàn ibu okun si fi ara hàn, ipilẹ aiye fi ara hàn, nipa ibawi Oluwa, nipa fifún ẽmi ihò imu rẹ̀. O ranṣẹ lati oke wá, o mu mi; o fà mi jade lati inu omi nla wá. O gbà mi lọwọ ọta mi alagbara, lọwọ awọn ti o korira mi: nitoripe nwọn li agbara jù mi lọ. Nwọn ṣaju mi li ọjọ ipọnju mi; ṣugbọn Oluwa li alafẹhinti mi. O si mu mi wá si àye nla: o gbà mi, nitoriti inu rẹ̀ dùn si mi. Oluwa san a fun mi gẹgẹ bi ododo mi: o si san a fun mi gẹgẹ bi mimọ́ ọwọ́ mi. Nitoripe emi pa ọ̀na Oluwa mọ, emi kò si fi ìwa buburu yapa kuro lọdọ Ọlọrun mi. Nitoripe gbogbo idajọ rẹ̀ li o wà niwaju mi: ati niti ofin rẹ̀, emi kò si yapa kuro ninu wọn. Emi si wà ninu iwà-titọ si i, emi si pa ara mi mọ kuro ninu ẹ̀ṣẹ mi. Oluwa si san a fun mi gẹgẹ bi ododo mi, gẹgẹ bi ìwa-mimọ́ mi niwaju rẹ̀.
II. Sam 22:1-25 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí OLUWA gba Dafidi lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ ati lọ́wọ́ Saulu, Dafidi kọ orin yìí sí OLUWA pé: “OLUWA ni àpáta mi, ààbò mi, ati olùgbàlà mi; Ọlọrun mi, àpáta mi, ọ̀dọ̀ ẹni tí mo sá pamọ́ sí. Àpáta mi ati ìgbàlà mi, ààbò mi ati ibi ìpamọ́ mi, olùgbàlà mi, ìwọ ni o gbà mí lọ́wọ́ ìwà ipá. Mo ké pe OLUWA, ẹni tí ìyìn yẹ, Ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi. “Ikú yí mi káàkiri, bí ìgbì omi; ìparun sì bò mí mọ́lẹ̀ bíi ríru omi; isà òkú ya ẹnu sílẹ̀ dè mí, ewu ikú sì dojú kọ mí. Ninu ìpọ́njú mi, mo ké pe OLUWA mo ké pe Ọlọrun mi, ó gbọ́ ohùn mi láti inú tẹmpili rẹ̀; ó sì tẹ́tí sí igbe mi. “Ayé mì, ó sì wárìrì; ìpìlẹ̀ àwọn ọ̀run sì wárìrì, ó mì tìtì, nítorí ibinu Ọlọrun. Èéfín jáde láti ihò imú rẹ̀, iná ajónirun sì jáde láti ẹnu rẹ̀; ẹ̀yinná tí ó pọ́n rẹ̀rẹ̀ ń ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ jáde. Ó tẹ àwọn ọ̀run ba, ó sì sọ̀kalẹ̀; ìkùukùu tí ó ṣókùnkùn sì wà ní abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó gun orí Kerubu, ó fò, afẹ́fẹ́ ni ó fi ṣe ìyẹ́ tí ó fi ń fò. Ó fi òkùnkùn bo ara, ìkùukùu tí ó ṣókùnkùn, tí ó sì kún fún omi ni ó fi ṣe ìbòrí. Ẹ̀yinná tí ń jó ń jáde, láti inú ìmọ́lẹ̀ tí ó wà níwájú rẹ̀. “OLUWA sán ààrá láti ọ̀run wá, ayé sì gbọ́ ohùn ọ̀gá ògo. Ó ta ọpọlọpọ ọfà, ó sì tú wọn ká. Ó tan mànàmáná, wọ́n sì ń sá. Ìsàlẹ̀ òkun di gbangba, ìpìlẹ̀ ayé sì ṣí sílẹ̀, nígbà tí OLUWA bá wọn wí, tí ó sì fi ibinu jágbe mọ́ wọn. “OLUWA nawọ́ sílẹ̀ láti òkè wá, ó dì mí mú, ó fà mí jáde kúrò ninu omi jíjìn. Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi, tí ó lágbára; ati lọ́wọ́ gbogbo àwọn tí wọ́n kórìíra mi; nítorí pé wọ́n lágbára jù mí lọ. Nígbà tí mo wà ninu ìpọ́njú; wọ́n gbógun tì mí, ṣugbọn OLUWA dáàbò bò mí. Ó ràn mí lọ́wọ́, ó kó mi yọ ninu ewu, ó sì gbà mí là, nítorí pé inú rẹ̀ dùn sí mi. “OLUWA fún mi ní èrè òdodo mi, ó san ẹ̀san fún mi, nítorí pé mo jẹ́ aláìlẹ́bi. Nítorí pé mo pa àwọn òfin OLUWA mọ́, n kò sì ṣe agídí, kí n yipada kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun mi. Mo ti tẹ̀lé gbogbo òfin rẹ̀, n kò sì ṣe àìgbọràn sí àwọn ìlànà rẹ̀. N kò lẹ́bi níwájú rẹ̀, mo sì ti yẹra fún ẹ̀ṣẹ̀ dídá. Nítorí náà ni OLUWA ṣe san án fún mi, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi, ati gẹ́gẹ́ bí mo ti jẹ́ mímọ́ níwájú rẹ̀.
II. Sam 22:1-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Dafidi sì kọ ọ̀rọ̀ orin yìí sí OLúWA ní ọjọ́ tí OLúWA gbà á kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀, àti kúrò lọ́wọ́ Saulu. Ó sì wí pé: “OLúWA ni àpáta mi, àti Olùgbàlà mi; Ọlọ́run mi, àpáta mi, nínú ẹni tí èmi ní ààbò, àti ìwo ìgbàlà mi, ibi ìsádi gíga mi. Àti ibi ìlùmọ̀ mi, Olùgbàlà mi; ìwọ ni ó ti gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìwà ipá. “Èmi ké pe OLúWA, tí ó yẹ láti máa yìn, ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi. Nígbà tí ìbìlù ìrora ikú yí mi káàkiri; tí àwọn ìṣàn ènìyàn búburú dẹ́rùbà mí. Ọ̀já isà òkú yí mi káàkiri; ìkẹ́kùn ikú dojúkọ mí. “Nínú ìpọ́njú mi, èmi ké pé OLúWA, èmi sì gbé ohùn mi sókè sí Ọlọ́run mi. Ó sí gbóhùn mi láti tẹmpili rẹ̀ igbe mí wọ etí rẹ̀. Ilẹ̀ sì mì, ó sì wárìrì; ìpìlẹ̀ ọ̀run wárìrì, ó sì mì, nítorí tí ó bínú. Èéfín ti ihò imú rẹ̀ jáde wá; Iná ajónirun ti ẹnu rẹ̀ jáde wá, ẹ̀yin iná bú jáde láti inú rẹ̀. Ó tẹ orí ọ̀run ba pẹ̀lú, ó sì sọ̀kalẹ̀; òkùnkùn biribiri sì ń bẹ ní àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀. Ó sì gun orí kérúbù, ó sì fò: a sì rí i lórí ìyẹ́ afẹ́fẹ́. Ó sì fi òkùnkùn ṣe ibùjókòó yí ara rẹ̀, àti àgbájọ omi, àní ìṣúdudu ìkùùkuu àwọ̀ sánmọ̀. Nípasẹ̀ ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ̀ ẹ̀yín iná ràn. OLúWA sán àrá láti ọ̀run wá, Ọ̀gá-ògo jùlọ sì fọhùn rẹ̀. Ó sì ta ọfà, ó sì tú wọn ká; ó kọ mànàmànà, ó sì ṣẹ́ wọn. Ìṣàn ibú Òkun sì fi ara hàn, ìpìlẹ̀ ayé fi ara hàn, nípa ìbáwí OLúWA, nípa fífún èémí ihò imú rẹ̀. “Ó ránṣẹ́ láti òkè wá, ó mú mi; ó fà mí jáde láti inú omi ńlá wá. Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi alágbára, lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi: nítorí pé wọ́n lágbára jù mí lọ. Wọ́n wá láti borí mi lọ́jọ́ ìpọ́njú mi: ṣùgbọ́n OLúWA ni aláfẹ̀yìntì mi. Ó sì mú mi wá sí ààyè ńlá: ó gbà mi, nítorí tí inú rẹ̀ dún sí mi. “OLúWA sán án fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi; ó sì san án fún mi gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi. Nítorí pé èmi pa ọ̀nà OLúWA mọ́, èmi kò sì fi ìwà búburú yapa kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run mi. Nítorí pé gbogbo ìdájọ́ rẹ̀ ni ó wà níwájú mi; àti ní ti òfin rẹ̀, èmi kò sì yapa kúrò nínú wọn. Èmi sì wà nínú ìwà títọ́ sí í, èmi sì pa ara mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi. OLúWA sì san fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi, gẹ́gẹ́ bí ìwà mímọ́ mi níwájú rẹ̀.