II. Sam 21:1-7

II. Sam 21:1-7 YBCV

IYAN kan si mu ni ọjọ Dafidi li ọdun mẹta, lati ọdun de ọdun; Dafidi si bere lọdọ Oluwa, Oluwa si wipe, Nitori ti Saulu ni, ati nitori ile rẹ̀ ti o kún fun ẹ̀jẹ̀, nitoripe o pa awọn ara Gibeoni. Ọba si pe awọn ara Gibeoni, o si ba wọn sọ̀rọ: awọn ara Gibeoni ki iṣe ọkan ninu awọn ọmọ Israeli, ṣugbọn nwọn jẹ awọn ti o kù ninu awọn ọmọ Amori; awọn ọmọ Israeli si ti bura fun wọn: Saulu si nwá ọ̀na ati pa wọn ni itara rẹ̀ fun awọn ọmọ Israeli ati Juda. Dafidi si bi awọn ara Gibeoni lere pe, Kili emi o ṣe fun nyin? ati kili emi o fi ṣe etutu, ki ẹnyin ki o le sure fun ilẹ ini Oluwa? Awọn ara Gibeoni si wi fun u pe, Awa kò ni fi fadaka tabi wura ti Saulu ati ti idile rẹ̀ ṣe, bẹ̃ni a kò si fẹ ki ẹ pa ẹnikan ni Israeli. O si wipe, eyi ti ẹnyin ba wi li emi o ṣe. Nwọn si wi fun ọba pe, ọkunrin ti o run wa, ti o si rò lati pa wa rẹ́ ki a má kù nibikibi ninu gbogbo agbegbe Israeli. Mu ọkunrin meje ninu awọn ọmọ rẹ̀ fun wa, awa o si so wọn rọ̀ fun Oluwa ni Gibea ti Saulu ẹniti Oluwa ti yàn. Ọba si wipe, Emi o fi wọn fun nyin. Ṣugbọn Ọba dá Mefiboṣeti si, ọmọ Jonatani, ọmọ Saulu, nitori ibura Oluwa ti o wà larin wọn, lãrin Dafidi ati Jonatani ọmọ Saulu.