II. Sam 21:1-7

II. Sam 21:1-7 Yoruba Bible (YCE)

Ní àkókò ìjọba Dafidi, ìyàn ńlá kan mú, fún odidi ọdún mẹta. Dafidi bá lọ wádìí ọ̀rọ̀ náà lọ́dọ̀ OLUWA. OLUWA sì dáhùn pé, “Saulu ati ìdílé rẹ̀ jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn, nítorí pé ó pa àwọn ará Gibeoni.” Àwọn ará Gibeoni kì í ṣe ara àwọn ọmọ Israẹli. Ara àwọn ará Amori tí wọ́n ṣẹ́kù ni wọ́n. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Israẹli ti ṣèlérí pé àwọn kò ní pa wọ́n, sibẹsibẹ Saulu gbìyànjú láti pa wọ́n run, nítorí ìtara rẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli ati Juda. Dafidi bá pe àwọn ará Gibeoni, ó sì bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ fẹ́ kí n ṣe fun yín? Ọ̀nà wo ni mo lè gbà ṣe àtúnṣe ibi tí wọ́n ṣe si yín, kí ẹ baà lè súre fún àwọn eniyan OLUWA?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Aáwọ̀ tí ó wà láàrin àwa ati Saulu ati ìdílé rẹ̀, kì í ṣe ohun tí a lè fi wúrà ati fadaka parí, a kò sì fẹ́ pa ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli.” Dafidi bá tún bèèrè pé, “Kí ni ẹ wá fẹ́ kí n ṣe fun yín?” Wọ́n dáhùn pé, “Saulu fẹ́ pa wá run, kò sì fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ninu wa wà láàyè níbikíbi, ní ilẹ̀ Israẹli. Nítorí náà, fún wa ní meje ninu àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, kí á lè so wọ́n kọ́ níwájú OLUWA ní Gibea, ní orí òkè OLUWA.” Dafidi dáhùn pé, “N óo kó wọn lé yín lọ́wọ́.” Ṣugbọn nítorí majẹmu tí ó wà láàrin Dafidi ati Jonatani, Dafidi kò fi ọwọ́ kan Mẹfiboṣẹti, ọmọ Jonatani, ọmọ Saulu.

II. Sam 21:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ìyàn kan sì mú lọ́jọ́ Dafidi ní ọdún mẹ́ta, láti ọdún dé ọdún; Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ OLúWA, OLúWA sì wí pé, Nítorí ti Saulu ni, àti nítorí ilé rẹ̀ tí ó kún fún ẹ̀jẹ̀, nítorí pé ó pa àwọn ará Gibeoni. Ọba sì pe àwọn ará Gibeoni, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀; àwọn ará Gibeoni kì í ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Israẹli, ṣùgbọ́n wọ́n jẹ́ àwọn tí ó kù nínú àwọn ọmọ Amori; àwọn ọmọ Israẹli sì ti búra fún wọn: Saulu sì ń wá ọ̀nà àti pa wọ́n ní ìtara rẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli àti Juda. Dafidi sì bi àwọn ará Gibeoni léèrè pé, “Kí ni èmi ó ṣe fún un yín? Àti kín ni èmi ó fi ṣe ètùtù, kí ẹ̀yin lè súre fún ilẹ̀ ìní OLúWA?” Àwọn ará Gibeoni sì wí fún un pé, “Kì í ṣe ọ̀rọ̀ fàdákà tàbí wúrà láàrín wa àti Saulu tàbí ìdílé rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì fẹ́ kí ẹ pa ẹnìkan ní Israẹli.” Dafidi sì wí pé, “Èyí tí ẹ̀yin bá wí ni èmi ó ṣe?” Wọ́n sì wí fún ọba pé, “Ọkùnrin tí ó run wá, tí ó sì rò láti pa wá rẹ́ ki a má kù níbikíbi nínú gbogbo agbègbè Israẹli. Mú ọkùnrin méje nínú àwọn ọmọ rẹ̀ fún wá, àwa ó sì so wọ́n rọ̀ fún OLúWA ní Gibeah ti Saulu ẹni tí OLúWA ti yàn.” Ọba sì wí pé, “Èmi ó fi wọ́n fún yín.” Ṣùgbọ́n ọba dá Mefiboṣeti sí, ọmọ Jonatani, ọmọ Saulu, nítorí ìbúra OLúWA tí ó wà láàrín Dafidi àti Jonatani ọmọ Saulu.