II. Sam 17:14-29

II. Sam 17:14-29 YBCV

Absalomu ati gbogbo ọkunrin Israeli si wipe, Ìmọ Huṣai ara Arki sàn jù ìmọ Ahitofeli lọ. Nitori Oluwa fẹ lati yi ìmọ rere ti Ahitofeli po, nitori ki Oluwa ki o le mu ibi wá sori Absalomu. Huṣai si wi fun Sadoku ati fun Abiatari awọn alufa pe, Bayi bayi ni Ahitofeli ti ba Absalomu ati awọn agbà Israeli dámọran; bayi bayi li emi si damọràn. Nitorina yara ranṣẹ nisisiyi ki o si sọ fun Dafidi pe, Máṣe duro ni pẹtẹlẹ ijù nì li alẹ yi, ṣugbọn yara rekọja, ki a má ba gbe ọba mì, ati gbogbo awọn enia ti o mbẹ lọdọ rẹ̀. Jonatani ati Ahimaasi si duro ni Enrogeli; ọdọmọdebirin kan si lọ, o si sọ fun wọn; awọn si lọ nwọn sọ fun Dafidi ọba nitoripe ki a má ba ri wọn pe nwọn wọ ilu. Ṣugbọn ọdọmọdekunrin kan ri wọn, o si wi fun Absalomu: ṣugbọn awọn mejeji si yara lọ kuro, nwọn si wá si ile ọkunrin kan ni Bahurimu, ẹniti o ni kanga kan li ọgbà rẹ̀, nwọn si sọkalẹ si ibẹ. Obinrin rẹ̀ si mu nkan o fi bo kanga na, o si sa agbado sori rẹ̀; a kò si mọ̀. Awọn iranṣẹ Absalomu si tọ obinrin na wá ni ile na, nwọn si bere pe, Nibo ni Ahimaasi ati Jonatani gbe wà? obinrin na si wi fun wọn pe, Nwọn ti goke rekọja iṣan odo nì. Nwọn si wá wọn kiri, nwọn kò si ri wọn, nwọn si yipada si Jerusalemu. O si ṣe, lẹhin igbati nwọn yẹra kuro tan, awọn si jade kuro ninu kanga, nwọn si lọ, nwọn si rò fun Dafidi ọba, nwọn si wi fun Dafidi pe, Dide ki o si goke odo kánkán: nitoripe bayi ni Ahitofeli gbìmọ si ọ. Dafidi si dide, ati gbogbo awọn enia ti mbẹ lọdọ rẹ̀, nwọn si goke odo Jordani: ki ilẹ to mọ́, ẹnikan kò kù ti kò goke odo Jordani. Nigbati Ahitofeli si ri pe nwọn kò fi ìmọ tirẹ̀ ṣe, o si di kẹtẹkẹtẹ rẹ̀ ni gãri, o si dide, o lọ ile rẹ̀, o si palẹ ile rẹ̀ mọ, o si pokùnso, o si kú, a si sin i si iboji baba rẹ̀. Dafidi si wá si Mahanaimu. Absalomu si goke odo Jordani, on, ati gbogbo awọn ọkunrin Israeli pẹlu rẹ̀. Absalomu si fi Amasa ṣe olori ogun ni ipò Joabu: Amasa ẹniti iṣe ọmọ ẹnikan, orukọ ẹniti a npè ni Itra, ara Israeli, ti o wọle tọ Abigaili ọmọbinrin Nahaṣi, arabinrin Seruia, iyá Joabu. Israeli ati Absalomu si do ni ilẹ Gileadi. O si ṣe, nigbati Dafidi si wá si Mahanaimu, Ṣobi ọmọ Nahaṣi ti Rabba ti awọn ọmọ Ammoni, ati Makiri ọmọ Ammieli ti Lodebari, ati Barsillai ara Gileadi ti Rogelimu, Mu akete, ati ago, ati ohun-elo amọ̀, ati alikama, ati ọkà, ati iyẹfun, ati agbado didin, ati ẹ̀wa, ati erẽ, ati ẹ̀wa didin. Ati oyin, ati ori-amọ, ati agutan, ati wàrakasi malu, wá fun Dafidi, ati fun awọn enia ti mbẹ lọdọ rẹ̀ lati jẹ: nitoriti nwọn wi pe, ebi npa awọn enia, o si rẹ̀ wọn, orungbẹ si ngbẹ wọn li aginju.