II. Sam 17:14-29

II. Sam 17:14-29 Bibeli Mimọ (YBCV)

Absalomu ati gbogbo ọkunrin Israeli si wipe, Ìmọ Huṣai ara Arki sàn jù ìmọ Ahitofeli lọ. Nitori Oluwa fẹ lati yi ìmọ rere ti Ahitofeli po, nitori ki Oluwa ki o le mu ibi wá sori Absalomu. Huṣai si wi fun Sadoku ati fun Abiatari awọn alufa pe, Bayi bayi ni Ahitofeli ti ba Absalomu ati awọn agbà Israeli dámọran; bayi bayi li emi si damọràn. Nitorina yara ranṣẹ nisisiyi ki o si sọ fun Dafidi pe, Máṣe duro ni pẹtẹlẹ ijù nì li alẹ yi, ṣugbọn yara rekọja, ki a má ba gbe ọba mì, ati gbogbo awọn enia ti o mbẹ lọdọ rẹ̀. Jonatani ati Ahimaasi si duro ni Enrogeli; ọdọmọdebirin kan si lọ, o si sọ fun wọn; awọn si lọ nwọn sọ fun Dafidi ọba nitoripe ki a má ba ri wọn pe nwọn wọ ilu. Ṣugbọn ọdọmọdekunrin kan ri wọn, o si wi fun Absalomu: ṣugbọn awọn mejeji si yara lọ kuro, nwọn si wá si ile ọkunrin kan ni Bahurimu, ẹniti o ni kanga kan li ọgbà rẹ̀, nwọn si sọkalẹ si ibẹ. Obinrin rẹ̀ si mu nkan o fi bo kanga na, o si sa agbado sori rẹ̀; a kò si mọ̀. Awọn iranṣẹ Absalomu si tọ obinrin na wá ni ile na, nwọn si bere pe, Nibo ni Ahimaasi ati Jonatani gbe wà? obinrin na si wi fun wọn pe, Nwọn ti goke rekọja iṣan odo nì. Nwọn si wá wọn kiri, nwọn kò si ri wọn, nwọn si yipada si Jerusalemu. O si ṣe, lẹhin igbati nwọn yẹra kuro tan, awọn si jade kuro ninu kanga, nwọn si lọ, nwọn si rò fun Dafidi ọba, nwọn si wi fun Dafidi pe, Dide ki o si goke odo kánkán: nitoripe bayi ni Ahitofeli gbìmọ si ọ. Dafidi si dide, ati gbogbo awọn enia ti mbẹ lọdọ rẹ̀, nwọn si goke odo Jordani: ki ilẹ to mọ́, ẹnikan kò kù ti kò goke odo Jordani. Nigbati Ahitofeli si ri pe nwọn kò fi ìmọ tirẹ̀ ṣe, o si di kẹtẹkẹtẹ rẹ̀ ni gãri, o si dide, o lọ ile rẹ̀, o si palẹ ile rẹ̀ mọ, o si pokùnso, o si kú, a si sin i si iboji baba rẹ̀. Dafidi si wá si Mahanaimu. Absalomu si goke odo Jordani, on, ati gbogbo awọn ọkunrin Israeli pẹlu rẹ̀. Absalomu si fi Amasa ṣe olori ogun ni ipò Joabu: Amasa ẹniti iṣe ọmọ ẹnikan, orukọ ẹniti a npè ni Itra, ara Israeli, ti o wọle tọ Abigaili ọmọbinrin Nahaṣi, arabinrin Seruia, iyá Joabu. Israeli ati Absalomu si do ni ilẹ Gileadi. O si ṣe, nigbati Dafidi si wá si Mahanaimu, Ṣobi ọmọ Nahaṣi ti Rabba ti awọn ọmọ Ammoni, ati Makiri ọmọ Ammieli ti Lodebari, ati Barsillai ara Gileadi ti Rogelimu, Mu akete, ati ago, ati ohun-elo amọ̀, ati alikama, ati ọkà, ati iyẹfun, ati agbado didin, ati ẹ̀wa, ati erẽ, ati ẹ̀wa didin. Ati oyin, ati ori-amọ, ati agutan, ati wàrakasi malu, wá fun Dafidi, ati fun awọn enia ti mbẹ lọdọ rẹ̀ lati jẹ: nitoriti nwọn wi pe, ebi npa awọn enia, o si rẹ̀ wọn, orungbẹ si ngbẹ wọn li aginju.

II. Sam 17:14-29 Yoruba Bible (YCE)

Absalomu ati gbogbo Israẹli dáhùn pé, “Ìmọ̀ràn ti Huṣai dára ju ti Ahitofeli lọ,” nítorí pé OLUWA ti pinnu láti yí ìmọ̀ràn rere tí Ahitofeli mú wá pada, kí ibi lè bá Absalomu. Huṣai bá lọ sọ fún Sadoku ati Abiatari, àwọn alufaa mejeeji, irú ìmọ̀ràn tí Ahitofeli fún Absalomu ati àwọn ọmọ Israẹli, ati èyí tí òun fún wọn. Huṣai tún fi kún un pé, kí wọ́n ranṣẹ kíákíá lọ sọ fún Dafidi pé, kò gbọdọ̀ sùn níbi tí wọ́n ti ń ré odò Jọdani kọjá ninu aṣálẹ̀ ní òru ọjọ́ náà. Ó gbọdọ̀ kọjá sí òdìkejì odò lẹsẹkẹsẹ kí ọwọ́ má baà tẹ̀ ẹ́ ati àwọn eniyan tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀, kí wọ́n sì pa wọ́n. Jonatani ati Ahimaasi dúró sí ibi orísun Enrogeli, ní ìgbèríko ati máa lọ sí Jerusalẹmu, nítorí pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ fojú kàn wọ́n, pé wọ́n wọ ìlú rárá. Iranṣẹbinrin kan ni ó máa ń lọ sọ ohun tí ó bá ti ṣẹlẹ̀ fún wọn, àwọn náà á lọ sọ fún Dafidi. Ṣugbọn ọmọkunrin kan rí wọn, ó sì sọ fún Absalomu. Jonatani ati Ahimaasi bá sáré lọ fi ara pamọ́ ní ilé ọkunrin kan ní Bahurimu. Ọkunrin yìí ní kànga kan ní àgbàlá ilé rẹ̀. Àwọn mejeeji bá kó sinu kànga náà. Aya ọkunrin náà fi nǹkan dé e lórí, ó sì da ọkà bàbà lé e kí ẹnikẹ́ni má baà fura sí i. Nígbà tí àwọn iranṣẹ Absalomu dé ọ̀dọ̀ obinrin náà, wọ́n bi í pé, “Níbo ni Ahimaasi ati Jonatani wà?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Wọ́n ti kọjá sí òdìkejì odò.” Àwọn ọkunrin náà wá wọn títí, ṣugbọn wọn kò rí wọn. Wọ́n bá pada lọ sí Jerusalẹmu. Nígbà tí àwọn ọkunrin náà lọ tán, Ahimaasi ati Jonatani jáde ninu kànga, wọ́n sì lọ ròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún Dafidi. Wọ́n sọ ohun tí Ahitofeli ti gbèrò láti ṣe sí Dafidi. Wọ́n ní kí ó yára, kí ó rékọjá sí òdìkejì odò náà kíá. Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí rékọjá sí òdìkejì odò Jọdani. Nígbà tí ilẹ̀ yóo fi mọ́, gbogbo wọn ti kọjá tán. Nígbà tí Ahitofeli rí i pé, Absalomu kò tẹ̀lé ìmọ̀ràn tí òun fún un, ó di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó pada lọ sí ìlú rẹ̀. Lẹ́yìn tí ó ti ṣètò ilé rẹ̀, ó pokùnso, ó bá kú; wọ́n sì sin ín sí ibojì ìdílé rẹ̀. Nígbà tí Absalomu ati àwọn ọmọ Israẹli yóo fi ré odò Jọdani kọjá tán, Dafidi ti dé ìlú tí wọn ń pè ní Mahanaimu. Amasa ni Absalomu fi ṣe olórí ogun rẹ̀, dípò Joabu. Itira ará Iṣimaeli ni baba Amasa. Ìyá rẹ̀ sì ni Abigaili, ọmọbinrin Nahaṣi, arabinrin Seruaya, ìyá Joabu. Absalomu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pàgọ́ sí ilẹ̀ Gileadi. Nígbà tí Dafidi dé Mahanaimu, Ṣobi, ọmọ Nahaṣi, wá pàdé rẹ̀, láti ìlú Raba, ní ilẹ̀ Amoni. Makiri, ọmọ Amieli, náà wá, láti Lodebari; ati Basilai, láti Rogelimu, ní ilẹ̀ Gileadi. Wọ́n kó ibùsùn lọ́wọ́ wá fún wọn, ati àwo, ìkòkò ati ọkà baali, ọkà tí wọ́n ti lọ̀, ati èyí tí wọ́n ti yan, erèé ati ẹ̀fọ́; oyin, omi wàrà, ati wàrà sísè. Wọ́n sì kó aguntan wá pẹlu, láti inú agbo wọn fún Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀, kí wọ́n lè rí nǹkan jẹ. Nítorí wọ́n rò pé yóo ti rẹ̀ wọ́n, ebi yóo ti máa pa wọ́n, òùngbẹ yóo sì ti máa gbẹ wọ́n, ninu aṣálẹ̀ tí wọ́n wà.

II. Sam 17:14-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Absalomu àti gbogbo ọkùnrin Israẹli sì wí pé, “Ìmọ̀ Huṣai ará Arki sàn ju ìmọ̀ Ahitofeli lọ! Nítorí OLúWA fẹ́ láti yí ìmọ̀ rere ti Ahitofeli po.” Nítorí kí OLúWA lè mú ibi wá sórí Absalomu. Huṣai sì wí fún Sadoku àti fún Abiatari àwọn àlùfáà pé, “Báyìí ni Ahitofeli ti bá Absalomu àti àwọn àgbàgbà Israẹli dámọ̀ràn: báyìí lèmi sì bá a dámọ̀ràn. Nítorí náà yára ránṣẹ́ nísinsin yìí kí o sì sọ fún Dafidi pé, ‘Má ṣe dúró ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ijù náà lálẹ́ yìí, ṣùgbọ́n yára rékọjá kí a má bá a gbé ọba mì, àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ.’ ” Jonatani àti Ahimasi sì dúró ní En-Rogeli ọ̀dọ́mọdébìnrin kan sì lọ, ó sì sọ fún wọn, wọ́n sì lọ wọ́n sọ fún Dafidi ọba nítorí pé kí a má bá à rí wọn pé wọ́n wọ ìlú. Ṣùgbọ́n ọ̀dọ́mọdékùnrin kan rí wọn, ó sì wí fún Absalomu: ṣùgbọ́n àwọn méjèèjì sì yára lọ kúrò, wọ́n sì wá sí ilé ọkùnrin kan ní Bahurimu, ẹni tí ó ní kànga kan ní ọgbà rẹ̀, wọ́n sì sọ̀kalẹ̀ sí ibẹ̀. Obìnrin rẹ̀ sì mú nǹkan ó fi bo kànga náà, ó sì sá àgbàdo sórí rẹ̀, a kò sì mọ̀. Àwọn ìránṣẹ́ Absalomu sì tọ obìnrin náà wá sí ilé náà, wọ́n sì béèrè pé, “Níbo ni Ahimasi àti Jonatani gbé wà?” Obìnrin náà sì wí fún wọn pé, “Wọ́n ti gòkè rékọjá ìṣàn odò náà.” Wọ́n sì wá wọn kiri, wọn kò sì rí wọn, wọ́n sì yípadà sí Jerusalẹmu. Ó sì ṣe lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti lọ tán, àwọn ọkùnrin náà sì jáde kúrò nínú kànga, wọ́n sì lọ wọ́n sì rò fún Dafidi ọba. Wọ́n sọ fún Dafidi pé, “Dìde kí o sì gòkè odò kánkán: nítorí pé báyìí ni Ahitofeli gbìmọ̀ sí ọ.” Dafidi sì dìde, àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì gòkè odò Jordani: kí ilẹ̀ tó mọ́, ènìyàn kò kù tí kò gòkè odò Jordani. Nígbà tí Ahitofeli sì rí i pé wọn kò fi ìmọ̀ tirẹ̀ ṣe, ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ni gàárì, ó sì dìde, ó lọ ilé rẹ̀, ó sì palẹ̀ ilé rẹ̀ mọ̀, ó sì so, ó sì kú, a sì sin ín sí ibojì baba rẹ̀. Absalomu gbógun ti Dafidi. Dafidi sì wá sí Mahanaimu, Absalomu sì gòkè odò Jordani, òun àti gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli pẹ̀lú rẹ̀. Absalomu sì fi Amasa ṣe olórí ogun ní ipò Joabu: Amasa ẹni tí í ṣe ọmọ ẹnìkan, orúkọ ẹni tí a ń pè ní Itira, ará Israẹli, tí ó wọlé tọ Abigaili ọmọbìnrin Nahaṣi, arábìnrin Seruiah, ìyá Joabu. Israẹli àti Absalomu sì dó ní ilẹ̀ Gileadi. Nígbà tí Dafidi sì wá sí Mahanaimu, Ṣobi ọmọ Nahaṣi ti Rabba tí àwọn ọmọ Ammoni, àti Makiri ọmọ Ammieli ti Lo-Debari, àti Barsillai ará Gileadi ti Rogelimu. Mú àwọn àkéte, àti àwọn àwo, àti ìkòkò amọ̀, àti alikama, àti ọkà barle, àti ìyẹ̀fun, àti àgbàdo díndín, àti ẹ̀wà, àti erèé, àti lẹntili. Àti oyin, àti òrí-àmọ́, àti àgùntàn, àti wàràǹkàṣì màlúù, wá fún Dafidi àti fún àwọn ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀, láti jẹ: nítorí tí wọ́n wí pé, “Ebi ń pa àwọn ènìyàn, ó sì rẹ̀ wọ́n, òǹgbẹ sì ń gbẹ wọ́n ní aginjù.”