AHITOFELI si wi fun Absalomu pe, Emi o si yan ẹgbãfa ọkunrin emi o si dide, emi o si lepa Dafidi li oru yi.
Emi o si yọ si i nigbati ãrẹ̀ ba mu u ti ọwọ́ rẹ̀ si ṣe alaile, emi o si dá ipaiya bá a; gbogbo awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀ yio si sa, emi o si kọlu ọba nikanṣoṣo:
Emi o si mu gbogbo awọn enia pada sọdọ rẹ; ọkunrin na ti iwọ nwá si ri gẹgẹ bi ẹnipe gbogbo wọn ti pada: gbogbo awọn enia yio si wà li alafia.
Ọrọ na si tọ loju Absalomu, ati li oju gbogbo awọn agbà Israeli.
Absalomu si wipe, Njẹ̀ pe Huṣai ará Arki, awa o si gbọ́ eyi ti o wà li ẹnu rẹ̀ pẹlu.
Huṣai si de ọdọ Absalomu, Absalomu si wi fun u pe, Bayi ni Ahitofeli wi, ki awa ki o ṣe bi ọ̀rọ rẹ̀ bi? bi kò ba si tọ bẹ̃, iwọ wi.
Huṣai si wi fun Absalomu pe, Imọ̀ ti Ahitofeli gbà nì, ko dara nisisiyi.
Huṣai si wipe, Iwọ mọ̀ baba rẹ ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ pe alagbara ni nwọn, nwọn si wà ni kikoro ọkàn bi amọ̀tẹkun ti a gbà li ọmọ ni igbẹ: baba rẹ si jẹ jagunjagun ọkunrin, kì yio ba awọn enia na gbe pọ̀ li oru.
Kiyesi i o ti fi ara rẹ̀ pamọ nisisiyi ni iho kan, tabi ni ibomiran: yio si ṣe, nigbati diẹ ninu wọn ba kọ ṣubu, ẹnikẹni ti o ba gbọ́ yio si wipe, Iparun si mbẹ ninu awọn enia ti ntọ̀ Absalomu lẹhin.
Ẹniti o si ṣe alagbara, ti ọkàn rẹ̀ si dabi ọkàn kiniun, yio si rẹ̀ ẹ: nitori gbogbo Israeli ti mọ̀ pe alagbara ni baba rẹ, ati pe, awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀ jẹ alagbara.
Nitorina emi damọ̀ran pe, Ki gbogbo Israeli wọjọ pọ̀ sọ̀dọ rẹ, lati Dani titi dé Beerṣeba, gẹgẹ bi yanrin ti o wà leti okun fun ọ̀pọlọpọ; ati pe, ki iwọ tikararẹ ki o lọ si ogun na.
Awa o si yọ si i nibikibi ti awa o gbe ri i, awa o si yi i ka bi irì iti sẹ̀ si ilẹ̀: ani ọkan kì yio kù pẹlu rẹ̀ ninu gbogbo awọn ọmọkunrin ti o wà lọdọ rẹ̀.
Bi o ba si bọ si ilu kan, gbogbo Israeli yio si mu okùn wá si ilu na, awa o si fà a lọ si odo, titi a kì yio fi ri okuta kekeke kan nibẹ.