II. Sam 17:1-13
II. Sam 17:1-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
AHITOFELI si wi fun Absalomu pe, Emi o si yan ẹgbãfa ọkunrin emi o si dide, emi o si lepa Dafidi li oru yi. Emi o si yọ si i nigbati ãrẹ̀ ba mu u ti ọwọ́ rẹ̀ si ṣe alaile, emi o si dá ipaiya bá a; gbogbo awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀ yio si sa, emi o si kọlu ọba nikanṣoṣo: Emi o si mu gbogbo awọn enia pada sọdọ rẹ; ọkunrin na ti iwọ nwá si ri gẹgẹ bi ẹnipe gbogbo wọn ti pada: gbogbo awọn enia yio si wà li alafia. Ọrọ na si tọ loju Absalomu, ati li oju gbogbo awọn agbà Israeli. Absalomu si wipe, Njẹ̀ pe Huṣai ará Arki, awa o si gbọ́ eyi ti o wà li ẹnu rẹ̀ pẹlu. Huṣai si de ọdọ Absalomu, Absalomu si wi fun u pe, Bayi ni Ahitofeli wi, ki awa ki o ṣe bi ọ̀rọ rẹ̀ bi? bi kò ba si tọ bẹ̃, iwọ wi. Huṣai si wi fun Absalomu pe, Imọ̀ ti Ahitofeli gbà nì, ko dara nisisiyi. Huṣai si wipe, Iwọ mọ̀ baba rẹ ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ pe alagbara ni nwọn, nwọn si wà ni kikoro ọkàn bi amọ̀tẹkun ti a gbà li ọmọ ni igbẹ: baba rẹ si jẹ jagunjagun ọkunrin, kì yio ba awọn enia na gbe pọ̀ li oru. Kiyesi i o ti fi ara rẹ̀ pamọ nisisiyi ni iho kan, tabi ni ibomiran: yio si ṣe, nigbati diẹ ninu wọn ba kọ ṣubu, ẹnikẹni ti o ba gbọ́ yio si wipe, Iparun si mbẹ ninu awọn enia ti ntọ̀ Absalomu lẹhin. Ẹniti o si ṣe alagbara, ti ọkàn rẹ̀ si dabi ọkàn kiniun, yio si rẹ̀ ẹ: nitori gbogbo Israeli ti mọ̀ pe alagbara ni baba rẹ, ati pe, awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀ jẹ alagbara. Nitorina emi damọ̀ran pe, Ki gbogbo Israeli wọjọ pọ̀ sọ̀dọ rẹ, lati Dani titi dé Beerṣeba, gẹgẹ bi yanrin ti o wà leti okun fun ọ̀pọlọpọ; ati pe, ki iwọ tikararẹ ki o lọ si ogun na. Awa o si yọ si i nibikibi ti awa o gbe ri i, awa o si yi i ka bi irì iti sẹ̀ si ilẹ̀: ani ọkan kì yio kù pẹlu rẹ̀ ninu gbogbo awọn ọmọkunrin ti o wà lọdọ rẹ̀. Bi o ba si bọ si ilu kan, gbogbo Israeli yio si mu okùn wá si ilu na, awa o si fà a lọ si odo, titi a kì yio fi ri okuta kekeke kan nibẹ.
II. Sam 17:1-13 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn náà, Ahitofeli wí fún Absalomu pé, “Jẹ́ kí n ṣa ẹgbaafa (12,000) ninu àwọn ọmọ ogun, kí n sì bẹ̀rẹ̀ sí lépa Dafidi lọ lálẹ́ òní. N óo kọlù ú nígbà tí àárẹ̀ bá mú un; tí ọkàn rẹ̀ sì rẹ̀wẹ̀sì; ẹ̀rù yóo bà á, gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ yóo sì sá lọ. Ọba nìkan ṣoṣo ni n óo pa. N óo sì kó gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ, gẹ́gẹ́ bí iyawo tí ó lọ bá ọkọ rẹ̀ nílé. Ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo ni o fẹ́ pa, àwọn eniyan yòókù yóo sì wà ní alaafia.” Ìmọ̀ràn náà dára lójú Absalomu ati gbogbo àgbààgbà Israẹli. Ṣugbọn Absalomu dáhùn pé, “Ẹ pe Huṣai wá, kí á gbọ́ ohun tí òun náà yóo sọ.” Nígbà tí Huṣai dé, Absalomu wí fún un pé, “Ìmọ̀ràn tí Ahitofeli fún wa nìyí, ṣé kí á tẹ̀lé e? Bí kò bá yẹ kí á tẹ̀lé e, sọ ohun tí ó yẹ kí á ṣe fún wa.” Huṣai dáhùn pé, “Ìmọ̀ràn tí Ahitofeli fún Kabiyesi ní àkókò yìí, kò dára. Ṣebí o mọ̀ pé, akikanju jagunjagun ni baba rẹ, ati àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀? Ara kan wọ́n báyìí, wọn yóo sì rorò ju abo ẹkùn beari tí ọdẹ jí lọ́mọ kó lọ. Bẹ́ẹ̀ sì ni jagunjagun tí ó ní ọpọlọpọ ìrírí ni baba rẹ, kò sì ní sùn lọ́dọ̀ àwọn eniyan rẹ̀ ní alẹ́ yìí. Bóyá bí a ti ń sọ̀rọ̀ yìí, ninu ihò ilẹ̀ níbìkan ni ó wà tabi ibòmíràn. Bí Dafidi bá kọlu àwọn eniyan rẹ, tí wọ́n sì pa díẹ̀ ninu wọn, àwọn tí wọ́n bá gbọ́ yóo wí pé wọ́n ti ṣẹgun àwọn eniyan Absalomu. Nígbà náà, ẹ̀rù yóo ba àwọn tí wọ́n jẹ́ akikanju jùlọ ninu àwọn eniyan rẹ, tí wọ́n sì láyà bíi kinniun; nítorí pé, gbogbo eniyan ní Israẹli ni ó mọ̀ pé akọni jagunjagun ni baba rẹ, akikanju sì ni àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀. Ìmọ̀ràn tèmi ni pé kí o kó gbogbo àwọn ọmọ ogun jọ jákèjádò ilẹ̀ Israẹli láti Dani títí dé Beeriṣeba, kí wọ́n pọ̀ bíi yanrìn etí òkun. Ìwọ gan-an ni kí o ṣáájú wọn lọ sí ogun náà. A óo kọlu Dafidi níbikíbi tí a bá ti bá a, a óo bò wọ́n bí ìgbà tí ìrì bá sẹ̀ sórí ilẹ̀; ẹnikẹ́ni kò sì ní yè ninu òun ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Bí ó bá sá wọ inú ìlú kan, àwọn ọmọ Israẹli yóo fi okùn fa ìlú náà lulẹ̀ sinu àfonífojì tí ó wà ní ìsàlẹ̀. Ẹyọ òkúta kan ṣoṣo kò ní ṣẹ́kù sórí òkè náà.”
II. Sam 17:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ahitofeli sì wí fún Absalomu pé, “Èmi ó yan ẹgbàafà ọkùnrin èmi ó sì dìde, èmi ó sì lépa Dafidi lóru yìí. Èmi ó sì yọ sí i nígbà tí àárẹ̀ bá mú un tí ọwọ́ rẹ̀ sì ṣe aláìle, èmi ó sì dá a ní ìjì: gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ yóò sì sá, èmi ó sì kọlu ọba nìkan ṣoṣo. Èmi ó sì mú gbogbo àwọn ènìyàn padà sọ́dọ̀ rẹ bi ìgbà tí ìyàwó bá padà sí ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀. Ọkàn ẹnìkan ṣoṣo tí ìwọ ń wá yìí ni ó túmọ̀ sí ìpadàbọ̀ gbogbo wọn; gbogbo àwọn ènìyàn yóò sì wà ní àlàáfíà.” Ọ̀rọ̀ náà sì tọ́ lójú Absalomu, àti lójú gbogbo àwọn àgbàgbà Israẹli. Absalomu sì wí pé, “Ǹjẹ́ pe Huṣai ará Arki, àwa ó sì gbọ́ èyí tí ó wà lẹ́nu rẹ̀ pẹ̀lú.” Huṣai sì dé ọ̀dọ̀ Absalomu, Absalomu sì wí fún un pé, “Báyìí ni Ahitofeli wí, kí àwa ṣe bí ọ̀rọ̀ rẹ bí? Bí ko bá sì tọ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ wí.” Huṣai sì wí fún Absalomu pé, “Ìmọ̀ tí Ahitofeli gbà yìí, kò dára nísinsin yìí.” Huṣai sì wí pé, “Ìwọ mọ baba rẹ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé alágbára ni wọ́n, wọ́n sì wà ní kíkorò ọkàn bí àmọ̀tẹ́kùn tí a gbà ní ọmọ ni pápá: baba rẹ sì jẹ́ jagunjagun ọkùnrin kì yóò bá àwọn ènìyàn náà gbé pọ̀ lóru. Kíyèsi i, ó ti fi ara rẹ̀ pamọ́ nísinsin yìí ni ihò kan, tàbí ní ibòmíràn: yóò sì ṣe, nígbà tí díẹ̀ nínú wọn bá kọ́ ṣubú, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ yóò sì wí pé, ‘Ìparun sì ń bẹ́ nínú àwọn ènìyàn tí ń tọ Absalomu lẹ́yìn.’ Ẹni tí ó sì ṣe alágbára, tí ọkàn rẹ̀ sì dàbí ọkàn kìnnìún, yóò sì rẹ̀ ẹ́: nítorí gbogbo Israẹli ti mọ̀ pé alágbára ni baba rẹ, àti pé, àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ jẹ́ alágbára. “Nítorí náà èmi dámọ̀ràn pé: Kí gbogbo Israẹli wọ́jọ pọ̀ sọ́dọ̀ rẹ, láti Dani títí dé Beerṣeba, gẹ́gẹ́ bí iyanrìn létí Òkun fún ọ̀pọ̀lọpọ̀; àti pé, kí ìwọ tìkára rẹ̀ ó lọ sí ogun náà. Àwa ó sì yọ sí i níbikíbi tí àwa o gbé rí i, àwa ó sì yí i ká bí ìrì ti ń ṣẹ̀ sí ilẹ̀ àní, ọkàn kan kì yóò kù pẹ̀lú rẹ̀ nínú gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Bí o bá sì bọ́ sí ìlú kan, gbogbo Israẹli yóò mú okùn wá sí ìlú náà, àwa ó sì fà á lọ sí odò, títí a kì yóò fi rí òkúta kéékèèkéé kan níbẹ̀.”