Ọba si dahùn, o si wi fun obinrin na pe, Máṣe fi nkan ti emi o bere lọwọ rẹ pamọ fun mi, emi bẹ̀ ọ. Obinrin na si wipe, Jẹ ki oluwa mi ọba ki o mã wi.
Ọba si wipe, Ọwọ́ Joabu kò ha wà pẹlu rẹ ninu gbogbo eyi? obinrin na si dahun o si wipe, Bi ẹmi rẹ ti mbẹ lãye, oluwa mi ọba, kò si iyipada si ọwọ́ ọtun, tabi si ọwọ́ osi ninu gbogbo eyi ti oluwa mi ọba ti wi: nitoripe Joabu iranṣẹ rẹ, on li o rán mi, on li o si fi gbogbo ọ̀rọ wọnyi si iranṣẹbinrin rẹ li ẹnu.
Lati mu iru ọ̀rọ wọnyi wá ni Joabu iranṣẹ rẹ si ṣe nkan yi: oluwa mi si gbọ́n, gẹgẹ bi ọgbọ́n angeli Ọlọrun, lati mọ̀ gbogbo nkan ti mbẹ li aiye.
Ọba si wi fun Joabu pe, Wõ, emi o ṣe nkan yi: nitorina lọ, ki o si mu ọmọdekunrin na Absalomu pada wá.
Joabu si wolẹ o doju rẹ̀ bolẹ, o si tẹriba fun u, o si sure fun ọba: Joabu si wipe, Loni ni iranṣẹ rẹ mọ̀ pe, emi ri ore-ọfẹ gbà li oju rẹ, oluwa mi, ọba, nitoripe ọba ṣe ifẹ iranṣẹ rẹ.
Joabu si dide, o si lọ si Geṣuri, o si mu Absalomu wá si Jerusalemu.
Ọba si wipe, Jẹ ki o yipada lọ si ile rẹ̀, má si ṣe jẹ ki o ri oju mi. Absalomu si yipada si ile rẹ̀, kò si ri oju ọba.
Kò si si arẹwà kan ni gbogbo Israeli ti a ba yìn bi Absalomu: lati atẹlẹsẹ rẹ̀ titi de atari rẹ̀ kò si abùkun kan lara rẹ̀.
Nigbati o ba si rẹ́ irun ori rẹ̀ (nitoripe li ọdọdun li on ima rẹ́ ẹ nitoriti o wuwo fun u, on a si ma rẹ́ ẹ) on si wọ̀n irun ori rẹ̀, o si jasi igba ṣekeli ninu òṣuwọn ọba.
A si bi ọmọkunrin mẹta fun Absalomu ati ọmọbinrin kan, orukọ rẹ̀ a si ma jẹ́ Tamari: on si jẹ obinrin ti o li ẹwà loju.
Absalomu si joko li ọdun meji ni Jerusalemu kò si ri oju ọba.
Absalomu si ranṣẹ si Joabu, lati rán a si ọba; ṣugbọn on kò fẹ wá sọdọ rẹ̀; o si ranṣẹ lẹ̃keji on kò si fẹ wá.
O si wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Wõ, oko Joabu gbè ti emi, o si ni ọkà nibẹ; ẹ lọ ki ẹ si tinabọ̀ ọ. Awọn iranṣẹ Absalomu si tinabọ oko na.
Joabu si dide, o si tọ Absalomu wá ni ile, o si wi fun u pe, Ẽṣe ti awọn iranṣẹ rẹ fi tinabọ oko mi?
Absalomu si da Joabu lohùn pe, Wõ, emi ranṣẹ si ọ, wipe, Wá nihinyi, emi o si rán ọ lọ sọdọ ọba, lati wi pe, Kili emi ti Geṣuri wá si? iba sàn fun mi bi o ṣepe emi wà nibẹ̀ sibẹ. Njẹ emi nfẹ ri oju ọba; bi o ba si ṣe pe ẹ̀ṣẹ mbẹ li ara mi, ki o pa mi.
Joabu si tọ̀ ọba wá, o si rò fun u: o si ranṣẹ pe Absalomu, on si wá sọdọ ọba, o tẹriba fun u, o si doju rẹ̀ bolẹ niwaju ọba; ọba si fi ẹnu ko Absalomu li ẹnu.