II. Sam 14:18-33

II. Sam 14:18-33 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ọba si dahùn, o si wi fun obinrin na pe, Máṣe fi nkan ti emi o bere lọwọ rẹ pamọ fun mi, emi bẹ̀ ọ. Obinrin na si wipe, Jẹ ki oluwa mi ọba ki o mã wi. Ọba si wipe, Ọwọ́ Joabu kò ha wà pẹlu rẹ ninu gbogbo eyi? obinrin na si dahun o si wipe, Bi ẹmi rẹ ti mbẹ lãye, oluwa mi ọba, kò si iyipada si ọwọ́ ọtun, tabi si ọwọ́ osi ninu gbogbo eyi ti oluwa mi ọba ti wi: nitoripe Joabu iranṣẹ rẹ, on li o rán mi, on li o si fi gbogbo ọ̀rọ wọnyi si iranṣẹbinrin rẹ li ẹnu. Lati mu iru ọ̀rọ wọnyi wá ni Joabu iranṣẹ rẹ si ṣe nkan yi: oluwa mi si gbọ́n, gẹgẹ bi ọgbọ́n angeli Ọlọrun, lati mọ̀ gbogbo nkan ti mbẹ li aiye. Ọba si wi fun Joabu pe, Wõ, emi o ṣe nkan yi: nitorina lọ, ki o si mu ọmọdekunrin na Absalomu pada wá. Joabu si wolẹ o doju rẹ̀ bolẹ, o si tẹriba fun u, o si sure fun ọba: Joabu si wipe, Loni ni iranṣẹ rẹ mọ̀ pe, emi ri ore-ọfẹ gbà li oju rẹ, oluwa mi, ọba, nitoripe ọba ṣe ifẹ iranṣẹ rẹ. Joabu si dide, o si lọ si Geṣuri, o si mu Absalomu wá si Jerusalemu. Ọba si wipe, Jẹ ki o yipada lọ si ile rẹ̀, má si ṣe jẹ ki o ri oju mi. Absalomu si yipada si ile rẹ̀, kò si ri oju ọba. Kò si si arẹwà kan ni gbogbo Israeli ti a ba yìn bi Absalomu: lati atẹlẹsẹ rẹ̀ titi de atari rẹ̀ kò si abùkun kan lara rẹ̀. Nigbati o ba si rẹ́ irun ori rẹ̀ (nitoripe li ọdọdun li on ima rẹ́ ẹ nitoriti o wuwo fun u, on a si ma rẹ́ ẹ) on si wọ̀n irun ori rẹ̀, o si jasi igba ṣekeli ninu òṣuwọn ọba. A si bi ọmọkunrin mẹta fun Absalomu ati ọmọbinrin kan, orukọ rẹ̀ a si ma jẹ́ Tamari: on si jẹ obinrin ti o li ẹwà loju. Absalomu si joko li ọdun meji ni Jerusalemu kò si ri oju ọba. Absalomu si ranṣẹ si Joabu, lati rán a si ọba; ṣugbọn on kò fẹ wá sọdọ rẹ̀; o si ranṣẹ lẹ̃keji on kò si fẹ wá. O si wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Wõ, oko Joabu gbè ti emi, o si ni ọkà nibẹ; ẹ lọ ki ẹ si tinabọ̀ ọ. Awọn iranṣẹ Absalomu si tinabọ oko na. Joabu si dide, o si tọ Absalomu wá ni ile, o si wi fun u pe, Ẽṣe ti awọn iranṣẹ rẹ fi tinabọ oko mi? Absalomu si da Joabu lohùn pe, Wõ, emi ranṣẹ si ọ, wipe, Wá nihinyi, emi o si rán ọ lọ sọdọ ọba, lati wi pe, Kili emi ti Geṣuri wá si? iba sàn fun mi bi o ṣepe emi wà nibẹ̀ sibẹ. Njẹ emi nfẹ ri oju ọba; bi o ba si ṣe pe ẹ̀ṣẹ mbẹ li ara mi, ki o pa mi. Joabu si tọ̀ ọba wá, o si rò fun u: o si ranṣẹ pe Absalomu, on si wá sọdọ ọba, o tẹriba fun u, o si doju rẹ̀ bolẹ niwaju ọba; ọba si fi ẹnu ko Absalomu li ẹnu.

II. Sam 14:18-33 Yoruba Bible (YCE)

Ọba dá obinrin náà lóhùn pé, “Ọ̀rọ̀ kan ni mo fẹ́ bèèrè lọ́wọ́ rẹ, mo sì fẹ́ kí o sọ òtítọ́ rẹ̀ fún mi.” Obinrin náà dáhùn pé, “Kabiyesi, bèèrè ohunkohun tí o bá fẹ́.” Ọba bá bí i pé, “Ṣé Joabu ni ó rán ọ ní gbogbo iṣẹ́ tí o wá jẹ́ yìí, àbí òun kọ?” Obinrin náà dáhùn pé, “Kabiyesi, bí o ti bèèrè ìbéèrè yìí kò jẹ́ kí n mọ̀ bí mo ti lè yí ẹnu pada rárá. Òtítọ́ ni, Joabu ni ó kọ́ mi ní gbogbo ohun tí mo sọ, ati gbogbo bí mo ti ṣe. Ṣugbọn, òun náà fẹ́ tún nǹkan ṣe, ni ó fi ṣe ohun tí ó ṣe. Ṣugbọn kabiyesi ní ọgbọ́n bí angẹli Ọlọ́run, láti mọ ohun gbogbo lórí ilẹ̀ ayé.” Nígbà náà ni ọba sọ fún Joabu pé, “Mo ti pinnu láti ṣe ohun tí o fẹ́ kí n ṣe. Lọ, kí o sì mú Absalomu, ọmọ mi, pada wá.” Joabu bá wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ ọba, ó ní, “Kabiyesi, nisinsinyii ni èmi iranṣẹ rẹ mọ̀ pé mo ti bá ojurere rẹ pàdé, nítorí pé o ṣe ohun tí mo fẹ́.” Joabu bá gbéra, ó lọ sí Geṣuri, ó sì mú Absalomu pada wá sí Jerusalẹmu. Ṣugbọn ọba pàṣẹ pé kí Absalomu máa gbé ilé rẹ̀, nítorí pé òun kò fẹ́ rí i sójú. Nítorí náà, inú ilé Absalomu ni ó ń gbé, kò sì dé ọ̀dọ̀ ọba rárá. Kò sí ẹyọ ẹnìkan ní gbogbo Israẹli tí òkìkí ẹwà rẹ̀ kàn bí ti Absalomu. Kò sí àbùkù kankan rárá lára rẹ̀ bí ti í wù kó mọ, láti orí títí dé àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀. Ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún ni í máa ń gé irun orí rẹ̀, nígbà tí ó bá kún, tí ó sì gùn ju bí ó ti yẹ lọ. Tí wọ́n bá fi ìwọ̀n ọba wọn èyí tí wọ́n bá gé lára irun rẹ̀, a máa tó igba ṣekeli. Absalomu bí ọmọkunrin mẹta ati ọmọbinrin kan. Tamari ni orúkọ ọmọbinrin yìí, ó sì jẹ́ arẹwà. Ọdún meji ni Absalomu fi gbé Jerusalẹmu láì fi ojú kan ọba. Ní ọjọ́ kan, ó ranṣẹ sí Joabu, pé kí ó wá mú òun lọ sọ́dọ̀ ọba, ṣugbọn Joabu kọ̀, kò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Absalomu ranṣẹ pe Joabu lẹẹkeji, Joabu sì tún kọ̀, kò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Absalomu bá pe àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Oko Joabu wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ tèmi, ó sì gbin ọkà baali sinu rẹ̀, ẹ lọ fi iná sí oko náà.” Wọ́n bá lọ, wọ́n sì ti iná bọ oko Joabu. Nígbà náà ni Joabu lọ sí ilé Absalomu, ó bi í pé, “Kí ló dé tí àwọn iranṣẹ rẹ fi ti iná bọ oko mi?” Absalomu dáhùn pé, “Nítorí pé mo ranṣẹ pè ọ́, pé kí o wá, kí n lè rán ọ lọ bèèrè lọ́wọ́ ọba pé, ‘Kí ni mo kúrò ní Geṣuri tí mo sì wá síhìn-ín fún? Ìbá sàn kí n kúkú wà lọ́hùn-ún.’ Mo fẹ́ kí o ṣe ètò kí n lè fi ojú kan ọba, bí ó bá sì jẹ́ pé mo jẹ̀bi, kí ó pa mí.” Joabu bá tọ Dafidi ọba lọ, ó sì sọ ohun tí Absalomu wí fún un. Ọba ranṣẹ pe Absalomu, ó sì wá sọ́dọ̀ ọba. Ó wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀ níwájú rẹ̀, ọba bá fi ẹnu kò ó ní ẹnu.

II. Sam 14:18-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ọba sì dáhùn, ó sì wí fún obìnrin náà pé, “Má ṣe fi nǹkan tí èmi ó béèrè lọ́wọ́ rẹ pamọ́ fún mi, èmi bẹ̀ ọ́.” Obìnrin náà wí pé, “Jẹ́ kí olúwa mi ọba máa wí?” Ọba sì wí pé, “Ọwọ́ Joabu kò ha wà pẹ̀lú rẹ nínú gbogbo èyí?” Obìnrin náà sì dáhùn ó sì wí pé, “Bí ẹ̀mí rẹ ti ń bẹ láààyè, olúwa mi ọba, kò sí ìyípadà sí ọwọ́ ọ̀tún, tàbí sí ọwọ́ òsì nínú gbogbo èyí tí olúwa mi ọba ti wí: nítorí pé Joabu ìránṣẹ́ rẹ, òun ni ó rán mi, òun ni ó sì fi gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí ìránṣẹ́bìnrin rẹ lẹ́nu. Láti mú irú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wá ni Joabu ìránṣẹ́ rẹ ṣe ṣe nǹkan yìí: olúwa mi sì gbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n angẹli Ọlọ́run, láti mọ gbogbo nǹkan tí ń bẹ̀ ní ayé.” Ọba sì wí fún Joabu pé, “Wò ó, èmi ó ṣe nǹkan yìí: nítorí náà lọ, kí o sì mú ọmọdékùnrin náà Absalomu padà wá.” Joabu sì wólẹ̀ ó dojú rẹ̀ bolẹ̀, ó sì tẹríba fún un, ó sì súre fún ọba. Joabu sì wí pé, “Lónìí ni ìránṣẹ́ rẹ mọ̀ pé, èmi rí oore-ọ̀fẹ́ gbà lójú rẹ, olúwa mi, ọba, nítorí pé ọba ṣe ìfẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀.” Joabu sì dìde, ó sì lọ sí Geṣuri, ó sì mú Absalomu wá sí Jerusalẹmu. Ọba sì wí pé, “Jẹ́ kí ó yípadà lọ sí ilé rẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ó rí ojú mi.” Absalomu sì yípadà sí ilé rẹ̀, kò sì rí ojú ọba. Kó sì sí arẹwà kan ní gbogbo Israẹli tí à bá yìn bí Absalomu: láti àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀ kò sí àbùkù kan lára rẹ̀. Nígbà tí ó bá sì rẹ́ irun orí rẹ̀ (nítorí pé lọ́dọọdún ni òun máa ń rẹ́ ẹ. Nígbà tí ó bá wúwo fún un, òun a sì máa rẹ́ ẹ) òun sì wọn irun orí rẹ̀, ó sì jásí igba ṣékélì nínú òṣùwọ̀n ọba. A sì bí ọmọkùnrin mẹ́ta fún Absalomu àti ọmọbìnrin kan ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tamari: òun sì jẹ́ obìnrin tí ó lẹ́wà lójú. Absalomu sì gbé ni ọdún méjì ní Jerusalẹmu kò sì rí ojú ọba. Absalomu sì ránṣẹ́ sí Joabu, láti rán an sí ọba: ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ wá sọ́dọ̀ rẹ̀; ó sì ránṣẹ́ lẹ́ẹ̀kejì òun kò sì fẹ́ wá. Ó sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Wò ó, oko Joabu gbé ti èmi, ó sì ní ọkà barle níbẹ̀; ẹ lọ kí ẹ sì ti iná bọ̀ ọ́.” Àwọn ìránṣẹ́ Absalomu sì tiná bọ oko náà. Joabu sì dìde, ó sì tọ Absalomu wá ní ilé, ó sì wí fún un pé, “Èéṣe tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ fi tiná bọ oko mi?” Absalomu sì dá Joabu lóhùn pé, “Wò ó, èmi ránṣẹ́ sí ọ, wí pé, ‘Wá níhìn-ín yìí, èmi ó sì rán ọ lọ sọ́dọ̀ ọba, láti béèrè pé, “Kí ni èmi ti Geṣuri wá si? Ìbá sàn fún mí bí ó ṣe pé èmi wà lọ́hùn ún síbẹ̀!” ’ Ǹjẹ́ nísinsin yìí jẹ́ kí èmi lọ síwájú ọba bí ó bá sì ṣe ẹ̀bi ń bẹ nínú mi, kí ó pa mí.” Joabu sì tọ ọba wá, ó sì rò fún un: ó sì ránṣẹ́ pe Absalomu, òun sì wá sọ́dọ̀ ọba, ó tẹríba fún un, ó sì dojú rẹ̀ bolẹ̀ níwájú ọba, ọba sì fi ẹnu ko Absalomu lẹ́nu.