SAMUẸLI KEJI 14:18-33

SAMUẸLI KEJI 14:18-33 YCE

Ọba dá obinrin náà lóhùn pé, “Ọ̀rọ̀ kan ni mo fẹ́ bèèrè lọ́wọ́ rẹ, mo sì fẹ́ kí o sọ òtítọ́ rẹ̀ fún mi.” Obinrin náà dáhùn pé, “Kabiyesi, bèèrè ohunkohun tí o bá fẹ́.” Ọba bá bí i pé, “Ṣé Joabu ni ó rán ọ ní gbogbo iṣẹ́ tí o wá jẹ́ yìí, àbí òun kọ?” Obinrin náà dáhùn pé, “Kabiyesi, bí o ti bèèrè ìbéèrè yìí kò jẹ́ kí n mọ̀ bí mo ti lè yí ẹnu pada rárá. Òtítọ́ ni, Joabu ni ó kọ́ mi ní gbogbo ohun tí mo sọ, ati gbogbo bí mo ti ṣe. Ṣugbọn, òun náà fẹ́ tún nǹkan ṣe, ni ó fi ṣe ohun tí ó ṣe. Ṣugbọn kabiyesi ní ọgbọ́n bí angẹli Ọlọ́run, láti mọ ohun gbogbo lórí ilẹ̀ ayé.” Nígbà náà ni ọba sọ fún Joabu pé, “Mo ti pinnu láti ṣe ohun tí o fẹ́ kí n ṣe. Lọ, kí o sì mú Absalomu, ọmọ mi, pada wá.” Joabu bá wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ ọba, ó ní, “Kabiyesi, nisinsinyii ni èmi iranṣẹ rẹ mọ̀ pé mo ti bá ojurere rẹ pàdé, nítorí pé o ṣe ohun tí mo fẹ́.” Joabu bá gbéra, ó lọ sí Geṣuri, ó sì mú Absalomu pada wá sí Jerusalẹmu. Ṣugbọn ọba pàṣẹ pé kí Absalomu máa gbé ilé rẹ̀, nítorí pé òun kò fẹ́ rí i sójú. Nítorí náà, inú ilé Absalomu ni ó ń gbé, kò sì dé ọ̀dọ̀ ọba rárá. Kò sí ẹyọ ẹnìkan ní gbogbo Israẹli tí òkìkí ẹwà rẹ̀ kàn bí ti Absalomu. Kò sí àbùkù kankan rárá lára rẹ̀ bí ti í wù kó mọ, láti orí títí dé àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀. Ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún ni í máa ń gé irun orí rẹ̀, nígbà tí ó bá kún, tí ó sì gùn ju bí ó ti yẹ lọ. Tí wọ́n bá fi ìwọ̀n ọba wọn èyí tí wọ́n bá gé lára irun rẹ̀, a máa tó igba ṣekeli. Absalomu bí ọmọkunrin mẹta ati ọmọbinrin kan. Tamari ni orúkọ ọmọbinrin yìí, ó sì jẹ́ arẹwà. Ọdún meji ni Absalomu fi gbé Jerusalẹmu láì fi ojú kan ọba. Ní ọjọ́ kan, ó ranṣẹ sí Joabu, pé kí ó wá mú òun lọ sọ́dọ̀ ọba, ṣugbọn Joabu kọ̀, kò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Absalomu ranṣẹ pe Joabu lẹẹkeji, Joabu sì tún kọ̀, kò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Absalomu bá pe àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Oko Joabu wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ tèmi, ó sì gbin ọkà baali sinu rẹ̀, ẹ lọ fi iná sí oko náà.” Wọ́n bá lọ, wọ́n sì ti iná bọ oko Joabu. Nígbà náà ni Joabu lọ sí ilé Absalomu, ó bi í pé, “Kí ló dé tí àwọn iranṣẹ rẹ fi ti iná bọ oko mi?” Absalomu dáhùn pé, “Nítorí pé mo ranṣẹ pè ọ́, pé kí o wá, kí n lè rán ọ lọ bèèrè lọ́wọ́ ọba pé, ‘Kí ni mo kúrò ní Geṣuri tí mo sì wá síhìn-ín fún? Ìbá sàn kí n kúkú wà lọ́hùn-ún.’ Mo fẹ́ kí o ṣe ètò kí n lè fi ojú kan ọba, bí ó bá sì jẹ́ pé mo jẹ̀bi, kí ó pa mí.” Joabu bá tọ Dafidi ọba lọ, ó sì sọ ohun tí Absalomu wí fún un. Ọba ranṣẹ pe Absalomu, ó sì wá sọ́dọ̀ ọba. Ó wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀ níwájú rẹ̀, ọba bá fi ẹnu kò ó ní ẹnu.