JOABU ọmọ Seruia si kiyesi i pe, ọkàn ọba si fà si Absalomu.
Joabu si ranṣẹ si Tekoa, o si mu ọlọgbọn obinrin kan lati ibẹ̀ wá, o si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, ṣe bi ẹniti nṣọfọ, ki o si fi aṣọ ọfọ sara, ki o má si ṣe fi ororo pa ara, ki o si dabi obinrin ti o ti nṣọ̀fọ fun okú li ọjọ pupọ̀.
Ki o si tọ̀ ọba wá, ki o si sọ fun u gẹgẹ bi ọ̀rọ yi. Joabu si fi ọ̀rọ si i li ẹnu.
Nigbati obinrin ará Tekoa na si nfẹ sọ̀rọ fun ọba, o wolẹ, o dojubolẹ, o si bu ọla fun u, o si wipe, Ọba, gbà mi.
Ọba si bi i lere pe, Ki li o ṣe ọ? on si dahùn wipe, Nitõtọ, opó li emi iṣe, ọkọ mi si kú.
Iranṣẹbinrin rẹ si ti li ọmọkunrin meji, awọn mejeji si jọ jà li oko, kò si si ẹniti yio là wọn, ekini si lu ekeji, o si pa a.
Si wõ, gbogbo idile dide si iranṣẹbinrin rẹ, nwọn si wipe, Fi ẹni ti o pa ẹnikeji rẹ̀ fun wa, awa o si pa a ni ipo ẹmi ẹnikeji rẹ̀ ti o pa, awa o si pa arole na run pẹlu: nwọn o si pa iná mi ti o kù, nwọn kì yio si fi orukọ tabi ẹni ti o kù silẹ fun ọkọ mi li aiye.
Ọba si wi fun obinrin na pe, Lọ si ile rẹ, emi o si kilọ nitori rẹ.
Obinrin ara Tekoa na si wi fun ọba pe, Oluwa mi, ọba, jẹ ki ẹ̀ṣẹ na ki o wà lori mi, ati lori idile baba mi; ki ọba ati itẹ rẹ̀ ki o jẹ́ alailẹbi.
Ọba si wipe, Ẹnikẹni ti o ba sọ̀rọ si ọ, mu oluwa rẹ̀ tọ̀ mi wá, on kì yio si tọ́ ọ mọ.
O si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki ọba ki o ranti Oluwa Ọlọrun rẹ̀, ki olugbẹsan ẹjẹ ki o máṣe ni ipa lati ṣe iparun, ki nwọn ki o má bà pa ọmọ mi; on si wipe, Bi Oluwa ti mbẹ lãye, ọkan ninu irun ori ọmọ rẹ ki yio bọ́ silẹ,
Obinrin na si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki iranṣẹbinrin rẹ ki o sọ̀rọ kan fun oluwa mi ọba; on si wipe, Ma wi.
Obinrin na si wipe, Nitori kini iwọ si ṣe ro iru nkan yi si awọn enia Ọlọrun? nitoripe ọba si sọ nkan yi bi ẹniti o jẹbi, nitipe ọba kò mu isánsa rẹ̀ bọ̀ wá ile.
Nitoripe awa o sa kú, a o si dabi omi ti a tú silẹ ti a kò si le ṣajọ mọ; nitori bi Ọlọrun kò ti gbà ẹmi rẹ̀, o si ti ṣe ọna ki a má bà lé isánsa rẹ̀ kuro lọdọ rẹ̀.
Njẹ nitorina li emi si ṣe wá isọ nkan yi fun oluwa mi ọba, bi o jẹpe awọn enia ti dẹrubà mi; iranṣẹbinrin rẹ si wi pe, Njẹ emi o sọ fun ọba; o le ri bẹ̃ pe ọba yio ṣe ifẹ iranṣẹbinrin rẹ̀ fun u.
Nitoripe ọba o gbọ́, lati gbà iranṣẹbinrin rẹ̀ silẹ lọwọ ọkunrin na ti o nfẹ ke emi ati ọmọ mi pẹlu kuro ninu ilẹ ini Ọlọrun.
Iranṣẹbinrin rẹ si wipe, Njẹ ọ̀rọ ọba oluwa mi yio si jasi itùnu: nitori bi angeli Ọlọrun bẹ̃ ni oluwa mi ọba lati mọ̀ rere ati buburu: Oluwa Ọlọrun rẹ yio si wà pẹlu rẹ.