II. Sam 14:1-17
II. Sam 14:1-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
JOABU ọmọ Seruia si kiyesi i pe, ọkàn ọba si fà si Absalomu. Joabu si ranṣẹ si Tekoa, o si mu ọlọgbọn obinrin kan lati ibẹ̀ wá, o si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, ṣe bi ẹniti nṣọfọ, ki o si fi aṣọ ọfọ sara, ki o má si ṣe fi ororo pa ara, ki o si dabi obinrin ti o ti nṣọ̀fọ fun okú li ọjọ pupọ̀. Ki o si tọ̀ ọba wá, ki o si sọ fun u gẹgẹ bi ọ̀rọ yi. Joabu si fi ọ̀rọ si i li ẹnu. Nigbati obinrin ará Tekoa na si nfẹ sọ̀rọ fun ọba, o wolẹ, o dojubolẹ, o si bu ọla fun u, o si wipe, Ọba, gbà mi. Ọba si bi i lere pe, Ki li o ṣe ọ? on si dahùn wipe, Nitõtọ, opó li emi iṣe, ọkọ mi si kú. Iranṣẹbinrin rẹ si ti li ọmọkunrin meji, awọn mejeji si jọ jà li oko, kò si si ẹniti yio là wọn, ekini si lu ekeji, o si pa a. Si wõ, gbogbo idile dide si iranṣẹbinrin rẹ, nwọn si wipe, Fi ẹni ti o pa ẹnikeji rẹ̀ fun wa, awa o si pa a ni ipo ẹmi ẹnikeji rẹ̀ ti o pa, awa o si pa arole na run pẹlu: nwọn o si pa iná mi ti o kù, nwọn kì yio si fi orukọ tabi ẹni ti o kù silẹ fun ọkọ mi li aiye. Ọba si wi fun obinrin na pe, Lọ si ile rẹ, emi o si kilọ nitori rẹ. Obinrin ara Tekoa na si wi fun ọba pe, Oluwa mi, ọba, jẹ ki ẹ̀ṣẹ na ki o wà lori mi, ati lori idile baba mi; ki ọba ati itẹ rẹ̀ ki o jẹ́ alailẹbi. Ọba si wipe, Ẹnikẹni ti o ba sọ̀rọ si ọ, mu oluwa rẹ̀ tọ̀ mi wá, on kì yio si tọ́ ọ mọ. O si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki ọba ki o ranti Oluwa Ọlọrun rẹ̀, ki olugbẹsan ẹjẹ ki o máṣe ni ipa lati ṣe iparun, ki nwọn ki o má bà pa ọmọ mi; on si wipe, Bi Oluwa ti mbẹ lãye, ọkan ninu irun ori ọmọ rẹ ki yio bọ́ silẹ, Obinrin na si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki iranṣẹbinrin rẹ ki o sọ̀rọ kan fun oluwa mi ọba; on si wipe, Ma wi. Obinrin na si wipe, Nitori kini iwọ si ṣe ro iru nkan yi si awọn enia Ọlọrun? nitoripe ọba si sọ nkan yi bi ẹniti o jẹbi, nitipe ọba kò mu isánsa rẹ̀ bọ̀ wá ile. Nitoripe awa o sa kú, a o si dabi omi ti a tú silẹ ti a kò si le ṣajọ mọ; nitori bi Ọlọrun kò ti gbà ẹmi rẹ̀, o si ti ṣe ọna ki a má bà lé isánsa rẹ̀ kuro lọdọ rẹ̀. Njẹ nitorina li emi si ṣe wá isọ nkan yi fun oluwa mi ọba, bi o jẹpe awọn enia ti dẹrubà mi; iranṣẹbinrin rẹ si wi pe, Njẹ emi o sọ fun ọba; o le ri bẹ̃ pe ọba yio ṣe ifẹ iranṣẹbinrin rẹ̀ fun u. Nitoripe ọba o gbọ́, lati gbà iranṣẹbinrin rẹ̀ silẹ lọwọ ọkunrin na ti o nfẹ ke emi ati ọmọ mi pẹlu kuro ninu ilẹ ini Ọlọrun. Iranṣẹbinrin rẹ si wipe, Njẹ ọ̀rọ ọba oluwa mi yio si jasi itùnu: nitori bi angeli Ọlọrun bẹ̃ ni oluwa mi ọba lati mọ̀ rere ati buburu: Oluwa Ọlọrun rẹ yio si wà pẹlu rẹ.
II. Sam 14:1-17 Yoruba Bible (YCE)
Joabu, ọmọ Seruaya, ṣe akiyesi pé ọkàn Absalomu ń fa Dafidi pupọ. Nítorí náà, ó ranṣẹ sí ọlọ́gbọ́n obinrin kan, tí ń gbé Tekoa. Nígbà tí obinrin yìí dé, Joabu wí fún un pé, “Ṣe bí ẹni pé o wà ninu ọ̀fọ̀, wọ aṣọ ọ̀fọ̀, má fi òróró para, kí o sì fi irun rẹ sílẹ̀ játijàti. Ṣe bí ẹni tí ó ti wà ninu ọ̀fọ̀ fún ọjọ́ pípẹ́; kí o lọ sọ́dọ̀ ọba, kí o sì sọ ohun tí n óo sọ fún ọ yìí fún un.” Joabu bá kọ́ ọ ní ohun tí yóo wí. Obinrin ará Tekoa náà bá tọ ọba lọ, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó dojúbolẹ̀, ó sì kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó wí fún un báyìí pé, “Kabiyesi, gbà mí.” Ọba bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni o fẹ́?” Ó dá ọba lóhùn pé, “Kabiyesi, opó ni mí, ọkọ mi ti kú. Ọmọkunrin meji ni mo bí. Ní ọjọ́ kan, àwọn mejeeji ń bá ara wọn jà ninu pápá, kò sì sí ẹnikẹ́ni nítòsí láti là wọ́n, ni ọ̀kan ninu wọn bá lu ekeji rẹ̀ pa. Nisinsinyii, kabiyesi, gbogbo àwọn eniyan mi ni wọ́n ti kẹ̀yìn sí mi. Wọ́n ní dandan kí ń fa ọmọ mi kan yòókù kalẹ̀ fún àwọn, kí wọ́n lè pa á nítorí arakunrin rẹ̀ tí ó pa. Bí mo bá gbà fún wọn, kò ní sí ẹni tí yóo jogún ọkọ mi, wọn yóo já ìrètí mi kan tí ó kù kulẹ̀, kò sì ní sí ọmọkunrin tí yóo gbé orúkọ ọkọ mi ró, tí orúkọ náà kò fi ní parun.” Ọba dá a lóhùn pé, “Máa pada lọ sí ilé rẹ, n óo mójú tó ọ̀rọ̀ náà.” Obinrin náà wí fún ọba pé, “Kabiyesi, gbogbo ohun tí o bá ṣe nípa ọ̀rọ̀ yìí, èmi ati ìdílé mi ni a ni ẹ̀bi rẹ̀, ẹ̀bi rẹ̀ kò kan kabiyesi ati ìdílé rẹ̀ rárá.” Ọba dá a lóhùn pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá tún halẹ̀ mọ́ ọ, mú olúwarẹ̀ wá sọ́dọ̀ mi, kò sì ní dé ọ̀dọ̀ rẹ mọ́ laelae.” Obinrin yìí tún wí fún ọba pé, “Kabiyesi, jọ̀wọ́, gbadura sí OLUWA Ọlọrun rẹ kí ẹni tí ó fẹ́ gbẹ̀san ikú ọmọ mi kinni má baà pa ọmọ mi keji.” Dafidi ọba bá dáhùn pé, “Mo ṣèlérí fún ọ, ní orúkọ OLUWA Ọlọrun alààyè, pé, ẹnikẹ́ni kò ní ṣe ọmọ rẹ ní ohunkohun.” Obinrin yìí bá tún dáhùn pé, “Kabiyesi, jọ̀wọ́, jẹ́ kí n sọ gbolohun kan yìí sí i.” Ọba dáhùn pé, “Ó dára, mò ń gbọ́.” Obinrin náà wí pé, “Kí ló dé tí o fi ṣe ohun tí ó burú yìí sí àwọn eniyan Ọlọrun? Ọ̀rọ̀ tí o sọ tán nisinsinyii, ara rẹ gan-an ni o fi dá lẹ́bi, nítorí pé, o kò jẹ́ kí ọmọ rẹ pada wá sílé láti ibi tí ó sá lọ? Dájúdájú, gbogbo wa ni a óo kú. A dàbí omi tí ó dà sílẹ̀, tí ẹnikẹ́ni kò sì lè kójọ mọ́. Ẹni tí ó bá ti kú, Ọlọrun pàápàá kì í tún gbé e dìde mọ́, ṣugbọn kabiyesi lè wá ọ̀nà, láti fi mú ẹni tí ó bá sá jáde kúrò ní ìlú pada wálé. Kabiyesi, ìdí tí mo fi kó ọ̀rọ̀ mi tọ̀ ọ́ wá ni pé, àwọn eniyan ń dẹ́rùbà mí, èyí ni ó mú kí n rò ninu ara mi pé, n óo wá bá ọ sọ̀rọ̀, mo sì ní ìrètí pé, kabiyesi yóo ṣe ohun tí mo wá bẹ̀bẹ̀ pé kí ó bá mi ṣe. Mo mọ̀ pé ọba yóo fetí sílẹ̀ láti gbọ́ tèmi, yóo sì gbà mí kalẹ̀ lọ́wọ́ ẹni tí ó fẹ́ pa èmi ati ọmọ mi, tí ó sì fẹ́ pa wá run kúrò lórí ilẹ̀ tí Ọlọrun fún àwọn eniyan rẹ̀. Mo sì ti mọ̀ lọ́kàn ara mi pé, ọ̀rọ̀ tí kabiyesi bá sọ fún mi yóo fi mí lọ́kàn balẹ̀ nítorí pé, ọba dàbí angẹli Ọlọrun tí ó mọ ìyàtọ̀ láàrin ire ati ibi. OLUWA Ọlọrun rẹ̀ wà pẹlu rẹ̀.”
II. Sam 14:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Joabu ọmọ Seruiah sì kíyèsi i, pé ọkàn ọba sì fà sí Absalomu. Joabu sì ránṣẹ́ sí Tekoa, ó sì mú ọlọ́gbọ́n obìnrin kan láti ibẹ̀ wá, ó sì wí fún un pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, ṣe bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀, kí o sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ sára, kí o má sì ṣe fi òróró pa ara, kí o sì dàbí obìnrin ti ó ti ń ṣọ̀fọ̀ fún òkú lọ́jọ́ púpọ̀. Kí o sì tọ ọba wá, kí o sọ fún un gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ yìí.” Joabu sì fi ọ̀rọ̀ sí lẹ́nu. Nígbà tí obìnrin àrá Tekoa sì ń fẹ́ sọ̀rọ̀ fún ọba, ó wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀, o sí bu ọlá fún un, o sì wí pé, “ọba, gbà mi.” Ọba sì bi í léèrè pé, “Kín ni o ṣe ọ́?” Òun sì dáhùn wí pé, “Nítòótọ́ opó ni èmi ń ṣe, ọkọ mi sì kú. Ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ sì ti ní ọmọkùnrin méjì, àwọn méjèèjì sì jọ jà lóko, kò sì si ẹni tí yóò là wọ́n, èkínní sì lu èkejì, ó sì pa á. Sì wò ó, gbogbo ìdílé dìde sí ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀, wọ́n sì wí pé, Fi ẹni tí ó pa arákùnrin rẹ fún wa, àwa ó sì pa á ní ipò ẹ̀mí arákùnrin rẹ̀ tí ó pa, àwa ó sì pa àrólé náà run pẹ̀lú: wọn ó sì pa iná mi tí ó kù, wọn kì yóò sì fi orúkọ tàbí ẹni tí ó kú sílẹ̀ fún ọkọ mi ní ayé.” Ọba sì wí fún obìnrin náà pé, “Lọ sí ilé rẹ̀, èmi ó sì kìlọ̀ nítorí rẹ.” Obìnrin ará Tekoa náà sì wí fún ọba pé, “Olúwa mi, ọba, jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ náà wà lórí mi, àti lórí ìdílé baba mí; kí ọba àti ìtẹ́ rẹ̀ ó jẹ́ aláìlẹ́bi.” Ọba sì wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ sí ọ, mú ẹni náà tọ̀ mí wá, òun kì yóò sì tọ́ ọ mọ́.” Ó sì wí pé, “Èmi bẹ̀ ọ́ jẹ́ kí ọba ó rántí OLúWA Ọlọ́run rẹ̀, kí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ má ṣe ní ipá láti ṣe ìparun, kí wọn o má bá a pa ọmọ mi!” Òun sì wí pé, “Bí OLúWA ti ń bẹ láààyè ọ̀kan nínú irun orí ọmọ rẹ ki yóò bọ sílẹ̀.” Obìnrin náà sì wí pé, “Èmí bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ìránṣẹ́bìnrin rẹ sọ̀rọ̀ kan fún olúwa mi ọba.” Òun si wí pé, “Máa wí.” Obìnrin náà sì wí pé, “Nítorí kín ni ìwọ sì ṣe ro irú nǹkan yìí sí àwọn ènìyàn Ọlọ́run? Nítorí pé ní sísọ nǹkan yìí ọba ní ẹ̀bi, nítorí pé ọba kò mú ìsáǹsá rẹ̀ bọ̀ wá ilé. Nítorí pé àwa ó sá à kú, a ó sì dàbí omi tí a tú sílẹ̀ tí a kò sì lè ṣàjọ mọ́; nítorí bí Ọlọ́run kò ti gbà ẹ̀mí rẹ̀, ó sì ti ṣe ọ̀nà kí a má bá a lé ìsáǹsá rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ rẹ. “Ǹjẹ́ nítorí náà ni èmi sì ṣe wá sọ nǹkan yìí fún olúwa mi ọba, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ti dẹ́rùbà mí; ìránṣẹ́bìnrin rẹ sì wí pé, ‘Ǹjẹ́ èmi ó sọ fún ọba; ó lè rí bẹ́ẹ̀ pé ọba yóò ṣe ìfẹ́ ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ fún un. Nítorí pé ọba ò gbọ́, láti gbà ìránṣẹ́bìnrin rẹ sílẹ̀ lọ́wọ́ ọkùnrin náà tí ó ń fẹ́ gé èmi àti ọmọ mi pẹ̀lú kúrò nínú ilẹ̀ ìní Ọlọ́run.’ “Ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ sì wí pé, ‘Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ ọba olúwa mi yóò sì jásí ìtùnú; nítorí bí angẹli Ọlọ́run bẹ́ẹ̀ ni olúwa mi ọba láti mọ rere àti búburú: OLúWA Ọlọ́run rẹ yóò sì wà pẹ̀lú rẹ.’ ”