O si ṣe, lẹhin ọdun meji, Absalomu si ni olurẹrun agutan ni Baal-hasori, eyiti o gbè Efraimu: Absalomu si pe gbogbo awọn ọmọ ọba.
Absalomu si tọ̀ ọba wá, o si wipe, Wõ, jọwọ, iranṣẹ rẹ ni olurẹrun agutan, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki ọba, ati awọn iranṣẹ rẹ̀ ba iranṣẹ rẹ lọ.
Ọba si wi fun Absalomu pe, Bẹ̃kọ, ọmọ mi, mo bẹ̀ ọ, má jẹ ki gbogbo wa lọ, ki a má mu ọ nawo pupọ. O si rọ̀ ọ gidigidi, ṣugbọn on kò fẹ lọ, o si sure fun u.
Absalomu si wi pe, Bi kò ba le ri bẹ̃, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki Amnoni ẹgbọ́n mi ba wa lọ. Ọba si wipe, Idi rẹ̀ ti yio fi ba ọ lọ?
Absalomu si rọ̀ ọ, on si jẹ ki Amnoni ati gbogbo awọn ọmọ ọba ba a lọ.
Absalomu si fi aṣẹ fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ki ẹnyin ki o ma kiyesi akoko ti ọti-waini yio mu ọkàn Amnoni dùn, emi o si wi fun nyin pe, Kọlu Amnoni; ki ẹ si pa a: ẹ má bẹ̀ru: ṣe emi li o fi aṣẹ fun nyin? ẹ ṣe giri, ki ẹ ṣe bi alagbara ọmọ.
Awọn iranṣẹ Absalomu si ṣe si Amnoni gẹgẹ bi Absalomu ti paṣẹ. Gbogbo awọn ọmọ ọba si dide, olukuluku gun ibaka rẹ̀, nwọn si sa.
O si ṣe, nigbati nwọn mbẹ li ọ̀na, ihìn si de ọdọ Dafidi pe, Absalomu pa gbogbo awọn ọmọ ọba, ọkan kò si kù ninu wọn.
Ọba si dide, o si fa aṣọ rẹ̀ ya, o si dubulẹ ni ilẹ; gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ ti nwọn duro tì i si fa aṣọ wọn ya.
Jonadabu ọmọ Ṣimea arakonrin Dafidi si dahùn o si wipe, Ki oluwa mi ọba ki o máṣe rò pe nwọn ti pa gbogbo awọn ọdọmọde-kọnrin awọn ọmọ ọba; nitoripe Amnoni nikanṣoṣo li o kú: nitori lati ẹnu Absalomu wá li a ti pinnu rẹ̀ lati ọjọ ti o ti fi agbara mu Tamari aburo rẹ̀.
Njẹ ki oluwa mi ọba ki o máṣe fi nkan yi si ọkàn pe, gbogbo awọn ọmọ ọba li o kú: nitori Amnoni nikanṣoṣo li o kú.
Absalomu si sa. Ọdọmọkunrin na ti nṣọ̀na si gbe oju rẹ̀ soke, o si ri pe, ọ̀pọ enia mbọ̀ li ọ̀na lẹhin rẹ̀ lati iha oko wá.
Jonadabu si wi fun ọba pe, Wõ, awọn ọmọ ọba mbọ̀: gẹgẹ bi ọ̀rọ iranṣẹ rẹ, bẹ̃ li o ri.
O si ṣe, nigbati o ti pari ọ̀rọ isọ, si wõ, awọn ọmọ ọba de, nwọn si gbe ohùn wọn soke, nwọn si sọkun: ọba ati gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ pẹlu si sọkun nlanla.
Absalomu si sa, o si tọ̀ Talmai lọ, ọmọ Ammihudu, ọba Geṣuri. Dafidi si nkãnu nitori ọmọ rẹ̀ lojojumọ.
Absalomu si sa, o si lọ si Geṣuri, o si gbe ibẹ li ọdun mẹta.
Ọkàn Dafidi ọba si fà gidigidi si Absalomu: nitoriti o ti gbà ipẹ̀ niti Amnoni: o sa ti kú.