II. Sam 13:23-39
II. Sam 13:23-39 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe, lẹhin ọdun meji, Absalomu si ni olurẹrun agutan ni Baal-hasori, eyiti o gbè Efraimu: Absalomu si pe gbogbo awọn ọmọ ọba. Absalomu si tọ̀ ọba wá, o si wipe, Wõ, jọwọ, iranṣẹ rẹ ni olurẹrun agutan, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki ọba, ati awọn iranṣẹ rẹ̀ ba iranṣẹ rẹ lọ. Ọba si wi fun Absalomu pe, Bẹ̃kọ, ọmọ mi, mo bẹ̀ ọ, má jẹ ki gbogbo wa lọ, ki a má mu ọ nawo pupọ. O si rọ̀ ọ gidigidi, ṣugbọn on kò fẹ lọ, o si sure fun u. Absalomu si wi pe, Bi kò ba le ri bẹ̃, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki Amnoni ẹgbọ́n mi ba wa lọ. Ọba si wipe, Idi rẹ̀ ti yio fi ba ọ lọ? Absalomu si rọ̀ ọ, on si jẹ ki Amnoni ati gbogbo awọn ọmọ ọba ba a lọ. Absalomu si fi aṣẹ fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ki ẹnyin ki o ma kiyesi akoko ti ọti-waini yio mu ọkàn Amnoni dùn, emi o si wi fun nyin pe, Kọlu Amnoni; ki ẹ si pa a: ẹ má bẹ̀ru: ṣe emi li o fi aṣẹ fun nyin? ẹ ṣe giri, ki ẹ ṣe bi alagbara ọmọ. Awọn iranṣẹ Absalomu si ṣe si Amnoni gẹgẹ bi Absalomu ti paṣẹ. Gbogbo awọn ọmọ ọba si dide, olukuluku gun ibaka rẹ̀, nwọn si sa. O si ṣe, nigbati nwọn mbẹ li ọ̀na, ihìn si de ọdọ Dafidi pe, Absalomu pa gbogbo awọn ọmọ ọba, ọkan kò si kù ninu wọn. Ọba si dide, o si fa aṣọ rẹ̀ ya, o si dubulẹ ni ilẹ; gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ ti nwọn duro tì i si fa aṣọ wọn ya. Jonadabu ọmọ Ṣimea arakonrin Dafidi si dahùn o si wipe, Ki oluwa mi ọba ki o máṣe rò pe nwọn ti pa gbogbo awọn ọdọmọde-kọnrin awọn ọmọ ọba; nitoripe Amnoni nikanṣoṣo li o kú: nitori lati ẹnu Absalomu wá li a ti pinnu rẹ̀ lati ọjọ ti o ti fi agbara mu Tamari aburo rẹ̀. Njẹ ki oluwa mi ọba ki o máṣe fi nkan yi si ọkàn pe, gbogbo awọn ọmọ ọba li o kú: nitori Amnoni nikanṣoṣo li o kú. Absalomu si sa. Ọdọmọkunrin na ti nṣọ̀na si gbe oju rẹ̀ soke, o si ri pe, ọ̀pọ enia mbọ̀ li ọ̀na lẹhin rẹ̀ lati iha oko wá. Jonadabu si wi fun ọba pe, Wõ, awọn ọmọ ọba mbọ̀: gẹgẹ bi ọ̀rọ iranṣẹ rẹ, bẹ̃ li o ri. O si ṣe, nigbati o ti pari ọ̀rọ isọ, si wõ, awọn ọmọ ọba de, nwọn si gbe ohùn wọn soke, nwọn si sọkun: ọba ati gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ pẹlu si sọkun nlanla. Absalomu si sa, o si tọ̀ Talmai lọ, ọmọ Ammihudu, ọba Geṣuri. Dafidi si nkãnu nitori ọmọ rẹ̀ lojojumọ. Absalomu si sa, o si lọ si Geṣuri, o si gbe ibẹ li ọdun mẹta. Ọkàn Dafidi ọba si fà gidigidi si Absalomu: nitoriti o ti gbà ipẹ̀ niti Amnoni: o sa ti kú.
II. Sam 13:23-39 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn ọdún meji tí nǹkan yìí ṣẹlẹ̀, Absalomu lọ rẹ́ irun aguntan rẹ̀ ní Baali Hasori, lẹ́bàá ìlú Efuraimu, ó sì pe gbogbo àwọn ọmọ ọba patapata lọkunrin sibẹ. Ó lọ sí ọ̀dọ̀ Dafidi ọba, ó wí fún un pé, “Kabiyesi, iranṣẹ rẹ ń rẹ́ irun aguntan rẹ̀, mo sì fẹ́ kí kabiyesi ati gbogbo àwọn oníṣẹ́ rẹ̀ wá síbi àjọ̀dún náà.” Ọba ní, “Rárá, ọmọ mi, bí gbogbo wa bá lọ, wahala náà yóo pọ̀jù fún ọ.” Absalomu rọ ọba títí, ṣugbọn ó kọ̀ jálẹ̀. Ọba bá súre fún un, ó ní kí ó máa lọ. Absalomu dáhùn pé, “Ó dára, bí o kò bá lè lọ, ṣé o óo jẹ́ kí Amnoni arakunrin mi lọ?” Ọba bá bèèrè pé, “Nítorí kí ni yóo ṣe ba yín lọ?” Ṣugbọn Absalomu rọ Dafidi títí tí ó fi gbà pé kí Amnoni ati àwọn ọmọ ọba yòókù lọkunrin bá a lọ. Absalomu sì se àsè rẹpẹtẹ, bí ẹni pé ọba ni ó fẹ́ ṣe lálejò. Absalomu wí fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ẹ máa kíyèsí Amnoni, nígbà tí ó bá mu ọtí yó, bí mo bá ti fun yín ní àṣẹ pé kí ẹ pa á, pípa ni kí ẹ pa á, ẹ má bẹ̀rù; èmi ni mo ran yín. Ẹ mú ọkàn gírí kí ẹ sì ṣe bí akikanju.” Àwọn iranṣẹ náà bá tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀, wọ́n sì pa Amnoni. Gbogbo àwọn ọmọ Dafidi yòókù bá gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn, wọ́n sì sá lọ. Nígbà tí wọn ń sá bọ̀ wálé, àwọn kan wá sọ fún Dafidi pé, “Absalomu ti pa gbogbo àwọn ọmọ rẹ, ati pé kò ṣẹ́ku ẹyọ ẹnìkan.” Ọba dìde, ó fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn, ó sì sùn sórí ilẹ̀ lásán, àwọn iranṣẹ rẹ̀ tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ fa aṣọ tiwọn náà ya. Ṣugbọn Jonadabu, ọmọ Ṣimea, arakunrin Dafidi, wí fún ọba pé, “Kabiyesi, ẹnikẹ́ni kò pa gbogbo àwọn ọmọ rẹ. Amnoni nìkan ni Absalomu pàṣẹ pé kí wọ́n pa. Láti ìgbà tí Amnoni ti fi ipá bá Tamari, arabinrin rẹ̀ lòpọ̀, ni ó ti pinnu láti ṣe ohun tí ó ṣe yìí. Nítorí náà, kí oluwa mi má gba ìròyìn tí wọ́n mú wá gbọ́, pé gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ ni wọ́n ti kú. Amnoni nìkan ni wọ́n pa.” Absalomu sá lọ ní àkókò yìí. Kò pẹ́ rárá, lẹ́yìn náà, ọmọ ogun tí ń ṣọ́ ọ̀nà tí ó wọ ìlú rí ogunlọ́gọ̀ eniyan, wọ́n ń bọ̀ láti ọ̀nà Horonaimu, lẹ́bàá òkè. Jonadabu bá sọ fún ọba pé, “Àwọn ọmọ oluwa mi ni wọ́n ń bọ̀ yìí, gẹ́gẹ́ bí mo ti wí.” Ó fẹ́rẹ̀ má tíì dákẹ́ ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, tí àwọn ọmọ Dafidi fi wọlé, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọkún, Dafidi ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ náà sì sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn. Ṣugbọn Absalomu sá lọ sọ́dọ̀ Talimai, ọmọ Amihudu, ọba Geṣuri, Dafidi sì ń ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ lojoojumọ. Absalomu wà ní Geṣuri níbi tí ó sá lọ fún ọdún mẹta. Nígbà tí ó yá tí Dafidi gbé ìbànújẹ́ ikú Amnoni ọmọ rẹ̀ kúrò lára, ọkàn Absalomu ọmọ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí fà á.
II. Sam 13:23-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì ṣe, lẹ́yìn ọdún méjì, Absalomu sì ní olùrẹ́run àgùntàn ní Baali-Hasori, èyí tí ó gbé Efraimu: Absalomu sì pe gbogbo àwọn ọmọ ọba. Absalomu sì tọ ọba wá, ó sì wí pé, “Wò ó, jọ̀wọ́, ìránṣẹ́ rẹ ní olùrẹ́run àgùntàn, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ọba, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá ìránṣẹ́ rẹ lọ.” Ọba sì wí fún Absalomu pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ, ọmọ mi, mo bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí gbogbo wa lọ, kí a má bá à mú ọ náwó púpọ̀.” Ó sì rọ̀ ọ́ gidigidi, ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ lọ, òun sì súre fún un. Absalomu sì wí pé, “Bí kò bá le rí bẹ́ẹ̀, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí Amnoni ẹ̀gbọ́n mi bá wa lọ.” Ọba sì wí pé, “Ìdí rẹ̀ tí yóò fi bá ọ lọ.” Absalomu sì rọ̀ ọ́, òun sì jẹ́ kí Amnoni àti gbogbo àwọn ọmọ ọba bá a lọ. Absalomu sì fi àṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Kí ẹ̀yin máa kíyèsi àkókò tí ọtí-wáinì yóò mú ọkàn Amnoni dùn, èmi ó sì wí fún yín pé, ‘Kọlu Amnoni,’ kí ẹ sì pa á. Ẹ má bẹ̀rù. Ṣé èmi ni ó fi àṣẹ fún yin? Ẹ ṣe gírí, kí ẹ ṣe bí alágbára ọmọ.” Àwọn ìránṣẹ́ Absalomu sì ṣe sí Amnoni gẹ́gẹ́ bí Absalomu ti pàṣẹ. Gbogbo àwọn ọmọ ọba sì dìde, olúkúlùkù gun ìbáaka rẹ̀, wọ́n sì sá. Nígbà tí wọ́n ń bẹ lọ́nà, ìròyìn sì dé ọ̀dọ̀ Dafidi pé, “Absalomu pa gbogbo àwọn ọmọ ọba, ọ̀kan kò sì kù nínú wọn.” Ọba sì dìde, ó sì fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì dùbúlẹ̀ ni ilẹ̀; gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n dúró tì í sì fà aṣọ wọn ya. Jonadabu ọmọ Ṣimea arákùnrin Dafidi sì dáhùn ó sì wí pé, “Kí olúwa mi ọba má ṣe rò pé wọ́n ti pa gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin àwọn ọmọ ọba; nítorí pé Amnoni nìkan ṣoṣo ni ó kú: nítorí láti ẹnu Absalomu wá ni a ti pinnu rẹ̀ láti ọjọ́ tí ó ti fi agbára mú Tamari àbúrò rẹ̀. Ǹjẹ́ kí olúwa mi ọba má ṣe fi nǹkan yìí sí ọkàn pé gbogbo àwọn ọmọ ọba ni o kú: nítorí Amnoni nìkan ṣoṣo ni ó kú.” Absalomu sì sá. Ọ̀dọ́mọkùnrin náà ti ń ṣọ́nà sì gbé ojú rẹ̀ sókè, o si rí i pé, “ọ̀pọ̀ ènìyàn ń bọ́ lọ́nà lẹ́yìn rẹ̀ láti ìhà òkè wá.” Jonadabu sì wí fún ọba pé, “Wò ó, àwọn ọmọ ọba ń bọ́; gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó rí.” Nígbà tí ó sì parí ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, sì wò ó àwọn ọmọ ọba dé, wọ́n sì gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì sọkún: ọba àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú sì sọkún ńláńlá. Absalomu sì sá, ó sì tọ Talmai lọ, ọmọ Ammihudu, ọba Geṣuri. Dafidi sì ń káàánú nítorí ọmọ rẹ̀ lójoojúmọ́. Absalomu sì sá, ó sì lọ sí Geṣuri ó sì gbé ibẹ̀ lọ́dún mẹ́ta. Ọkàn Dafidi ọba sì fà gidigidi sí Absalomu: nítorí tí ó tí gba ìpẹ̀ ní ti Amnoni: ó sá à ti kú.