I. Sam 9:15-17

I. Sam 9:15-17 YBCV

Oluwa ti wi leti Samueli ni ijọ kan ki Saulu ki o to de, wipe, Niwoyi ọla emi o ran ọkunrin kan lati ilẹ Benjamini wá si ọ, iwọ o si da ororo si i lori ki o le jẹ olori-ogun Israeli awọn enia mi, yio si gbà awọn enia mi là lọwọ awọn Filistini: nitori emi ti bojuwo awọn enia mi, nitoripe ẹkun wọn ti de ọdọ mi. Nigbati Samueli ri Saulu, Oluwa wi fun u pe, Wo ọkunrin na ti mo ti sọrọ rẹ̀ fun ọ! on ni yio jọba awọn enia mi.