I. Sam 9:15-17
I. Sam 9:15-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Oluwa ti wi leti Samueli ni ijọ kan ki Saulu ki o to de, wipe, Niwoyi ọla emi o ran ọkunrin kan lati ilẹ Benjamini wá si ọ, iwọ o si da ororo si i lori ki o le jẹ olori-ogun Israeli awọn enia mi, yio si gbà awọn enia mi là lọwọ awọn Filistini: nitori emi ti bojuwo awọn enia mi, nitoripe ẹkun wọn ti de ọdọ mi. Nigbati Samueli ri Saulu, Oluwa wi fun u pe, Wo ọkunrin na ti mo ti sọrọ rẹ̀ fun ọ! on ni yio jọba awọn enia mi.
I. Sam 9:15-17 Yoruba Bible (YCE)
Ó ku ọ̀la kí Saulu dé ni OLUWA ti sọ fún Samuẹli pé, “Ní ìwòyí ọ̀la, n óo rán ọkunrin kan sí ọ láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini. O óo ta òróró sí i lórí láti yàn án ní ọba Israẹli, àwọn eniyan mi. Ọkunrin náà ni yóo gbà wọ́n kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Filistia, nítorí mo ti rí àwọn eniyan mi tí ń jìyà, mo sì ti gbọ́ igbe wọn.” Nígbà tí Samuẹli fi ojú kan Saulu, OLUWA wí fún un pé, “Ọkunrin tí mo sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún ọ nìyí. Òun ni yóo jọba lórí àwọn eniyan mi.”
I. Sam 9:15-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA ti sọ létí Samuẹli ní ọjọ́ kan kí Saulu ó tó dé pé, “Ní ìwòyí ọ̀la, èmi yóò ran ọmọkùnrin kan sí ọ láti ilẹ̀ Benjamini. Fi òróró yàn án gẹ́gẹ́ bí olórí lórí àwọn ọmọ Israẹli, yóò gba àwọn ènìyàn mi kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Filistini. Mo ti bojú wo àwọn ènìyàn mi, nítorí igbe wọn ti dé ọ̀dọ̀ mi.” Nígbà tí Samuẹli fojúrí Saulu, OLúWA sọ fún un pé, “Èyí ni ọkùnrin tí mo sọ fún ọ nípa rẹ̀, yóò darí àwọn ènìyàn mi.”