I. Sam 7:1-2

I. Sam 7:1-2 YBCV

AWỌN ọkunrin Kirjatjearimu wá, nwọn gbe apoti Oluwa na, nwọn si mu u wá si ile Abinadabu ti o wà lori oke, nwọn si ya Eleasari ọmọ rẹ̀ si mimọ́ lati ma tọju apoti Oluwa. O si ṣe, lati igba ti apoti Oluwa fi wà ni Kirjatjearimu, ọjọ na pẹ́; o si jẹ ogun ọdun: gbogbo ile Israeli si pohunrere ẹkun si Oluwa.