I. Sam 7:1-2
I. Sam 7:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
AWỌN ọkunrin Kirjatjearimu wá, nwọn gbe apoti Oluwa na, nwọn si mu u wá si ile Abinadabu ti o wà lori oke, nwọn si ya Eleasari ọmọ rẹ̀ si mimọ́ lati ma tọju apoti Oluwa. O si ṣe, lati igba ti apoti Oluwa fi wà ni Kirjatjearimu, ọjọ na pẹ́; o si jẹ ogun ọdun: gbogbo ile Israeli si pohunrere ẹkun si Oluwa.
I. Sam 7:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn ará ìlú Kiriati Jearimu wá, wọ́n gbé àpótí OLUWA náà lọ sí ilé Abinadabu, tí ń gbé orí òkè kan. Wọ́n ya Eleasari, ọmọ rẹ̀ sí mímọ́, láti máa bojútó àpótí OLUWA náà. Láti ìgbà náà, Kiriati Jearimu ni wọ́n gbé àpótí OLUWA sí fún nǹkan bíi ogún ọdún, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sì ń ké pe OLUWA fún ìrànlọ́wọ́.
I. Sam 7:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà àwọn ará Kiriati-Jearimu wá, wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí OLúWA. Wọ́n gbé e lọ sí ilé Abinadabu lórí òkè, wọ́n sì ya Eleasari ọmọ rẹ̀ sí mímọ́ láti ṣọ́ àpótí ẹ̀rí OLúWA. Ó sì jẹ́ ní ìgbà pípẹ́, ogún ọdún ni àpótí ẹ̀rí OLúWA fi wà ní Kiriati-Jearimu. Gbogbo ilé Israẹli ṣọ̀fọ̀ wọ́n sì pohùnréré ẹkún sí OLúWA.