I. Joh 4:15-18

I. Joh 4:15-18 YBCV

Ẹnikẹni ti o ba jẹwọ pe Jesu Ọmọ Ọlọrun ni, Ọlọrun ngbé inu rẹ̀, ati on ninu Ọlọrun. Awa ti mọ̀, a si gbà ifẹ ti Ọlọrun ní si wa gbọ́. Ifẹ ni Ọlọrun; ẹniti o ba si ngbé inu ifẹ o ngbé inu Ọlọrun, ati Ọlọrun ninu rẹ̀. Ninu eyi li a mu ifẹ ti o wà ninu wa pé, ki awa ki o le ni igboiya li ọjọ idajọ: nitoripe bi on ti ri, bẹ̃li awa si ri li aiye yi. Ìbẹru kò si ninu ifẹ; ṣugbọn ifẹ ti o pé nlé ibẹru jade: nitoriti ìbẹru ni iyà ninu. Ẹniti o bẹ̀ru kò pé ninu ifẹ.