I. Joh 3:1-12

I. Joh 3:1-12 YBCV

Ẹ wo irú ifẹ ti Baba fi fẹ wa, ti a fi npè wa ni ọmọ Ọlọrun; bẹ̃ li a sa jẹ. Nitori eyi li aiye kò ṣe mọ̀ wa, nitoriti ko mọ̀ ọ. Olufẹ, ọmọ Ọlọrun li awa iṣe nisisiyi, a kò si ti ifihàn bi awa ó ti ri: awa mọ pe, nigbati a bá fihan, a ó dabi rẹ̀; nitori awa o ri i ani bi on ti ri. Olukuluku ẹniti o ba si ni ireti yi ninu rẹ̀, a wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́, ani bi on ti mọ́. Ẹnikẹni ti o ba ndẹṣẹ o nrú ofin pẹlu: nitori ẹ̀ṣẹ ni riru ofin. Ẹnyin si mọ̀ pe, on farahàn lati mu ẹ̀ṣẹ kuro; ẹ̀ṣẹ kò si si ninu rẹ̀. Ẹnikẹni ti o ba ngbé inu rẹ̀ ki idẹṣẹ; ẹnikẹni ti o ba ndẹṣẹ kò ri i, bẹ̃ni kò mọ̀ ọ. Ẹnyin ọmọ mi, ẹ máṣe jẹ ki ẹnikẹni ki o tàn nyin: ẹniti o ba nṣe ododo, o jasi olododo, gẹgẹ bi on ti iṣe olododo. Ẹniti o ba ndẹṣẹ ti Èṣu ni; nitori lati àtetekọṣe ni Èṣu ti ndẹṣẹ. Nitori eyi li Ọmọ Ọlọrun ṣe farahàn, ki o le pa iṣẹ Èṣu run. Ẹnikẹni ti a ti ipa Ọlọrun bí, ki idẹṣẹ; nitoriti irú rẹ̀ ngbe inu rẹ̀: kò si le dẹṣẹ nitoripe a ti ti ipa Ọlọrun bi i. Ninu eyi li awọn ọmọ Ọlọrun nfarahan, ati awọn ọmọ Èṣu: ẹnikẹni ti kò ba nṣe ododo kì iṣe ti Ọlọrun, ati ẹniti kò fẹràn arakunrin rẹ̀. Nitori eyi ni iṣẹ ti ẹnyin ti gbọ́ li àtetekọṣe, ki awa ki o fẹràn ara wa. Ki iṣe bi Kaini, ti jẹ́ ti ẹni buburu nì, ti o si pa arakunrin rẹ̀. Nitori kili o si ṣe pa a? Nitoriti iṣẹ on jẹ buburu, ti arakunrin rẹ̀ si jẹ ododo.