ORIN SOLOMONI 1:12-17

ORIN SOLOMONI 1:12-17 YCE

Nígbà tí ọba rọ̀gbọ̀kú lórí ìjókòó rẹ̀, turari mi ń tú òórùn dídùn jáde. Olùfẹ́ mi dàbí àpò òjíá, bí ó ti sùn lé mi láyà. Olùfẹ́ mi dàbí ìdì òdòdó igi Sipirẹsi, ninu ọgbà àjàrà Engedi. Wò ó! O mà dára o, olólùfẹ́ mi; o lẹ́wà pupọ. Ojú rẹ tutù bíi ti àdàbà. Háà, o mà dára o! Olùfẹ́ mi, o lẹ́wà gan-an ni. Ewéko tútù ni yóo jẹ́ ibùsùn wa. Igi Kedari ni òpó ilé wa, igi firi sì ni ọ̀pá àjà ilé wa.