O. Sol 1:12-17
O. Sol 1:12-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati ọba wà ni ibujoko ijẹun rẹ̀, ororo mi rán õrun rẹ̀ jade. Idi ojia ni olufẹ ọ̀wọ́n mi si mi; on o ma gbe ãrin ọmu mi. Olufẹ mi ri si mi bi ìdi ìtànná igi kipressi ni ọgba-ajara Engedi. Wò o, iwọ li ẹwà, olufẹ mi; wò o, iwọ li ẹwà: iwọ li oju àdaba. Wò o, iwọ li ẹwà, olufẹ mi, nitõtọ, o wuni: ibusun wa pẹlu ni itura. Igi kedari ni iti-igi ile wa, igi firi si ni ẹkẹ́ wa.
O. Sol 1:12-17 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ọba rọ̀gbọ̀kú lórí ìjókòó rẹ̀, turari mi ń tú òórùn dídùn jáde. Olùfẹ́ mi dàbí àpò òjíá, bí ó ti sùn lé mi láyà. Olùfẹ́ mi dàbí ìdì òdòdó igi Sipirẹsi, ninu ọgbà àjàrà Engedi. Wò ó! O mà dára o, olólùfẹ́ mi; o lẹ́wà pupọ. Ojú rẹ tutù bíi ti àdàbà. Háà, o mà dára o! Olùfẹ́ mi, o lẹ́wà gan-an ni. Ewéko tútù ni yóo jẹ́ ibùsùn wa. Igi Kedari ni òpó ilé wa, igi firi sì ni ọ̀pá àjà ilé wa.
O. Sol 1:12-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí ọba wà ní orí ìjókòó rẹ̀, òróró ìkunra mi tú òórùn jáde. Ìdì òjìá ni olùfẹ́ mi jẹ sí mi, òun ó sinmi lé àárín ọmú mi. Bí ìdì ìtànná Henina ni olùfẹ́ mi rí sí mi láti inú ọgbà àjàrà ti En-Gedi. Báwo ni o ti lẹ́wà tó, olólùfẹ́ mi! Háà, Báwo ni o ṣe lẹ́wà tó! Ìwọ ní ojú ẹyẹlé. Báwo ni o ṣe dára tó, olùfẹ́ mi! Háà, Báwo ni o ṣe wu ni! Ibùsùn wa ní ìtura. Ìtànṣán ilé wa jẹ́ ti igi kedari ẹkẹ́ ilé wa jẹ́ ti igi firi.