ORIN DAFIDI 68:5-7

ORIN DAFIDI 68:5-7 YCE

Baba àwọn aláìníbaba ati olùgbèjà àwọn opó ni Ọlọrun, ní ibùgbé rẹ̀ mímọ́. Ọlọrun, olùpèsè ibùjókòó fún àlejò tí ó nìkan wà; ẹni tí ó kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n jáde sinu ìdẹ̀ra, ṣugbọn ó sì fi àwọn ọlọ̀tẹ̀ sílẹ̀ ninu ilẹ̀ gbígbẹ. Ọlọrun, nígbà tí ò ń jáde lọ níwájú àwọn eniyan rẹ, nígbà tí ò ń yan la aṣálẹ̀ já